Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 46

Jèhófà Fi Dá Wa Lójú Pé Òun Máa Sọ Ayé Di Párádísè

Jèhófà Fi Dá Wa Lójú Pé Òun Máa Sọ Ayé Di Párádísè

“Ọlọ́run òtítọ́ [máa] bù kún ẹnikẹ́ni tó bá ń wá ìbùkún fún ara rẹ̀ ní ayé.”—ÀÌSÁ. 65:16.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí ni wòlíì Àìsáyà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

 WÒLÍÌ Àìsáyà pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òtítọ́.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “òtítọ́” túmọ̀ sí “àmín.” (Àìsá. 65:16, àlàyé ìsàlẹ̀) Ọ̀rọ̀ náà “àmín” túmọ̀ sí “kí ó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “dájúdájú.” Nínú Bíbélì, tí wọ́n bá lo “àmín” níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà tàbí Jésù, ó máa ń jẹ́ kó dáni lójú pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n ń sọ. Torí náà, nǹkan tí wòlíì Àìsáyà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa yé wọn. Ohun tó sọ ni pé: Ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ, dandan ni kó ṣẹ. Jèhófà sì ti fi hàn pé bó ṣe rí nìyẹn torí gbogbo ìlérí ẹ̀ ló ń ṣẹ.

2. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí tó ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la ṣẹ, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?

2 Ṣé ó dá wa lójú pé àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la máa ṣẹ? Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́jọ (800) lẹ́yìn tí Àìsáyà kú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ń ṣẹ. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ọlọ́run ò lè parọ́.’ (Héb. 6:18) Bí ìsun omi kan ò ṣe lè sun omi tó níyọ̀ àtèyí tí ò níyọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́ kò lè parọ́. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká fọkàn tán Jèhófà pátápátá pé ó máa ṣe ohun tó bá sọ, ó sì máa mú àwọn ìlérí tó ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la ṣẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú? Báwo ni Jèhófà ṣe fi dá wa lójú pé òun máa mú àwọn ìlérí náà ṣẹ?

ÌLÉRÍ WO NI JÈHÓFÀ ṢE?

3. (a) Ìlérí wo làwa èèyàn Jèhófà fẹ́ràn gan-an? (Ìfihàn 21:3, 4) (b) Kí làwọn kan máa ń sọ tá a bá ń wàásù nípa ìlérí náà fún wọn?

3 Àwa èèyàn Jèhófà fẹ́ràn ìlérí tó ṣe tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ báyìí. (Ka Ìfihàn 21:3, 4.) Jèhófà ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ikú ò ní sí mọ́, [tí] kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Ọ̀pọ̀ lára wa ló máa ń ka ẹsẹ Bíbélì yìí tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè, ó sì máa ń múnú wọn dùn. Kí làwọn kan máa ń sọ tá a bá sọ ìlérí náà fún wọn? Àwọn kan máa ń sọ pé: “Àlá tí ò lè ṣẹ ni.”

4. (a) Nígbà tí Jèhófà ṣèlérí pé Párádísè máa dé, kí ló mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí? (b) Yàtọ̀ sí ìlérí tí Jèhófà ṣe, nǹkan míì wo ló tún ṣe?

4 Nígbà tí Jèhófà darí àpọ́sítélì Jòhánù pé kó kọ ìlérí tóun ṣe nípa Párádísè sílẹ̀, Jèhófà mọ̀ pé àwa Kristẹni máa wàásù nípa ẹ̀ fáwọn èèyàn lónìí. Jèhófà tún mọ̀ pé ó máa ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gba “àwọn nǹkan tuntun” tóun ṣèlérí gbọ́. (Àìsá. 42:9; 60:2; 2 Kọ́r. 4:3, 4) Torí náà, báwo la ṣe lè jẹ́ kó dá àwa àtàwọn tá à ń wàásù fún lójú pé àwọn ohun rere tí Jèhófà sọ nínú Ìfihàn 21:3, 4 máa ṣẹ lóòótọ́? Kì í kàn ṣe pé Jèhófà ṣe àwọn ìlérí tó ń múnú wa dùn nìkan ni, ó tún jẹ́ ká rí àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Àwọn ẹ̀rí wo nìyẹn?

