ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 48
Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Nígbà Ìṣòro
‘Jẹ́ onígboyà, torí mo wà pẹ̀lú rẹ, ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.’—HÁG. 2:4.
ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1-2. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ wa ṣe jọ tàwọn Júù tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù? (b) Sọ ìṣòro táwọn Júù tó pa dà náà ní. (Wo àpótí náà, “ Àwọn Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ayé Hágáì, Sekaráyà àti Ẹ́sírà.”)
LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN, ṣé o máa ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ lọ́jọ́ iwájú? Ó lè jẹ́ pé iṣẹ́ bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́, tó o wá ń ronú ohun tí ìwọ àti ìdílé ẹ máa jẹ. O tún lè máa ronú nípa bó o ṣe máa dáàbò bo ìdílé ẹ nígbà táwọn ará ìlú bá ń bá ìjọba jà, tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa tàbí tí wọ́n ń ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé ọ̀kan lára àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wàá jàǹfààní gan-an tó o bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n nírú ìṣòro yẹn.
2 Ó gba ìgbàgbọ́ káwọn Júù tó ti lo gbogbo ìgbésí ayé wọn ní Bábílónì tó lè fibẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù tí ọ̀pọ̀ lára wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀. Ìdí sì ni pé nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù fún ọ̀pọ̀ lára wọn níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í níṣòro àtijẹ àtimu, àwọn èèyàn tí ìjọba Páṣíà ń ṣàkóso ń bá ara wọn jà, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wọn sì ń ta kò wọ́n. Ìyẹn jẹ́ kó ṣòro fáwọn kan lára wọn láti gbájú mọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà tí wọ́n ń tún kọ́. Torí náà, nígbà tó di nǹkan bí ọdún 520 Ṣ.S.K., Jèhófà rán wòlíì Hágáì àti Sekaráyà pé kí wọ́n lọ fún wọn lókun, kí wọ́n lè máa fìtara ṣiṣẹ́ Ọlọ́run. (Hág. 1:1; Sek. 1:1) A máa rí i pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wọn sọ fún wọn níṣìírí gan-an. Àmọ́ ní nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún lẹ́yìn náà, àwọn Júù yẹn rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì ń fẹ́ ìṣírí. Ẹ́sírà akọ̀wé Òfin Ọlọ́run tó jáfáfá wá sí Jerúsálẹ́mù láti Bábílónì kó lè fún àwọn Júù yẹn níṣìírí, kí wọ́n lè gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.—Ẹ́sírà 7:1, 6.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn? (Òwe 22:19)
3 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Hágáì àti Sekaráyà sọ ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ nígbà àtijọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń ta kò wọ́n, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á gbà wá nígbà ìṣòro. (Ka Òwe 22:19.) Bá a ṣe ń gbé iṣẹ́ tí Jèhófà rán Hágáì àti Sekaráyà yẹ̀ wò, tá a sì tún ń kẹ́kọ̀ọ́ lára Ẹ́sírà, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo nìṣòro táwọn Júù tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù ní ṣe dín ìtara wọn kù? Kí nìdí tó fi yẹ ká gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run nígbà ìṣòro? Báwo la sì ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lákòókò wàhálà?
BÍ ÌṢÒRO TÁWỌN JÚÙ TÓ PA DÀ NÍ ṢE DÍN ÌTARA WỌN KÙ
4-5. Kí ló ṣeé ṣe kó mú káwọn Júù má fi bẹ́ẹ̀ nítara mọ́ láti tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́?
4 Nígbà táwọn Júù pa dà dé Jerúsálẹ́mù, iṣẹ́ pọ̀ fún wọn láti ṣe. Láìjáfara, wọ́n kọ́ pẹpẹ Jèhófà, wọ́n sì fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀. (Ẹ́sírà 3:1-3, 10) Àmọ́ kò pẹ́ tí wọn ò fi nítara mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé yàtọ̀ sí tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́, wọ́n máa kọ́ ilé tara wọn, wọ́n máa dáko, wọ́n á sì wá nǹkan tí ìdílé wọn máa jẹ. (Ẹ́sírà 2:68, 70) Bákan náà, àwọn ọ̀tá ta kò wọ́n, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti dá iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́ dúró.—Ẹ́sírà 4:1-5.
