ÀPILẸ̀KỌ 47
ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
“O Ṣeyebíye Gan-an”!
“O ṣeyebíye gan-an.”—DÁN. 9:23.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àpilẹ̀ko yìí máa jẹ́ káwọn tó rò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan rí i pé àwọn ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà.
1-2. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kó dá wa lójú pé a ṣeyebíye lójú Jèhófà?
ÀWỌN ìránṣẹ́ Jèhófà ṣeyebíye gan-an lójú ẹ̀, àmọ́ àwọn kan lára wọn máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan tàbí pé Ọlọ́run ò rí tàwọn rò. Ìdí sì ni pé ó ṣeé ṣe kẹ́nì kan ti hùwà tí ò dáa sí wọn tàbí sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n máa rò pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló máa jẹ́ kó o gbà pé o ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà?
2 Ọ̀kan lára ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká wo àwọn ìtàn inú Bíbélì, ká lè mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn àti bó ṣe fẹ́ ká máa ṣe sí wọn. Jésù Ọmọ ẹ̀ pọ́n àwọn èèyàn lé, ó sì buyì kún wọn. Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé òun àti Bàbá ẹ̀ mọyì àwọn tí wọ́n rò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. (Jòh. 5:19; Héb. 1:3) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa: (1) bí Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé àwọn ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà àti (2) bá a ṣe lè jẹ́ kó dá wa lójú pé òótọ́ la ṣeyebíye lójú Jèhófà.—Hág. 2:7.
BÍ JÉSÙ ṢE JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN RÍ I PÉ ÀWỌN ṢEYEBÍYE
3. Báwo ni Jésù ṣe ṣe sáwọn ará Gálílì tó wá ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ ẹ̀?
3 Nígbà tí Jésù ń wàásù káàkiri ní Gálílì, ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ ẹ̀ kí wọ́n lè tẹ́tí sí i, kó sì lè wò wọ́n sàn. Jésù sọ nípa wọn pé “wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó lawọ́, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36; wo àlàyé ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí nínú nwtsty-E.) Ìdí ni pé lójú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, wọn ò dákan mọ̀, wọn ò sì yẹ lẹ́ni tá à ń pọ́n lé, kódà “ẹni ègún” ni wọ́n kà wọ́n sí. (Jòh. 7:47-49; àlàyé ọ̀rọ̀ nínú nwtsty-E.) Àmọ́ Jésù pọ́n wọn lé, torí ẹ̀ ló ṣe wáyè kọ́ wọn tó sì wò wọ́n sàn. (Mát. 9:35) Kò tán síbẹ̀ o, kó lè túbọ̀ ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa wàásù, ó sì fún wọn lágbára láti wo àwọn èèyàn sàn.—Mát. 10:5-8.
4. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ronú nípa bí Jésù ṣe ṣe sáwọn tó wá gbọ́rọ̀ ẹ̀?
4 Bí Jésù ṣe pọ́n àwọn èèyàn lé nígbà tí wọ́n wá gbọ́rọ̀ ẹ̀ tó sì fi inúure hàn sí wọn fi hàn pé òun àti bàbá ẹ̀ mọyì wọn, báwọn míì ò tiẹ̀ kà wọ́n sí láwùjọ. Tó o bá ń sin Jèhófà, àmọ́ tó ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò wúlò, á dáa kó o ronú nípa bí Jésù ṣe fi hàn pé òun mọyì àwọn tí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ẹ̀, báwọn míì ò tiẹ̀ kà wọ́n sí. Ìyẹn á jẹ́ kó o rí i pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà.
5. Ìṣòro wo lobìnrin tí Jésù pà dé ní Gálílì ní?