JÈHÓFÀ JẸ́ KÓ DÁ WA LÓJÚ PÉ ÒUN MÁA MÚ ÌLÉRÍ ÒUN ṢẸ

5. Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ló mú kó dá wa lójú pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé, kí làwọn ẹsẹ Bíbélì náà sì sọ?

5 Àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ ká gbà pé Párádísè tí Jèhófà ṣèlérí máa dé wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fẹ́ sọ yìí. Àwọn ẹsẹ náà sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Ó tún sọ pé: ‘Kọ ọ́ sílẹ̀, torí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.’ Ó sọ fún mi pé: ‘Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀! Èmi ni Ááfà àti Ómégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.’”—Ìfi. 21:5, 6a.

6. Báwo làwọn ìlérí tó dájú tó wà ní Ìfihàn 21:5, 6 ṣe túbọ̀ jẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run máa ṣe ohun tó sọ?

6 Báwo làwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe túbọ̀ jẹ́ ká gbà pé Ọlọ́run máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ? Nígbà tí ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ó sọ pé: “Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ń fọwọ́ sí ìwé ẹ̀rí ìmúdánilójú tàbí ìwé ẹ̀rí jíjẹ́ oníǹkan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún aráyé onígbọràn pé wọ́n á gba àwọn ìbùkún wọ̀nyí lọ́jọ́ iwájú.” b Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí wà nínú Ìfihàn 21:3, 4. Àmọ́ ní ẹsẹ 5 àti 6, Jèhófà sọ nǹkan kan níbẹ̀ tó fi dá wa lójú pé òun máa mú àwọn ìlérí òun ṣẹ. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ.

7. Ta ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà ní Ìfihàn 21:5, kí sì nìdí tí ọ̀rọ̀ náà fi ṣe pàtàkì?

7 Ohun tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ karùn-ún ni pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé.” (Ìfi. 21:5a) Ọ̀rọ̀ yìí ló ṣáájú ọ̀kan lára ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú ìwé Ìfihàn. Kì í ṣe áńgẹ́lì alágbára kan, kódà kì í ṣe Jésù tó ti jíǹde ló ṣe ìlérí yìí, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣe ìlérí náà! Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló sọ ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé a lè gba àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e nínú ẹsẹ yẹn gbọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé Jèhófà “kò lè parọ́.” (Títù 1:2) Torí náà, ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìfihàn 21:5, 6 máa ṣẹ.

“WÒ Ó! MÒ Ń SỌ OHUN GBOGBO DI TUNTUN”

8. Báwo ni Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ọn pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ? (Àìsáyà 46:10)

8 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e, ìyẹn “Wò ó!” (Ìfi. 21:5) Léraléra ni wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí wọ́n tú sí “wò ó!” nínú ìwé Ìfihàn. Ìwé ìwádìí kan sọ pé tí wọ́n bá fi àmì ìyanu síwájú ọ̀rọ̀ kan, “ńṣe nìyẹn ń sọ fún ẹni tó ń ka ìwé náà pé kó fara balẹ̀ kíyè sí gbólóhùn tó tẹ̀ lé e.” Gbólóhùn wo ni Jèhófà sọ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ náà “Wò ó!”? Ó sọ pé: “Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Òótọ́ ni pé ọjọ́ iwájú ni Jèhófà máa ṣe àwọn nǹkan tó sọ yìí, àmọ́ torí pé ó dá a lójú pé òun máa ṣe é, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé àwọn nǹkan náà ti ń ṣẹ.—Ka Àìsáyà 46:10.

