Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Dáàbò Bò Mí Torí Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé E

Jèhófà Dáàbò Bò Mí Torí Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé E

TÁWỌN èèyàn bá bi mí pé àwọn nǹkan wo ni mo ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo sábà máa ń sọ fún wọn pé “Ńṣe ni mo dà bí báàgì tí wọ́n ń kó nǹkan sí, tí Jèhófà ń gbé káàkiri lọ síbi tó bá fẹ́!” Ohun tí mò ń sọ ni pé bí mo ṣe máa ń gbé báàgì tí mò ń kẹ́rù sí lọ síbi tó bá wù mí, bẹ́ẹ̀ náà ni mo ṣe fẹ́ kí Jèhófà àti ètò ẹ̀ máa darí mi lọ síbi tó wù wọ́n àti nígbà tó bá wù wọ́n. Mo ti gba àwọn iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún mi tó gba pé kí n yááfì àwọn nǹkan kan, nígbà míì sì rèé àwọn iṣẹ́ náà máa ń léwu. Àmọ́, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé tí mo bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa dáàbò bò mí.

BÍ MO ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA JÈHÓFÀ TÍ MO SÌ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í GBẸ́KẸ̀ LÉ E

Wọ́n bí mi lọ́dún 1948 ní abúlé kékeré kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Nígbà yẹn, àbúrò bàbá mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Moustapha àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Wahabi ti ṣèrìbọmi, wọ́n sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, bàbá mi kú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà mí nínú jẹ́ gan-an. Wahabi ẹ̀gbọ́n mi sọ fún mi pé a lè pa dà rí bàbá wa nígbà àjíǹde. Ọ̀rọ̀ ìtùnú tó sọ fún mi yìí mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1963, kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjì àti àbúrò mi ọkùnrin náà ṣèrìbọmi.

Lọ́dún 1965, mo kó lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi tó ń jẹ́ Wilson nílùú Èkó, mo sì gbádùn bí mo ṣe ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó wà níjọ Igbobi. Bí mo ṣe rí i pé wọ́n ń láyọ̀, tí wọ́n sì nítara jẹ́ kémi náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní January 1968.

Arákùnrin Albert Olugbebi tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ṣètò ìpàdé pàtàkì kan pẹ̀lú àwa ọ̀dọ́, ó sì sọ pé a nílò àwọn tó máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Mo ṣì rántí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Olugbebi fi gbà wá níyànjú, ó ní: “Ọ̀dọ́ ni yín, ẹ ṣì lè lo àkókò àti okun yín fún Jèhófà. Iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà!” Torí pé ó ń wù mí kí n fara wé wòlíì Àìsáyà tó yọ̀ǹda ara ẹ̀, wọ́n fún mi ní fọ́ọ̀mù aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, mo sì buwọ́ lù ú.—Àìsá. 6:8.

Nígbà tó di May 1968, ètò Ọlọ́run ní kí n lọ máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Kano ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àsìkò yẹn ni Ogun Biafra tó wáyé lọ́dún 1967 sí 1970 ń lọ lọ́wọ́ ní gbogbo agbègbè yẹn, ẹ̀yìn ìgbà yẹn sì ni ogun náà dé gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àmọ́, arákùnrin kan ò fẹ́ kí n lọ torí kò fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí mi. Torí náà, mo sọ fún un pé: “O ṣeun gan-an, mo mọrírì ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí n lọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó dá mi lójú pé ó máa wà pẹ̀lú mi.”

MO GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ NÍ AGBÈGBÈ TÍ OGUN TI ṢỌṢẸ́

Bí ogun ṣe ṣọṣẹ́ nílùú Kano bani nínú jẹ́ gan-an. Ogun abẹ́lé yẹn ti pa ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì ti fìyà jẹ wọ́n gan-an. Nígbà míì tá a bá ń wàásù, a máa ń rí òkú àwọn èèyàn tí wọ́n pa nípakúpa nígbà ogun náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọ tó wà ní Kano pọ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti sá kúrò nílùú. Àwọn ará tó ṣẹ́ kù sílùú ò tó mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), ọkàn tiwọn náà ò sì balẹ̀. Inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn dùn gan-an nígbà táwa aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́fà dé síbẹ̀. A fún wọn níṣìírí, ìyẹn sì jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀. A ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé, kí wọ́n máa wàásù, kí wọ́n máa fi ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí wọ́n sì máa béèrè àwọn ìwé tí wọ́n nílò.

