ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 49
Ṣé Jèhófà Máa Dáhùn Àdúrà Mi?
“Ẹ ó pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, màá sì fetí sí yín.”—JER. 29:12.
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1-2. Kí ló lè mú ká máa rò pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa?
BÍBÉLÌ sọ pé: “Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ nínú Jèhófà, yóò sì fún ọ ní àwọn ohun tí ọkàn rẹ fẹ́.” (Sm. 37:4) Ìlérí yẹn mà dáa gan-an o! Àmọ́, ṣé ó yẹ ká máa retí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà máa ṣe gbogbo ohun tá a béèrè lọ́wọ́ ẹ̀? Kí ló lè mú ká béèrè ìbéèrè yẹn? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí. Arábìnrin kan tí ò lọ́kọ ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n pe òun sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún bíi mélòó kan, wọn ò tíì pè é. Arákùnrin ọ̀dọ́ kan ń bẹ Jèhófà pé kó gba òun lọ́wọ́ àìsàn burúkú kan kóun lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ. Síbẹ̀, àìsàn náà ò lọ. Àwọn òbí kan tó jẹ́ Kristẹni ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí ọmọ wọn dúró sínú òtítọ́, àmọ́ ọmọ náà sọ pé òun ò sin Jèhófà mọ́.
2 Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti bẹ Jèhófà pé kó ṣe nǹkan kan fún ẹ, àmọ́ tí ò tíì ṣe é. Ìyẹn lè mú kó o máa ronú pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àwọn kan, àmọ́ kì í dáhùn àdúrà tìẹ. O sì lè máa rò pé o ti ṣe ohun tí ò dáa. Bó ṣe rí lára arábìnrin kan tó ń jẹ́ Janice b nìyẹn. Òun àti ọkọ ẹ̀ gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí wọ́n pè wọ́n sí Bẹ́tẹ́lì. Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé wọn ò ní pẹ́ pè wá sí Bẹ́tẹ́lì.” Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọn ò pè wọ́n. Janice sọ pé: “Ó dùn mí gan-an, mi ò sì mọ ohun tí màá ṣe. Mò ń rò ó pé ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ Jèhófà tí ò fi dáhùn àdúrà mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti dìídì gbàdúrà nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Kí ló wá dé tí ò tíì dáhùn àdúrà mi?”
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé Jèhófà kì í fetí sí àdúrà wa. Kódà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́ náà ronú bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 30:20; Sm. 22:2; Háb. 1:2) Torí náà, kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà ẹ? (Sm. 65:2) Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò àwọn ìbéère yìí: (1) Kí ló yẹ ká máa retí pé kí Jèhófà ṣe fún wa? (2) Kí ni Jèhófà ń retí pé káwa náà ṣe? (3) Tí Jèhófà ò bá ṣe ohun tá a béèrè, kí nìdí tó fi yẹ ká béèrè nǹkan míì?
KÍ LÓ YẸ KÁ MÁA RETÍ PÉ KÍ JÈHÓFÀ ṢE FÚN WA?
4. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún wa nínú Jeremáyà 29:12?
4 Jèhófà ṣèlérí pé òun máa tẹ́tí sáwọn àdúrà wa. (Ka Jeremáyà 29:12.) Ọlọ́run wa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn, torí náà ó máa ń gbọ́ àdúrà wọn. (Sm. 10:17; 37:28) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tá a bá béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ ló máa ṣe fún wa. Ó dinú ayé tuntun ká tó rí àwọn nǹkan míì tá a béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ gbà.
5. Kí ni Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dáhùn àdúrà wa? Ṣàlàyé.
5 Jèhófà máa ń wò ó bóyá ohun tá à ń béèrè bá ìfẹ́ ẹ̀ mu. (Àìsá. 55:8, 9) Ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn ọkùnrin àtobìnrin kún ayé, kó sì máa ṣàkóso wọn bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Àmọ́ Sátánì sọ pé táwọn èèyàn bá ń ṣàkóso ara wọn ló dáa jù. (Jẹ́n. 3:1-5) Kí Jèhófà lè fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa, ó gba àwọn èèyàn láyè láti máa ṣàkóso ara wọn. Torí náà, àkóso àwọn èèyàn ló fa ọ̀pọ̀ ìṣòro tá a ní lónìí. (Oníw. 8:9) A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìṣòro náà ni Jèhófà máa mú kúrò báyìí. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn kan máa rò pé àkóso èèyàn ló dáa jù àti pé ó lè yanjú gbogbo ìṣòro àwa èèyàn.
6. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ṣe ohun tó tọ́, tó sì máa fìfẹ́ hàn sí wa?
6 Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà ń gbà dáhùn àdúrà wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Hẹsikáyà ń ṣàìsàn tó le gan-an, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kára òun yá. Jèhófà sì wò ó sàn. (2 Ọba 20:1-6) Àmọ́ nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bẹ Jèhófà pé kó yọ “ẹ̀gún kan” tó wà nínú ara òun kúrò, ìyẹn àìsàn kan tó ń bá a fínra, Jèhófà ò mú un kúrò. (2 Kọ́r. 12:7-9) Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Jémíìsì àti àpọ́sítélì Pétérù. Àwọn méjèèjì ni Ọba Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa. Ìjọ wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà fún Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbàdúrà fún Jémíìsì náà. Àmọ́ wọ́n pa Jémíìsì, Jèhófà sì dá Pétérù sílẹ̀ lọ́nà ìyanu. (Ìṣe 12:1-11) A lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi gba Pétérù sílẹ̀ àmọ́ tí ò gba Jémíìsì sílẹ̀?’ Bíbélì ò sọ fún wa. c Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà “kì í ṣe ojúsàájú.” (Diu. 32:4) A sì mọ̀ pé àwọn méjèèjì ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́. (Ìfi. 21:14) Nígbà míì, ó lè jẹ́ ohun tá ò lérò ni Jèhófà máa fi dáhùn àdúrà wa. Àmọ́, a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó tọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé a kì í ráhùn nípa ọ̀nà tó gbà dáhùn àdúrà wa.—Jóòbù 33:13.
7. Kí ni ò yẹ ká máa ṣe, kí sì nìdí?
7 Kò yẹ ká máa fi bí nǹkan ṣe rí fún wa wé tàwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, a lè ní kí Jèhófà ṣe nǹkan kan fún wa, àmọ́ kó má ṣe nǹkan náà. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, a gbọ́ pé ẹlòmíì béèrè ohun kan náà lọ́wọ́ Jèhófà, ó sì jọ pé ó ṣe é fún un. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Anna nìyẹn. Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí àìsàn jẹjẹrẹ tó ń ṣe Matthew ọkọ ẹ̀ lọ. Àsìkò yẹn náà ni àrùn jẹjẹrẹ ń ṣe àwọn arábìnrin àgbàlagbà méjì kan. Anna gbàdúrà gan-an fún Matthew àtàwọn arábìnrin méjì náà. Ara àwọn arábìnrin méjèèjì náà yá, àmọ́ Matthew kú. Nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, Anna ń bi ara ẹ̀ pé ṣé torí pé Jèhófà ran àwọn arábìnrin yẹn lọ́wọ́ lara wọn fi yá? Tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tí ò fi dáhùn àdúrà òun kí ara ọkọ òun náà sì yá? Lóòótọ́, a ò mọ ohun tó jẹ́ kí ara àwọn arábìnrin méjèèjì náà yá. Ohun tá a mọ̀ ni pé Jèhófà mọ bó ṣe máa yanjú gbogbo ìṣòro tá a bá ní, ó sì máa jí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ti kú dìde.—Jóòbù 14:15.
8. (a) Kí ni Àìsáyà 43:2 sọ pé Jèhófà máa ń ṣe fún wa kó lè ràn wá lọ́wọ́? (b) Báwo ni àdúrà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro tó le gan-an? (Wo fídíò náà Àdúrà Ló Ràn Wá Lọ́wọ́.)
8 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́. Torí pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, kì í fẹ́ ká máa jẹ̀rora. (Àìsá. 63:9) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìṣòro wa tó dà bí odò tàbí iná ló máa ń mú kúrò. (Ka Àìsáyà 43:2.) Ṣùgbọ́n, ó ti ṣèlérí pé òun máa wà ‘pẹ̀lú wa,’ kò sì ní jẹ́ kí ìṣòro mú ká fi òun sílẹ̀. Jèhófà tún máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè fara dà á. (Lúùkù 11:13; Fílí. 4:13) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà á máa pèsè ohun tá a nílò, ká lè máa fara da ìṣòro wa ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. d
KÍ NI JÈHÓFÀ Ń RETÍ PÉ KÁWA NÁÀ ṢE?
9. Bí Jémíìsì 1:6, 7 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́?
9 Jèhófà fẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Héb. 11:6) Nígbà míì, ìṣòro wa lè dà bí òkè ńlá. Kódà, ó lè ṣe wá bíi pé Jèhófà ò ní ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa lágbára tá a lè fi “gun ògiri.” (Sm. 18:29) Torí náà, dípò ká máa ṣiyèméjì, ṣe ló yẹ ká máa gbàdúrà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé ó máa dáhùn àdúrà wa.—Ka Jémíìsì 1:6, 7.