9. (a) Nígbà tí Jèhófà sọ pé òun máa “sọ ohun gbogbo di tuntun,” àwọn nǹkan méjì wo ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí “ọ̀run” àti “ayé” tó wà tẹ́lẹ̀?

9 Ẹ jẹ́ ká wo gbólóhùn tó tẹ̀ lé e nínú Ìfihàn 21:5, ìyẹn “Sọ ohun gbogbo di tuntun.” Nínú orí Bíbélì yẹn, gbólóhùn yìí ń sọ àwọn nǹkan méjì tí Jèhófà máa ṣe. Kí ni ohun àkọ́kọ́ tí Jèhófà máa ṣe? Ohun àkọ́kọ́ tó máa ṣe ni pé ó máa pa ọ̀run àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ run, ìkejì sì ni pé ó máa fi ọ̀run tuntun àti ayé tuntun rọ́pò ẹ̀. Ìfihàn 21:1 sọ pé: “Ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀ àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ ti kọjá lọ.” “Ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀” ni àwọn ìjọba ayé tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ń darí. (Mát. 4:8, 9; 1 Jòh. 5:19) Nígbà míì tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ayé,” àwọn èèyàn tó ń gbé inú ẹ̀ ló ń sọ nípa ẹ̀. (Jẹ́n. 11:1; Sm. 96:1) Torí náà, “ayé tó wà tẹ́lẹ̀” ni àwọn èèyàn burúkú tó wà láyé lónìí. Kì í ṣe pé Jèhófà máa dá “ọ̀run” tàbí “ayé” míì, àmọ́ àwọn èèyàn burúkú inú ẹ̀ ló máa pa run. Ọlọ́run máa mú ọ̀run àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ kúrò, á sì fi “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” rọ́pò ẹ̀, ìyẹn ìjọba tuntun tí Ọlọ́run máa gbé kalẹ̀, táá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn èèyàn olódodo.

10. Kí ni Jèhófà máa sọ di tuntun?

10 Nínú Ìfihàn 21:5, Jèhófà tún sọ nípa àwọn nǹkan tóun máa sọ di tuntun. Kíyè sí pé Jèhófà ò sọ pé: “Mò ń dá àwọn ohun tuntun.” Kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan tó sọ ni pé: “Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Torí náà, Jèhófà máa sọ ayé yìí àtàwọn èèyàn tó ń gbé inú ẹ̀ di tuntun, á sì jẹ́ kí wọ́n di pípé. Bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, gbogbo ayé pátápátá máa di ọgbà ẹlẹ́wà kan bíi ti ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà tún máa sọ wá di tuntun torí pé ó máa wo ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sàn. Ó máa wo àwọn tó yarọ, àwọn tí ò ríran àtàwọn adití sàn, kódà ó máa jí àwọn tó ti kú dìde.—Àìsá. 25:8; 35:1-7.

“ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ YÌÍ ṢEÉ GBÁRA LÉ, ÒÓTỌ́ SÌ NI. . . . WỌ́N TI RÍ BẸ́Ẹ̀!”

11. Kí ni Jèhófà sọ fún Jòhánù pé kó ṣe, kí sì nìdí tó fi ní kó ṣe bẹ́ẹ̀?

11 Nǹkan míì wo ni Jèhófà sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ? Jèhófà sọ fún Jòhánù pé: “Kọ ọ́ sílẹ̀, torí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.” (Ìfi. 21:5) Kì í kàn ṣe pé Jèhófà sọ fún Jòhánù pé kó “kọ” àwọn ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ nìkan ni, ó tún sọ ìdí tó fi ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Torí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.” Ìyẹn ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì péye. A mà dúpẹ́ o pé Jòhánù ṣègbọràn sí Jèhófà pé kó “kọ” ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa kà nípa Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí, ká sì máa ronú nípa àwọn ohun rere tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

12. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé: “Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!”?