5 Kì í ṣe àwùjọ àwọn èèyàn nìkan ni Jésù ràn lọ́wọ́, ó tún máa ń kíyè sí àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ń wàásù ní Gálílì, ó pà dé obìnrin kan tí ìsun ẹ̀jẹ̀ ti fojú ẹ̀ rí màbo fọ́dún méjìlá (12). (Máàkù 5:25) Bí òfin Mósè ṣe sọ, ẹnikẹ́ni tó bá nírú àìsàn yìí máa di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì fọwọ́ kàn án náà máa di aláìmọ́. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe lobìnrin náà máa ń dá wà lọ́pọ̀ ìgbà. Yàtọ̀ síyẹn, kò ní lè dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n bá ń jọ́sìn Jèhófà àti nígbà àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe. (Léf. 15:19, 25) Ẹ ò rí i pé ìyà ọ̀nà méjì ló ń jẹ obìnrin yìí, bí àìsàn ṣe ń hàn án léèmọ̀ bẹ́ẹ̀ láá tún máa ronú pé òun ò wúlò.—Máàkù 5:26.
6. Kí ni obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ṣe kó lè rí ìwòsàn?
6 Obìnrin náà fẹ́ kí Jésù wo òun sàn, àmọ́ kò lọ bá Jésù ní tààràtà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kójú máa tì í torí àìsàn tó ń ṣe é. Tàbí kó jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà á pé Jésù máa lé òun pa dà torí òun jẹ́ aláìmọ́, kò sì yẹ kóun wá sáàárín èrò. Ló bá rọra fọwọ́ kan aṣọ Jésù, torí ó nígbàgbọ́ pé ìyẹn máa jẹ́ kára òun yá. (Máàkù 5:27, 28) Ìgbàgbọ́ tó ní yẹn sì jẹ́ kára ẹ̀ yá lóòótọ́. Jésù wá béèrè pé ta ló fọwọ́ kan òun, obìnrin náà jẹ́wọ́ pé òun ni. Kí ni Jésù wá ṣe?
7. Báwo ni Jésù ṣe ṣe sí obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà? (Máàkù 5:34)
7 Jésù pọ́n obìnrin náà lé, ó sì ṣàánú ẹ̀. Ó kíyè sí pé “ẹ̀rù ba obìnrin náà, jìnnìjìnnì sì bò ó.” (Máàkù 5:33) Ó fara balẹ̀ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ kára lè tù ú, torí ó rí i pé ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀. Kódà Jésù pè é ní “ọmọbìnrin.” Ọ̀rọ̀ tí Jésù lò yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àpọ́nlé nìkan, àmọ́ ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure téèyàn fohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ. (Ka Máàkù 5:34.) Àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé, “ibí yìí nìkan ni Bíbélì ti sọ pé Jésù pe obìnrin ní ‘ọmọbìnrin,’ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀rù tó ń ba obìnrin náà ló jẹ́ kó sọ̀rọ̀ yìí.” Ẹ wo bí ara ṣe máa tu obìnrin náà lẹ́yìn tí Jésù bá a sọ̀rọ̀. Ká ní Jésù ò sọ̀rọ̀ tó mára tu obìnrin náà, ó ṣeé ṣe kó ríwòsàn lóòótọ́, àmọ́ ó ṣì lè máa dára ẹ̀ lẹ́bi torí bó ṣe wọ àárín èrò tó sì fọwọ́ kan aṣọ Jésù. Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé, kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ wo obìnrin náà sàn, àmọ́ ó fẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣeyebíye lójú Jèhófà Baba wa ọ̀run.
8. Ìṣòro wo ni arábìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil ní?
8 Lónìí, àwọn kan lára wa ń ṣàìsàn tó le gan-an, ìyẹn lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn kó sì máa ṣe wọ́n bíi pé wọn ò wúlò. Bí àpẹẹrẹ, aṣáájú-ọ̀nà ni Arábìnrin Maria a tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil, aláàbọ̀ ara ni látìgbà tí wọ́n ti bí i, kò ní ẹsẹ̀ rárá kò sì ní ọwọ́ òsì. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà làwọn ọmọléèwé mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì máa ń pè mí láwọn orúkọ tí mi ò jẹ́. Èyí tó tiẹ̀ wá dùn mí jù ni pé báwọn mọ̀lẹ́bí mi ṣe máa ń ṣe sí mi nígbà míì máa ń jẹ́ kí n ro ara mi pin.”