5 Ohun míì tí ò jẹ́ káwọn Júù yẹn nítara mọ́ ni pé àtijẹ àtimu dogun, àwọn èèyàn tí ìjọba Páṣíà ń ṣàkóso ń bá ara wọn jà. Àwọn ará Páṣíà sì ti gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Kírúsì ọba Páṣíà kú lọ́dún 530 Ṣ.S.K., Kanbáísísì tó jọba lẹ́yìn ẹ̀ gbógun ja ilẹ̀ Íjíbítì kó lè gbà á. Nígbà tó ń lọ sí Íjíbítì, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ogun ẹ̀ gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kọjá, kí wọ́n sì ní kí wọ́n fún àwọn ní oúnjẹ, omi àti ibi táwọn máa gbé, ìyẹn sì lè mú kí nǹkan túbọ̀ nira fáwọn Júù yẹn. Lẹ́yìn tí Kanbáísísì kú, Dáríúsì Kìíní jọba. Kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀, tí wọ́n sì ń bá ìjọba jà. Àwọn nǹkan yìí mú káwọn Júù tó pa dà sílùú wọn máa ṣàníyàn nípa bí wọ́n á ṣe pèsè fún ìdílé wọn. Nítorí gbogbo ìṣòro tó dé bá wọn yìí, àwọn Júù kan rò pé kì í ṣe àsìkò yẹn ló yẹ káwọn tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́.—Hág. 1:2.
6. Àwọn ìṣòro míì wo ni Sekaráyà 4:6, 7 sọ pé àwọn Júù ní, kí ni Sekaráyà sì fi dá wọn lójú?
6 Ka Sekaráyà 4:6, 7. Yàtọ̀ sí ìṣòro àtijẹ àtimu táwọn Júù ní àtàwọn èèyàn tó ń bá ìjọba Páṣíà jà, wọ́n tún ṣenúnibíni sáwọn Júù. Nígbà tó fi máa dọdún 522 Ṣ.S.K., àwọn ọ̀tá mú kí ìjọba Páṣíà dá iṣẹ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà tí wọ́n ń kọ́ dúró. Àmọ́ Sekaráyà fi dá àwọn Júù yẹn lójú pé Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó láìka àtakò èyíkéyìí sí. Nígbà tó dọdún 520 Ṣ.S.K., Ọba Dáríúsì pàṣẹ pé kí wọ́n máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà nìṣó. Kódà, ó fún wọn lówó, ó sì tún ní káwọn gómìnà tó wà lágbègbè wọn ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ẹ́sírà 6:1, 6-10.
7. Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn Júù tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́ torí pé wọ́n fi ìjọsìn ẹ̀ sípò àkọ́kọ́?
7 Jèhófà ṣèlérí fáwọn èèyàn ẹ̀ nípasẹ̀ Hágáì àti Sekaráyà pé òun máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n bá gbájú mọ́ iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń tún kọ́. (Hág. 1:8, 13, 14; Sek. 1:3, 16) Ohun táwọn wòlíì yẹn sọ fáwọn Júù fún wọn níṣìírí gan-an, wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń tún kọ́ lọ́dún 520 Ṣ.S.K., wọ́n sì parí ẹ̀ kí ọdún márùn-ún tó pé. Torí pé àwọn Júù yẹn fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n níṣòro, Jèhófà pèsè ohun tí wọ́n nílò, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn ẹ̀.—Ẹ́sírà 6:14-16, 22.
GBÁJÚ MỌ́ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN
8. Báwo ni ohun tí Hágáì 2:4 sọ ṣe máa jẹ́ ká gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
8 Bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé, a mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká túbọ̀ máa wàásù fáwọn èèyàn. (Máàkù 13:10) Ó lè nira fún wa láti gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, pàápàá tá ò bá lówó lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n bá ń ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kí lá jẹ́ ká gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run? Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni tá a bá ń rántí pé “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” b wà pẹ̀lú wa. Ó máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn ẹ̀ dípò ọ̀rọ̀ tara wa. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ ṣojo.—Ka Hágáì 2:4.