Àwa aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Haúsá. Torí pé èdè wọn la fi ń wàásù fún wọn, ọ̀pọ̀ wọn máa ń tẹ́tí sí wa. Àmọ́, àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tó wọ́pọ̀ jù níbẹ̀ ò fẹ́ ká máa wàásù, torí náà a máa ń ṣọ́ra gan-an. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan yọ ọ̀bẹ jáde, ó sì fi lé èmi àti arákùnrin tá a jọ ń wàásù. Jèhófà kó wa yọ torí ọkùnrin náà lé wa, àmọ́ kò lé wa bá! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé agbègbè yẹn léwu gan-an, Jèhófà ń jẹ́ ká máa “gbé láìséwu” níbẹ̀, àwọn ará sì ń pọ̀ sí i. (Sm. 4:8) Ní báyìí, ìjọ mọ́kànlá (11) ló wà nílùú Kano, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lọ ló sì wà níbẹ̀.

WỌ́N ṢENÚNIBÍNI SÍ WA LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ NIGER

Ìgbà tí mò ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Niamey, Niger

Nígbà tó di August 1968, lẹ́yìn tá a lo oṣù mélòó kan nílùú Kano, ètò Ọlọ́run rán èmi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì lọ sílùú Niamey, tó jẹ́ olú ìlú Republic of Niger. Lẹ́yìn tá a dé orílẹ̀-èdè Niger ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, kò pẹ́ rárá tá a fi mọ̀ pé ibẹ̀ wà lára àwọn agbègbè tó gbóná jù lọ láyé. Yàtọ̀ sí pé ká fara da ooru tó wà lágbègbè yẹn, ó tún gba pé ká kọ́ èdè Faransé tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń sọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí ò rọrùn, èmi àtàwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nílùú yẹn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a sì ń wàásù. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó mọ̀wé kà ní Niamey ló ti gba ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. Kódà, àwọn tí kò tíì ní ìwé náà máa ń wá sọ́dọ̀ wa kí wọ́n lè gba tiwọn!

Kò pẹ́ tá a fi mọ̀ pé àwọn aláṣẹ ìjọba orílẹ̀-èdè yẹn ò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní July 1969, a ṣe àpéjọ àyíká àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè yẹn, nǹkan bí ogún (20) èèyàn ló sì wá síbẹ̀. Ní àpéjọ yẹn, àwọn arákùnrin méjì ló fẹ́ ṣèrìbọmi. Àmọ́ ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà, àwọn ọlọ́pàá dé, wọ́n sì ní a ò gbọ́dọ̀ ṣe àpéjọ náà. Bí wọ́n ṣe mú àwa aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti alábòójútó àyíká lọ sí àgọ́ wọn nìyẹn. Lẹ́yìn tí wọ́n bi wá láwọn ìbéèrè kan, wọ́n ní ká pa dà wá lọ́jọ́ kejì. Nígbà tá a rí i pé àwọn aláṣẹ ìjọba fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀, a ṣètò pé ká sọ àsọyé ìrìbọmi nílé ọ̀kan lára àwọn ará, a sì dọ́gbọ́n kó àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi lọ sí odò tá a ti ṣèrìbọmi fún wọn.

Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé sọ pé kémi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe márùn-ún yòókù kúrò ní orílẹ̀-èdè yẹn. Wọ́n láwọn fún wa ní ọjọ́ méjì péré, ọ̀rọ̀ náà wá di alátiṣe ló mọ àtiṣe ara ẹ̀. Kíá la ṣe ohun tí wọ́n sọ, a forí lé ẹ̀ka ọ́fíìsì Nàìjíríà, wọ́n sì yan ibòmíì tá a ti máa ṣiṣẹ́ fún wa.

Wọ́n ní kí n máa lọ ṣiṣẹ́ ní abúlé kan tó ń jẹ́ Orisunbare lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èmi àtàwọn ará tó wà níbẹ̀ jọ máa ń wàásù, a sì máa ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí n ṣètò bí màá ṣe pa dà sí orílẹ̀-èdè Niger. Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́, ó yà mí lẹ́nu, ẹ̀rù bà mí, àmọ́ ó wù mí láti tún pa dà rí àwọn ará lórílẹ̀-èdè Niger!

Mo pa dà sílùú Niamey. Ní ọjọ́ kejì tí mo débẹ̀, ọkùnrin oníṣòwò kan tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi mí láwọn ìbéèrè kan nípa Bíbélì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó yá kò mu sìgá mọ́, kò sì mutí lámujù mọ́, lẹ́yìn náà ó ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, inú mi dùn bí mo ṣe ń wàásù pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lónírúurú agbègbè lórílẹ̀-èdè Niger. Nígbà tí mo pa dà débẹ̀, àwọn ará mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló wà níbẹ̀, àmọ́ nígbà tí mo fi máa kúrò níbẹ̀, wọ́n ti di mọ́kàndínláàádọ́rin (69).

“A Ò MỌ OHUN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ARÁ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ GUINEA”

Ní December 1977, mo pa dà sí Nàìjíríà láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tá a fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà parí, Arákùnrin Malcolm Vigo tó jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé kí n ka lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Sierra Leone kọ sí wa. Nínú lẹ́tà yẹn, àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó ń wá arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà tí ò níyàwó, tí ìlera ẹ̀ jí pépé, tó sì lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Faransé láti wá ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ní Guinea. Arákùnrin Vigo sọ fún mi pé wọ́n ti dá mi lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ yẹn. Wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé iṣẹ́ yẹn kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn. Torí náà, wọ́n sọ pé: “Rò ó dáadáa kó o tó fèsì o.” Ojú ẹsẹ̀ ni mo dáhùn pé: “Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ló rán mi níṣẹ́, màá lọ.”

Mo wọkọ̀ òfúrufú lọ sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone, èmi àtàwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó ní ẹ̀ka ọ́fíìsì sì ríra wa. Arákùnrin kan tó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ fún mi pé, “A ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará lórílẹ̀-èdè Guinea.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì Sierra Leone tó wà nítòsí Guinea ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù orílẹ̀-èdè náà, kò ṣeé ṣe láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará nítorí rògbòdìyàn òṣèlú tó wà níbẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ti gbìyànjú gan-an lọ́pọ̀ ìgbà láti rán arákùnrin kan lọ sí Guinea kó lè bẹ àwọn ará wò, àmọ́ kò ṣeé ṣe. Torí náà, ètò Ọlọ́run ní kí n rìnrìn àjò lọ sí Conakry tó jẹ́ olú ìlú Guinea, kí n lè gba ìwé ìgbélùú.

“Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ló rán mi níṣẹ́, màá lọ”

Nígbà tí mo dé ìlú Conakry, mo lọ rí aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọ́fíìsì ẹ̀. Mo sọ fún un pé ó wù mí kí n máa wàásù lórílẹ̀-èdè Guinea. Ó gbà mí níyànjú pé kí n má dúró torí pé wọ́n lè fàṣẹ ọba mú mi tàbí kí wọ́n ṣe mí ní jàǹbá. Ó wá sọ pé: “Pa dà sí Nàìjíríà kó o lọ máa wàásù níbẹ̀,” èmi náà sì dá a lóhùn pé, “Mo ti pinnu pé ibí ni màá ti máa wàásù.” Torí náà, ó kọ lẹ́tà sí Mínísítà Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé ní Guinea pé kó ràn mí lọ́wọ́, mínísítà náà sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo pa dà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Sierra Leone, mo sì sọ ìpinnu mínísítà náà fáwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó. Inú àwọn arákùnrin náà dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jèhófà jẹ́ kí ibi tí mo lọ yọrí sí rere. Ìjọba orílẹ̀-èdè yẹn ti gbà mí láyè kí n máa gbébẹ̀!

Ìgbà tí mò ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ní Sierra Leone

Lọ́dún 1978 sí 1989, mo ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Guinea àti Sierra Leone, mo sì ṣe adelé alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Làìbéríà. Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, mo sábà máa ń ṣàìsàn, ìyẹn sì máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì tí mo bá wà ní ìgbèríko, àmọ́ àwọn ará máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti gbé mi lọ sílé ìwòsàn.

Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí àìsàn ibà tó le gan-an ṣe mí, tí aràn inú sì ń dà mí láàmú. Ìgbà tára mi yá ni mo wá mọ̀ pé àwọn ará ti ń ronú ibi tí wọ́n máa sin mí sí, tó bá ṣẹlẹ̀ pé mo kú! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn fẹ́ gbẹ̀mí mi, mi ò rò ó rí pé màá fi iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún mi sílẹ̀. Ó dá mi lójú pé kò sẹ́ni tó lè dáàbò bò wá bí Ọlọ́run, ìdí sì ni pé tá a bá tiẹ̀ kú, ó máa jí wa dìde.

ÈMI ÀTI ÌYÀWÓ MI GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ

Ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó ní 1988

Lọ́dún 1988, mo pàdé Arábìnrin Dorcas. Aṣáájú-ọ̀nà tó nírẹ̀lẹ̀, tó sì tún nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an ni. A ṣègbéyàwó, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Dorcas ṣiṣẹ́ kára gan-an, ó sì máa ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó lè ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Èmi àtiẹ̀ máa ń fẹsẹ̀ rin nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) láti ìjọ kan sí òmíì, a sì máa ń gbé ẹrù wa dání. Àmọ́ tá a bá rí i pé àwọn ìjọ tá à ń lọ jìnnà, a máa ń wọkọ̀ tá a bá rí, ẹrọ̀fọ̀ àtàwọn kòtò ńlá sì pọ̀ lójú ọ̀nà gan-an.

Dorcas nígboyà gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì a máa ń wọ́dò kọjá omi táwọn ọ̀nì pọ̀ sí gan-an. Ìgbà kan wà tá a rìnrìn àjò ọlọ́jọ́ márùn-ún, igi tí wọ́n fi ṣe afárá odò tá a fẹ́ gbà kọjá sì ti bà jẹ́, torí náà a wọkọ̀ ojú omi. Bí Dorcas ṣe ní kóun bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀, ó ṣubú sínú odò náà, ibẹ̀ sì jìn. Kò sẹ́ni tó lè lúwẹ̀ẹ́ nínú àwa méjèèjì, àwọn ọ̀nì sì wà nínú odò náà. Àmọ́, a dúpẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin mélòó kan bẹ́ sínú odò, wọ́n sì gbé e jáde. Kódà, ó ṣe díẹ̀ kó tó di pé a ò fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lá àlá mọ́, síbẹ̀ à ń bá iṣẹ́ wa lọ.

Àwọn ọmọ wa Jahgift àti Eric jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà

Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1992, ó ya àwa méjèèjì lẹ́nu gan-an nígbà tá a gbọ́ pé Dorcas ti lóyún. À ń rò ó pé, ṣé ibi tí iṣẹ́ ìsìn àkànṣe tá à ń ṣe máa parí sí nìyí? Àmọ́, a tún rò ó pé “Jèhófà mà ti fún wa lẹ́bùn kan!” Torí náà, a pinnu pé Jahgift (ìyẹn Ẹ̀bùn Jáà) la máa sọ ọmọbìnrin wa. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tá a bí Jahgift, a tún bí Eric àbúrò ẹ̀ ọkùnrin. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ wa méjèèjì yìí jẹ́. Jahgift ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè tó wà ní Conakry, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ni Eric.

Torí pé Dorcas ń tọ́ àwọn ọmọ wa lọ́wọ́, kò lè ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mọ́, àmọ́ ó ṣì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní tèmi, Jèhófà jẹ́ kí n máa báṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nìṣó. Lẹ́yìn táwọn ọmọ wa dàgbà, Dorcas pa dà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ní báyìí, iṣẹ́ míṣọ́nnárì làwa méjèèjì ń ṣe ní Conakry.

JÈHÓFÀ DÁÀBÒ BÒ WÁ

Gbogbo ibi tí Jèhófà rán mi lọ ni mo lọ, kò sì sígbà témi àti ìyàwó mi ò rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa, a sì tún rí i pé ó ń dáàbò bò wá. Torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a ò ní ẹ̀dùn ọkàn táwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé nǹkan ìní máa ń ní. Èmi àti Dorcas ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa pé Jèhófà “Ọlọ́run ìgbàlà wa” ni Orísun ààbò tòótọ́. (1 Kíró. 16:35) Ó dá mi lójú pé Jèhófà máa fi ẹ̀mí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e “pa mọ́ sínú àpò ìwàláàyè lọ́dọ̀ rẹ̀.”—1 Sám. 25:29.