9. Kí ló jẹ́ kí Maria mọ̀ pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà?
9 Kí ló ran Maria lọ́wọ́ tí ò fi ro ara ẹ̀ pin mọ́? Nígbà tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ará ìjọ ẹ̀ tù ú nínú, wọ́n sì jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì mọyì ẹ̀. Ó sọ pé: “Tí mo bá ní kí n máa dárúkọ gbogbo àwọn tó ti ràn mí lọ́wọ́ ilẹ̀ á kún. Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ kí n wà láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi.” Ẹ ò rí i pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin yìí ṣe dáadáa gan-an bí wọ́n ṣe jẹ́ kí Maria rí i pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà.
10. Ìṣòro wo ni Màríà Magidalénì ní? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe ran Màríà Magidalénì lọ́wọ́. Ẹ̀mí èṣù méje ló ń da obìnrin yìí láàmú. (Lúùkù 8:2) Ó ṣeé ṣe káwọn ẹ̀mí èṣù náà mú kó máa ṣe wọ́nranwọ̀nran, kíyẹn sì mú káwọn èèyàn máa sá fún un. Láwọn àsìkò yẹn, ó ṣeé ṣe kí nǹkan nira fún un gan-an, kẹ́rù máa bà á, kó sì ro ara ẹ̀ pin. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù ló lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ẹ̀, tó sì wá di ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Àmọ́ kí làwọn nǹkan míì tí Jésù ṣe tó jẹ́ kí Màríà Magidalénì mọ̀ pé òun ṣeyebíye lójú Ọlọ́run?
Kí ni Jésù ṣe tó jẹ́ kí Màríà Magidalénì mọ̀ pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà? (Wo ìpínrọ̀ 10-11)
11. Àwọn nǹkan míì wo ni Jésù ṣe tó jẹ́ kí Màríà Magidalénì mọ̀ pé òun ṣeyebíye lójú Ọlọ́run? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Jésù ní kí Màríà Magidalénì máa tẹ̀ lé òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn òun táwọn bá fẹ́ lọ wàásù láti ibì kan dé ibòmíì. b Tí Jésù bá ń wàásù, Màríà máa ń gbọ́ bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn, ó sì ń fi àwọn ohun tó ń kọ́ sílò. Jésù tún fara hàn án lọ́jọ́ tó jíǹde. Kódà, ó wà lára àwọn tí Jésù kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn. Jésù tiẹ̀ sọ fún un pé, kó lọ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé òun ti jíǹde. Kò sí àní-àní pé àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yìí máa jẹ́ kó dá a lójú pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà!—Jòh. 20:11-18.
12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Lidia tó fi ronú pé òun ò wúlò?
12 Bíi ti Màríà Magidalénì àwọn kan lónìí máa ń rò pé àwọn ò wúlò. Arábìnrin Lidia tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ pé nígbà tí màmá òun lóyún òun, díẹ̀ ló kù kí wọ́n ṣẹ́ oyún náà. Kódà nígbà tí Lidia ṣì kéré gan-an, ó rántí bí màmá ẹ̀ ṣe máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sí i, tó sì máa ń pa á tì. Ó sọ pé: “Torí ohun tójú mi ti rí, ó máa ń wù mí káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ mi, kí wọ́n sì mú mi lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, ó máa ń ṣe mí bíi pé kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ mi, torí ohun tí màmá mi ti fojú mi rí ti jẹ́ kí n gbà pé èèyàn burúkú ni mí.”