12 Kí ni Jèhófà sọ ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e? Ó sọ pé: “Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!” (Ìfi. 21:6) Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yìí bíi pé gbogbo nǹkan tó ṣèlérí nípa Párádísè ti ṣẹ. Jèhófà sì lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ kó má mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, Jèhófà tún sọ nǹkan míì tó jẹ́ kó dá wa lójú háún-háún pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Kí ló sọ?

“ÈMI NI ÁÁFÀ ÀTI ÓMÉGÀ”

13. Kí nìdí tí Jèhófà fi pe ara ẹ̀ ní “Ááfà àti Ómégà”?

13 Bá a ṣe sọ níṣàájú, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà fúnra ẹ̀ bá Jòhánù sọ̀rọ̀ nínú ìran. (Ìfi. 1:8; 21:5, 6; 22:13) Ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì ni Jèhófà lo gbólóhùn náà: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà.” Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, ómégà sì ni lẹ́tà tó kẹ́yìn. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ pé òun ni “Ááfà àti Ómégà,” ohun tó ń sọ ni pé tóun bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan, ó dájú pé òun máa parí ẹ̀.

Tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan, ó máa ń parí ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 14, 17)

14. (a) Sọ àpẹẹrẹ ìgbà tí Jèhófà sọ pé “Ááfà” àti ìgbà tó máa sọ pé “Ómégà.” (b) Kí ni Jèhófà sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:1-3 tó fi hàn pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ?

14 Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà, ó sọ ìdí tóun fi dá ayé àtàwa èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’” (Jẹ́n. 1:28) Ìgbà tí Jèhófà sọ̀rọ̀ yìí ni “Ááfà.” Àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn bá kún ayé, tí wọ́n sì sọ ọ́ di Párádísè ni Jèhófà máa sọ pé “Ómégà.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá “ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn” tán, ó sọ ohun tó fi hàn pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ. Ohun tó sọ wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:1-3. (Kà á.) Jèhófà ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ torí ó sọ pé ó jẹ́ mímọ́. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ìyẹn ni pé Jèhófà máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fáwa èèyàn àti ayé ní òpin ọjọ́ keje.

15. Kí nìdí tó fi dà bíi pé Sátánì ti dí Jèhófà lọ́wọ́ láti mú ìlérí tó ṣe fún aráyé ṣẹ?

15 Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ọmọ wọn náà sì jogún ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Torí náà, ó lè dà bíi pé Sátánì ti dí Jèhófà lọ́wọ́ láti mú ìlérí tó ṣe fún aráyé ṣẹ, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn pípé táá máa ṣègbọràn kún ayé. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Sátánì ò fẹ́ kí Jèhófà sọ pé “Ómégà.” Ó ṣeé ṣe kí Sátánì máa rò pé Jèhófà ò lè rí ojúùtú ọ̀rọ̀ náà mọ́. Ọ̀kan lára ohun tó lè máa rò ni pé kí Jèhófà pa Ádámù àti Éfà, kó sì dá tọkọtaya míì tó jẹ́ pípé, kó lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Àmọ́ ká ní ohun tí Jèhófà ṣe nìyẹn, ńṣe ni Èṣù máa sọ pé òpùrọ́ ni Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:28, Jèhófà ti sọ fún Ádámù àti Éfà pé àtọmọdọ́mọ wọn máa kún ayé.

16. Nǹkan míì wo ni Sátánì rò pé Jèhófà máa ṣe, tí ò ní jẹ́ kó mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ?

16 Kí ni nǹkan míì tó ṣeé ṣe kí Sátánì rò pé Jèhófà máa ṣe? Ó ṣeé ṣe kí Sátánì máa rò pé Jèhófà máa fàyè gba Ádámù àti Éfà kí wọ́n bí àwọn ọmọ aláìpé tí wọn ò ní lè di ẹni pípé láé. (Oníw. 7:20; Róòmù 3:23) Ká sọ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn ni, kò sí àní-àní pé ńṣe ni Sátánì máa fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, ìyẹn ni pé káwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ pípé, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn kún ayé.