10. Sọ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè ṣe ipa tiwa kí àdúrà wa lè gbà.
10 Jèhófà fẹ́ ká ṣe ipa tiwa kó lè dáhùn àdúrà wa. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n fún òun láyè níbi iṣẹ́ kóun lè lọ sí àpéjọ agbègbè. Báwo ni Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà yẹn? Ó lè fún arákùnrin náà nígboyà tó máa fi lọ bá ọ̀gá ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àmọ́ arákùnrin náà ṣì gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀. Kódà, ó lè gba pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra. Ó sì lè gba pé kó yí àkókò tó máa ṣiṣẹ́ pa dà, kí ẹlòmíì lè bá a ṣe é. Tó bá sì pọn dandan, ó lè ní kí wọ́n yọ owó ọjọ́ tóun ò ní wá síbi iṣẹ́ kóun lè lọ sí àpéjọ náà.
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà léraléra nípa ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè?
11 Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà léraléra nípa àwọn nǹkan tó ń kó wa lọ́kàn sókè. (1 Tẹs. 5:17) Ohun tí Jésù sọ jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà máa dáhùn gbogbo àdúrà wa. (Lúùkù 11:9) Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ! Máa gbàdúrà tọkàntọkàn, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lemọ́lemọ́. (Lúùkù 18:1-7) Tá a bá ń gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ kan lemọ́lemọ́, Jèhófà á mọ̀ pé nǹkan náà ṣe pàtàkì sí wa. Ìyẹn tún fi hàn pé a nígbàgbọ́ pé ó máa ràn wá lọ́wọ́.
TÍ JÈHÓFÀ Ò BÁ ṢE OHUN TÁ A BÉÈRÈ, KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ BÉÈRÈ NǸKAN MÍÌ?
12. (a) Kí ló yẹ ká máa bi ara wa nípa nǹkan tá à ń béèrè nínú àdúrà, kí sì nìdí? (b) Báwo la ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà? (Wo àpótí náà “ Ṣé Ohun Tí Mò Ń Béèrè Fi Hàn Pé Mo Bọ̀wọ̀ fún Jèhófà?”)
12 Tá ò bá rí àwọn nǹkan tá à ń béèrè nínú àdúrà wa gbà, ó yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan. Àkọ́kọ́ ni pé ‘Ṣé ohun tó tọ́ ni mò ń béèrè?’ Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ronú pé a mọ ohun tó dáa jù fún wa. Àmọ́ àwọn ohun tá à ń béèrè yẹn lè má ṣe wá láǹfààní. Tá a bá ń gbàdúrà nípa ìṣòro kan, ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà míì wà láti gbà yanjú ìṣòro náà tó dáa ju ohun tá a rò lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nǹkan míì tá a béèrè lè má bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (1 Jòh. 5:14) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn òbí tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn níbẹ̀rẹ̀. Wọ́n ti bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ọmọ àwọn dúró sínú òtítọ́. Àdúrà tó dáa sì nìyẹn. Síbẹ̀, Jèhófà ò ní fipá mú ẹnikẹ́ni nínú wa láti jọ́sìn òun. Ó fẹ́ kí gbogbo wa títí kan àwọn ọmọ wa pinnu pé òun làá máa sìn. (Diu. 10:12, 13; 30:19, 20) Torí náà, ó yẹ kí wọ́n bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn kọ́ ọmọ àwọn lọ́nà tá á fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá á sì jọ́sìn ẹ̀.—Òwe 22:6; Éfé. 6:4.
13. Ìgbà wo ni Hébérù 4:16 sọ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́? Ṣàlàyé.
13 Ìbéèrè kejì tó yẹ ká bi ara wa ni pé ‘Ṣé àsìkò ti tó lójú Jèhófà láti dáhùn àdúrà mi?’ Ó lè máa ṣe wá bíi pé kí Jèhófà dáhùn àdúrà wa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà mọ àsìkò tó dáa jù láti dáhùn àdúrà wa. (Ka Hébérù 4:16.) Tá ò bá tètè rí ìdáhùn àdúrà wa, a lè rò pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé kò tíì tó àsìkò lójú ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹ rántí arákùnrin ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú tó bẹ Jèhófà pé kó wo òun sàn? Ká sọ pé Jèhófà wò ó sàn lọ́nà ìyanu ni, Sátánì lè sọ pé torí pé Jèhófà wò ó sàn ló ṣe ń sin Jèhófà. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti mọ ìgbà tó máa mú gbogbo àìsàn kúrò pátápátá. (Àìsá. 33:24; Ìfi. 21:3, 4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a ò lè retí pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa wò wá sàn lọ́nà ìyanu. Torí náà, arákùnrin yẹn lè bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun, kó sì jẹ́ kọ́kàn òun balẹ̀ kóun lè máa fara da àìsàn náà, kóun sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Sm. 29:11.