9-10. Báwo ni tọkọtaya kan ṣe rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33?
9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Oleg àti Irina. c Tọkọtaya ni wọ́n, àwọn méjèèjì ló sì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn tí wọ́n dé ìjọ kan tí wọ́n lọ ràn lọ́wọ́, iṣẹ́ bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ torí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó tó nǹkan bí ọdún kan tí iṣẹ́ wọn ò fi lọ dáadáa, wọ́n ń rí ọwọ́ Jèhófà lára wọn. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà míì. Báwo ni wọ́n ṣe borí ìṣòro wọn? Ọ̀rọ̀ náà kọ́kọ́ kó ìdààmú bá Oleg, àmọ́ nígbà tó yá, ó sọ pé: “Bá a ṣe ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù ti ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé wa.” Kódà nígbà tóun àti ìyàwó ẹ̀ ṣì ń wá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n gbájú mọ́.
10 Nígbà tí wọ́n pa dà délé láti òde ìwàásù lọ́jọ́ kan, wọ́n rí i pé ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ kan ti rìnrìn àjò nǹkan bí ọgọ́jọ kìlómítà (160) wá sọ́dọ̀ wọn, ó sì gbé àpò oúnjẹ méjì wá fún wọn. Oleg sọ pé: “Lọ́jọ́ yẹn, a tún rí bí Jèhófà àtàwọn ará ṣe ń bójú tó wa. Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ kódà tí wọ́n bá ń rò pé kò sí ọ̀nà àbáyọ fáwọn.”—Mát. 6:33.
11. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run?
11 Jèhófà fẹ́ ká gbájú mọ́ iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Bá a ṣe sọ ní ìpínrọ̀ keje, Hágáì rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn lákọ̀tun, bí ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé òun ‘á bù kún wọn.’ (Hág. 2:18, 19) Ó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá wa tá a bá gbájú mọ́ iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́.
BÁ A ṢE LÈ TÚBỌ̀ GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ
12. Kí nìdí tí Ẹ́sírà àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára?
12 Lọ́dún 468 Ṣ.S.K., Ẹ́sírà rìnrìn àjò pẹ̀lú àwùjọ àwọn Júù kejì láti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Kí Ẹ́sírà àtàwọn tó ń pa dà náà tó lè rìnrìn àjò yìí, ó gba ìgbàgbọ́ tó lágbára. Ojú ọ̀nà tó léwu ni wọ́n máa gbà, wọ́n á sì kó ọ̀pọ̀ wúrà àti fàdákà tí ọba ní kí wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì dání. Ìyẹn sì lè mú kí àwọn adigunjalè dá wọn lọ́nà. (Ẹ́sírà 7:12-16; 8:31) Yàtọ̀ síyẹn, ewu wà ní Jerúsálẹ́mù náà torí pé àwọn tó wà níbẹ̀ ò pọ̀, ògiri ẹ̀ àtàwọn ẹnubodè ẹ̀ sì ti bà jẹ́. Kí la rí kọ́ lára Ẹ́sírà nípa bó ṣe yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
13. Báwo ni Ẹ́sírà ṣe túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
13 Ẹ́sírà ti rí bí Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àdánwò. Ní ọdún díẹ̀ ṣáájú 484 Ṣ.S.K., ó jọ pé Bábílónì ni Ẹ́sírà ń gbé nígbà tí Ọba Ahasuérúsì pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn Júù tó wà ní Ilẹ̀ Páṣíà run. (Ẹ́sít. 3:7, 13-15) Ó dájú pé ẹ̀mí Ẹ́sírà wà nínú ewu! Nígbà tí àwọn Júù “tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀” náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n ṣọ̀fọ̀, ó sì dájú pé wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà. (Ẹ́sít. 4:3) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Ẹ́sírà àtàwọn Júù yòókù nígbà tí ọ̀rọ̀ náà yí dà sórí àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa àwọn Júù! (Ẹ́sít. 9:1, 2) Àwọn nǹkan tójú Ẹ́sírà rí nígbà àdánwò yẹn máa jẹ́ kó múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro ọjọ́ iwájú, á sì jẹ́ kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. d