13. Kí ló jẹ́ kó dá Lidia lójú pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà?
13 Nǹkan yí pa dà fún Lidia lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìdí ni pé ó máa ń gbàdúrà, ó máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, àwọn ará máa ń sọ̀rọ̀ tó tù ú lára, wọ́n sì máa ń ràn án lọ́wọ́. Ìyẹn jẹ́ kó rí i pé òun ṣeyebíye lójú Jèhófà. Lidia sọ pé: “Léraléra lọkọ mi máa ń sọ fún mi pé òun nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì máa ń rán mi létí àwọn ìwà dáadáa tí mo ní. Ohun táwọn ọ̀rẹ́ mi náà sì máa ń ṣe fún mi nìyẹn.” Ó máa dáa kíwọ náà ronú nípa àwọn tó o lè ràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé àwọn ṣeyebíye lójú Jèhófà.
MÁA RÁNTÍ PÉ JÈHÓFÀ MỌYÌ Ẹ
14. Kí ni 1 Sámúẹ́lì 16:7 sọ tó jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwa èèyàn? (Wo àpótí náà “ Kí Nìdí Táwa Ìránṣẹ́ Jèhófà Fi Ṣeyebíye Lójú Ẹ̀?”)
14 Máa rántí pé kì í ṣojú táwọn èèyàn fi ń wò ẹ́ ni Jèhófà fi ń wò ẹ́. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:7.) Nínú ayé, bí ẹnì kan bá ṣe rí, bó ṣe lẹ́nu tó láwùjọ tàbí bó ṣe kàwé tó ló máa ń pinnu bóyá ó máa níyì lójú àwọn èèyàn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà. (Àìsá. 55:8, 9) Torí náà, dípò kó o máa fi èrò àwọn èèyàn díwọ̀n ara ẹ, ṣe ni kó o máa wo ara ẹ bí Jèhófà ṣe ń wò ẹ́. O lè ka àwọn ìtàn Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà mọyì àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tí wọ́n rò pé àwọn ò wúlò, irú bí Èlíjà, Náómì àti Hánà. O sì lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó jẹ́ kó o gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì mọyì ẹ. Bákan náà, o tún lè ṣèwádìí nínú àwọn ìwé àtàwọn fídíò wa nípa bá a ṣe ṣeyebíye tó lójú Jèhófà. c
15. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé Dáníẹ́lì “ṣeyebíye gan-an”? (Dáníẹ́lì 9:23)
15 Máa rántí pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà torí pé o jẹ́ olóòótọ́. Nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì ti fẹ́ẹ̀ pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, ìgbà kan wà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, ó sì sọ pé: “Okun ti tán nínú mi pátápátá.” (Dán. 9:20, 21) Báwo ni Jèhófà ṣe fi í lọ́kàn balẹ̀? Ó rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sí i, ó sì sọ fún un pé, ó “ṣeyebíye gan-an” àti pé Jèhófà ti gbọ́ àdúrà ẹ̀. (Ka Dáníẹ́lì 9:23.) Kí ló mú kí Dáníẹ́lì ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run? Ìdí ni pé Dáníẹ́lì láwọn ànímọ́ tó dáa, lára ẹ̀ ni pé ó jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo. (Ìsík. 14:14) Jèhófà jẹ́ kí àkọsílẹ̀ yìí wà nínú Ọ̀rọ̀ ẹ̀ kó lè máa tù wá nínú. (Róòmù 15:4) Jèhófà tún máa ń gbọ́ àdúrà wa, ó sì mọyì bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́, tá a sì ń sin òun tọkàntọkàn.—Míkà 6:8, àlàyé ìsàlẹ̀; Héb. 6:10.
16. Kí ló máa jẹ́ kó o gbà pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ẹ ni Jèhófà?
16 Gbà pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ẹ ni Jèhófà. Kì í ṣe ibi tó o kù sí ni Jèhófà ń wá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm. 130:3; Mát. 7:11; Lúùkù 12:6, 7) Nígbà táwọn kan ronú lórí òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn ò ro ara wọn pin mọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Eliana tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ọ̀pọ̀ ọdún lọkọ ẹ̀ fi sọ̀rọ̀ burúkú sí i, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó ro ara ẹ̀ pin. Ó sọ pé, “Nígbàkigbà tó bá ń ṣe mí bíi pé mi ò wúlò, mo máa ń fojú inú wò ó pé Jèhófà gbé mi, ó ń ṣìkẹ́ mi, ó sì ń dáàbò bò mí.” (Sm. 28:9) Arábìnrin Lauren tó ń gbé ní South Africa máa ń rán ara ẹ̀ létí pé, “Tí Jèhófà bá lè fi okùn ìfẹ́ fà mí mọ́ra, tó mẹ́sẹ̀ mi dúró látọdún yìí wá, tó sì ti lò mí láti kọ́ àwọn míì, ó dá mi lójú pé mo wúlò, mo sì ṣeyebíye gan-an lójú ẹ̀.”—Hós. 11:4.
17. Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ? (Sáàmù 5:12)
17 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ń ṣojúure sí ẹ. (Ka Sáàmù 5:12.) Dáfídì fi ojúure Jèhófà wé “apata ńlá” tó ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́. Tó o bá ń rántí pé Jèhófà ń fi ojúure hàn sí ẹ, inú ẹ̀ sì ń dùn sí ẹ, kò ní jẹ́ kó o máa wo ara ẹ bí ẹni tí ò wúlò. Àmọ́, kí lá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ? Bá a ṣe sọ, ohun táá jẹ́ kó dá wa lójú ni pé, Jèhófà ń lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀ láti jẹ́ ká mọ̀ pé òun mọyì wa. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún ń lo àwọn alàgbà, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn míì láti rán wa létí pé a ṣeyebíye lójú òun. Kí ló yẹ kó o ṣe táwọn èèyàn bá gbóríyìn fún ẹ tí wọ́n sì sọ àwọn nǹkan dáadáa nípa ẹ?
Tá a bá ń rántí pé inú Jèhófà ń dùn sí wa, ìyẹn ò ní jẹ́ ká máa wo ara wa bí ẹni tí ò wúlò (Wo ìpínrọ̀ 16)
18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fojú kéré ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn sọ láti gbóríyìn fún wa?
18 Táwọn tó mọ̀ ẹ́ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ẹ bá gbóríyìn fún ẹ, má ṣe fojú kéré ọ̀rọ̀ wọn. Máa rántí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ni Jèhófà ń lò láti jẹ́ kó o mọ̀ pé inú òun dùn sí ẹ. Eliana tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Díẹ̀díẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì báwọn èèyàn ṣe ń gbóríyìn fún mi, tí wọ́n sì ń sọ ohun tó dáa nípa mi. Kò rọrùn fún mi, àmọ́ mo mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ nìyẹn.” Àwọn alàgbà ran Eliana lọ́wọ́, ìyẹn sì ṣe é láǹfààní gan-an. Ní báyìí, ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ó sì ń bá Bẹ́tẹ́lì ṣiṣẹ́ látilé.
19. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé a ṣeyebíye lójú Ọlọ́run?
19 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. (Lúùkù 12:24) Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì wa, ẹni ọ̀wọ́n la sì jẹ́ lójú ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí máa ró gbọnmọ-gbọnmọ lọ́kàn wa, ká sì jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọ́run!
ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Ó ṣeé ṣe kí Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin tó máa ń tẹ̀ lé Jésù tó bá ń rìnrìn àjò. Tinútinú làwọn obìnrin yìí máa ń lo ohun tí wọ́n ní láti bójú tó Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀.—Mátíù 27:55, 56; Lúùkù 8:1-3.
c Bí àpẹẹrẹ, wo orí 24 nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, kó o sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì àti àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ àkòrí náà, “Iyèméjì” nínú ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́.

