Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Mọ “Àwọn Orin Ẹ̀mí” Sórí

“Nígbà tí gbogbo nǹkan bá tojú sú mi, mo máa ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà tí mo bá gbọ́ àwọn orin JW Broadcasting®.” —Lorraine, U.S.A.

Àtìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ làwa Kristẹni ti máa ń kọ “àwọn orin ẹ̀mí.” (Kól. 3:16) Tó o bá mọ àwọn orin yìí sórí, wàá lè máa kọ àwọn orin náà tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò ní ìwé orin tàbí fóònù. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí, á rọrùn fún ẹ láti mọ àwọn orin náà sórí.

  • Fara balẹ̀ ka àwọn ọ̀rọ̀ orin náà kó o lè mọ ìtumọ̀ ẹ̀. Tó o bá mọ ìtumọ̀ nǹkan tó ò ń kà, wàá tètè máa rántí ẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ orin wa títí kan àwọn orin wa míì àtàwọn orin ọmọdé ló wà lórí jw.org. Wo abala Ohun Tá A Ní, lẹ́yìn náà lọ sí Orin.

  • Fọwọ́ kọ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sínú ìwé míì. Ìyẹn á jẹ́ kó o tètè máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà.—Diu. 17:18.

  • Máa kọrin náà sókè. Máa ka ọ̀rọ̀ orin náà, kó o sì máa kọ ọ́ léraléra.

  • Wò ó bóyá wàá lè rántí ẹ̀. Gbìyànjú ẹ̀ wò bóyá wàá rántí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà láìwo ìwé. Lẹ́yìn náà, wò ó bóyá o ti mọ̀ ọ́n kọ dáadáa.