14. Kí ni arábìnrin kan rí kọ́ nígbà tí Jèhófà bójú tó o lákòókò tó níṣòro?
14 Tí Jèhófà bá bójú tó wa nígbà ìṣòro, ó máa ń túbọ̀ dá wa lójú pé á bójú tó wa lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Anastasia, tó ń gbé ní ìlà oòrùn Yúróòpù. Ó fi iṣẹ́ tó ń ṣe sílẹ̀ torí kò fẹ́ dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Ó sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ò sówó kankan lọ́wọ́ mi.” Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Mo fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, mo sì rí bó ṣe fìfẹ́ bójú tó mi. Tí iṣẹ́ bá tún bọ́ lọ́wọ́ mi, mi ò ní bẹ̀rù. Tí Bàbá mi ọ̀run bá bójú tó mi lónìí, ó dájú pé á bójú tó mi lọ́la.”
15. Kí ló mú kí Ẹ́sírà túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Ẹ́sírà 7:27, 28)
15 Ẹ́sírà rọ́wọ́ Jèhófà láyé ẹ̀. Bí Ẹ́sírà ṣe ń ronú nípa àwọn ìgbà tí Jèhófà ti ràn án lọ́wọ́ mú kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Kíyè sí ohun tó sọ, ó ní “ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run mi wà lára mi.” (Ka Ẹ́sírà 7:27, 28.) Kódà, ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ẹ́sírà lo irú ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Bíbélì tó kọ.—Ẹ́sírà 7:6, 9; 8:18, 22, 31.
Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa táá jẹ́ ká rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa? (Wo ìpínrọ̀ 16) e
16. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ ká túbọ̀ rọ́wọ́ Ọlọ́run láyé wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá wa ká lè lọ sí àpéjọ agbègbè tàbí tá a bá ní kí wọ́n yí àkókò iṣẹ́ wa pa dà ká lè ráyè máa wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ, àá rí ọwọ́ Jèhófà lára wa. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lè yà wá lẹ́nu gan-an. Ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
Ẹ́sírà ń sunkún, inú ẹ̀ sì bà jẹ́ bó ṣe ń gbàdúrà nínú tẹ́ńpìlì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn èèyàn náà sì ń sunkún. Ṣẹkanáyà tu Ẹ́sírà nínú, ó sì fi dá a lójú pé: “Ìrètí ṣì wà fún Ísírẹ́lì. . . . A sì wà pẹ̀lú rẹ.”—Ẹ́sírà 10:2, 4 (Wo ìpínrọ̀ 17)
17. Báwo ni Ẹ́sírà ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tó níṣòro? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
17 Ẹ́sírà fi ìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà tíṣẹ́ tó fẹ́ ṣe bá ti kà á láyà, ó máa ń fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà. (Ẹ́sírà 8:21-23; 9:3-5) Torí pé Ẹ́sírà gbára lé Jèhófà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ràn án lọ́wọ́, wọ́n sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó ní. (Ẹ́sírà 10:1-4) Tá a bá ń ṣàníyàn nípa àtijẹ àtimu tàbí nípa bá a ṣe máa dáàbò bo ìdílé wa, ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́.
18. Kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
18 Tá a bá fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, tá a sì tún jẹ́ káwọn ará ràn wá lọ́wọ́, àá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Gbogbo ìgbà ni Erika tó ń dá tọ́mọ mẹ́ta gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kódà láwọn ìgbà tó níṣòro. Lẹ́yìn tí ọmọ inú ẹ̀ kú, kò pẹ́ sígbà yẹn, ọkọ ẹ̀ náà kú. Nígbà tó ń rántí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “A ò lè mọ bí Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló máa ń yà wá lẹ́nu tá a bá rí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́. Mo ti rí i pé Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà mi torí ó lo àwọn ọ̀rẹ́ mi láti tù mí nínú, wọ́n sì tún ràn mí lọ́wọ́. Tí mo bá sọ ohun tó ń ṣe mí fún wọn, wọ́n á mọ bí wọ́n ṣe máa ràn mí lọ́wọ́.”
GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ TÍTÍ DÓPIN
19-20. Kí la kọ́ lára àwọn Júù tí kò ṣeé ṣe fún láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù?
19 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì lára àwọn Júù tí kò ṣeé ṣe fún láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn kan lára wọn ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ nítorí ọjọ́ ogbó, àìsàn tó le gan-an àti bí wọ́n ṣe máa pèsè fún ìdílé wọn. Síbẹ̀, wọ́n fún àwọn tó ń pa dà sí Jerúsálẹ́mù láwọn nǹkan tí wọ́n máa fi kọ́ tẹ́ńpìlì, tọkàntọkàn ni wọ́n sì fi ṣe é. (Ẹ́sírà 1:5, 6) Ó jọ pé ní nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlógún (19) lẹ́yìn táwọn Júù tó kọ́kọ́ fi Bábílónì sílẹ̀ dé Jerúsálẹ́mù, àwọn Júù tó ṣẹ́ kù sí Bábílónì ṣì ń fi ọrẹ ránṣẹ́ sáwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù.—Sek. 6:10.
20 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò lè ṣe tó bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe tọkàntọkàn, ó sì mọyì ẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Nígbà ayé Sekaráyà, Jèhófà sọ fún un pé kó fi wúrà àti fàdákà táwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì fi ránṣẹ́ ṣe adé kan. (Sek. 6:11) “Adé ńlá” náà á jẹ́ kí wọ́n máa rántí ọrẹ àtinúwá táwọn tó wà ní Bábílónì fi ránṣẹ́. (Sek. 6:14, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé gbogbo nǹkan táwa náà ń ṣe tọkàntọkàn bá a ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ nígbà ìṣòro.—Héb. 6:10.
21. Kí lá jẹ́ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú sí?
21 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí, àá ṣì máa níṣòro, kódà ó ṣeé ṣe kó burú ju báyìí lọ lọ́jọ́ iwájú. (2 Tím. 3:1, 13) Àmọ́, kò yẹ ká kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ. Máa rántí ohun tí Jèhófà sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ nígbà ayé Hágáì, ó sọ pé: “Mo wà pẹ̀lú yín . . . Ẹ má bẹ̀rù.” (Hág. 2:4, 5) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwa náà bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣohun tó fẹ́. Torí náà, tá a bá ń fi àwọn ẹ̀kọ́ inú àsọtẹ́lẹ̀ Hágáì àti Sekaráyà sílò, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹ́sírà, àá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìka àwọn ìṣòro tó lè dé bá wa lọ́jọ́ iwájú sí.
ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!
a Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tá ò bá lówó lọ́wọ́, táwọn ará ìlú bá ń bá ìjọba jà tàbí tí wọ́n bá ń ta kò wá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
b Gbólóhùn náà “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” fara hàn nígbà mẹ́rìnlá (14) nínú ìwé Hágáì, ó sì rán àwọn Júù àtàwa náà létí pé agbára Jèhófà ò láàlà àti pé ó ń darí àìmọye àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogun ẹ̀.—Sm. 103:20, 21.
c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
d Akọ̀wé Òfin Ọlọ́run tó já fáfá ni Ẹ́sírà, ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ, kódà kó tó rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù.—2 Kíró. 36:22, 23; Ẹ́sírà 7:6, 9, 10; Jer. 29:14.
e ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń sọ fún ọ̀gá ẹ̀ pé kó fún òun láyè láti lọ sí àpéjọ agbègbè, àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀. Nígbà tó fẹ́ pa dà lọ bá ọ̀gá ẹ̀, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Ó fi ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ náà han ọ̀gá ẹ̀, ó sì ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ máa ń jẹ́ ká níwà tó dáa. Ohun tó sọ yẹn wú ọ̀gá ẹ̀ lórí, ó sì jẹ́ kó lọ sí àpéjọ yẹn.