17. Nígbà tí Sátánì, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe yanjú ẹ̀, kí nìyẹn sì máa yọrí sí lọ́jọ́ iwájú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Nígbà tí Sátánì, Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà yanjú ẹ̀ lọ́nà tí Sátánì ò lérò. (Sm. 92:5) Jèhófà mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ nígbà tó jẹ́ kí Ádámù àti Éfà bímọ, ìyẹn sì fi hàn pé kì í ṣe òpùrọ́. Jèhófà ti fi hàn pé òun kì í ṣe aláṣetì torí gbogbo ohun tó bá sọ pé òun máa ṣe ló máa ń ṣe. Ó ṣe ohun tó jẹ́ kí ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ìyẹn bó ṣe pèsè “ọmọ” tó máa gba àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tó jẹ́ onígbọràn là. (Jẹ́n. 3:15; 22:18) Bí Jèhófà ṣe gbà kí ọmọ ẹ̀ kú láti ra aráyé pa dà ya Sátánì lẹ́nu gan-an torí ibi tó fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀! Kí nìdí? Ìdí ni pé ìràpadà jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì mọ tara ẹ̀ nìkan. (Mát. 20:28; Jòh. 3:16) Àmọ́ Sátánì ò nífẹ̀ẹ́ wa torí onímọ-tara-ẹni-nìkan ni. Torí náà, kí ló máa jẹ́ àbájáde ìràpadà tí Jèhófà pèsè yìí? Tó bá fi máa di òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn á ti di pípé, wọ́n á sì máa gbé ayé nínú Párádísè bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. Ìgbà yẹn ni Jèhófà máa sọ pé “Ómégà.”

BÁ A ṢE LÈ JẸ́ KÓ TÚBỌ̀ DÁ WA LÓJÚ PÉ PÁRÁDÍSÈ MÁA DÉ

18. Nǹkan mẹ́ta wo ni Jèhófà sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ? (Wo àpótí náà “ Nǹkan Mẹ́ta Tó Jẹ́ Kó Dá Wa Lójú Pé Jèhófà Máa Mú Ìlérí Ẹ̀ Ṣẹ.”)

18 Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tá a ti jíròrò, kí la lè sọ fáwọn tí ò gbà pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé? Àkọ́kọ́, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣèlérí yẹn. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” Jèhófà ní ọgbọ́n àti agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ohun tó sì fẹ́ ṣe nìyẹn. Ìkejì, ó dá Jèhófà lójú háún-háún pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé ó ti ṣẹ. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni. . . . Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!” Ìkẹta, tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ ohun kan, ó dájú pé ó máa parí ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà.” Torí náà, Jèhófà máa fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, kò sì lè dí òun lọ́wọ́ láti mú ìlérí òun ṣẹ.

19. Táwọn èèyàn ò bá gbà pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé, kí lo lè ṣe?

19 Rántí pé ní gbogbo ìgbà tó o bá ń wàásù fáwọn èèyàn nípa Párádísè tí Jèhófà ṣèlérí, ńṣe lò ń jẹ́ kí àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ dá ẹ lójú. Torí náà, nígbà míì tó o bá ń ka ìlérí Párádísè tó ń múnú wa dùn yìí fún ẹni tó ò ń wàásù fún nínú Ìfihàn 21:4, tẹ́ni náà sì sọ pé, “Àlá tí ò lè ṣẹ ni,” kí lo máa ṣe? O ò ṣe ka ẹsẹ karùn-ún àti ìkẹfà fún ẹni náà, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀? O lè jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé Jèhófà ti fi dá wa lójú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, òun sì ti fi òòtẹ̀ lù ú.—Àìsá. 65:16.

ORIN 145 Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè

a Jèhófà ṣèlérí pé Párádísè máa dé. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe fi dá wa lójú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ. Gbogbo ìgbà tá a bá ń sọ fáwọn èèyàn pé Párádísè máa dé, ńṣe là ń jẹ́ kí àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe túbọ̀ dá wa lójú.