14. Kí la kọ́ lára Janice?
14 Ṣé ẹ rántí Arábìnrin Janice tó gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí wọ́n pe òun sí Bẹ́tẹ́lì? Ẹ̀yìn ọdún márùn-ún ló tó rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà ẹ̀. Ó sọ pé: “Jèhófà lo àsìkò yẹn láti kọ́ mi kí n lè sunwọ̀n sí i. Ó yẹ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, kí n túbọ̀ máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kí n sì máa láyọ̀ níbikíbi tí mo bá ti ń sin Jèhófà.” Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí Janice àti ọkọ ẹ̀ máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Nígbà tí Janice ń rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ó ní: “Jèhófà dáhùn àdúrà mi bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun tí mò ń retí nìyẹn. Ó gbà mí lákòókò díẹ̀ kí n tó rí i pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi torí pé iṣẹ́ àtàtà ló gbé fún wa, inú mi sì dùn pé ó fìfẹ́ àti inúure hàn sí mi.”
Tó o bá rò pé Jèhófà ò tíì fún ẹ ní nǹkan tó ò ń béèrè, bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe nǹkan míì fún ẹ (Wo ìpínrọ̀ 15) f
15. Kí nìdí tí ò fi yẹ kó jẹ́ ohun kan péré làá máa béèrè tá a bá ń gbàdúrà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Ìbéèrè kẹta tó yẹ ká bi ara wa ni pé ‘Ṣé ohun kan péré ló yẹ kí n máa béèrè tí mo bá ń gbàdúrà?’ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kí àdúrà wa ṣe pàtó, nígbà míì ó máa dáa kí àdúrà wa má dá lórí ohun kan péré ká lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ fún wa. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tí ò lọ́kọ tó ń gbàdúrà pé kí ètò Ọlọ́run pe òun sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run kó lè lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù. Bó ṣe ń gbàdúrà pé kí wọ́n pe òun sílé ẹ̀kọ́ yẹn, ó tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun mọ àwọn iṣẹ́ ìsìn míì tóun lè ṣe. (Ìṣe 16:9, 10) Lẹ́yìn náà, á ṣe ohun tó bá àdúrà ẹ̀ mu, ìyẹn ni pé kó béèrè lọ́wọ́ alábòójútó àyíká wọn bóyá ìjọ kan wà nítòsí tó ń fẹ́ káwọn aṣáájú-ọ̀nà wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó sì lè béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. e
16. Kí ló dá wa lójú?
16 Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó tọ́, á sì fìfẹ́ hàn sí wa. (Sm. 4:3; Àìsá. 30:18) Nígbà míì, Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá a fẹ́. Àmọ́ Jèhófà ò ní ṣàìgbọ́ àdúrà wa. Ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì ní fi wá sílẹ̀. (Sm. 9:10) Torí náà, ẹ jẹ́ ká “gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà,” ká sì máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún un tá a bá ń gbàdúrà.—Sm. 62:8.
ORIN 43 Àdúrà Ìdúpẹ́
a Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó tọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé O Gbà Pé Ohun Tó Tọ́ Ni Jèhófà Máa Ń Ṣe?” nínú Ilé Ìṣọ́ February 2022, ìpínrọ̀ 3-6.
d Kó o lè mọ̀ sí i nípa bí Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá níṣòro, wo fídíò Àdúrà Ló Ràn Wá Lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org.
e Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè lọ sìn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí kò sí lórílẹ̀-èdè ẹ, wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 10, ìpínrọ̀ 6-9.
f ÀWÒRÁN: Àwọn arábìnrin méjì kan ń gbàdúrà kí wọ́n tó kọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó yá, wọ́n pe ọ̀kan, àmọ́ wọn ò pe arábìnrin kejì. Dípò kí arábìnrin tí wọn ò pè náà rẹ̀wẹ̀sì, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kóun rí àwọn nǹkan míì tóun lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó sì sọ fún wọn pé òun máa fẹ́ lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù.