Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 46

Ṣé Ò Ń Bójú Tó “Apata Ńlá Ti Ìgbàgbọ́” Rẹ?

Ṣé Ò Ń Bójú Tó “Apata Ńlá Ti Ìgbàgbọ́” Rẹ?

“Ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́.”​—ÉFÉ. 6:16.

ORIN 119 Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Bó ṣe wà nínú Éfésù 6:16, kí nìdí tá a fi nílò “apata ńlá ti ìgbàgbọ́”? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

ṢÉ O ní “apata ńlá ti ìgbàgbọ́”? (Ka Éfésù 6:16.) Ó dájú pé o ní. Bí apata ńlá ṣe máa ń dáàbò bo ọmọ ogun, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ ṣe máa dáàbò bò ẹ́ lọ́wọ́ ìṣekúṣe, ìwà ipá àtàwọn ìwàkiwà míì tó kúnnú ayé èṣù yìí.

2 Àmọ́ torí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé yìí, àwọn nǹkan táá dán ìgbàgbọ́ wa wò á máa yọjú ṣáá ni. (2 Tím. 3:1) Kí lá jẹ́ kó o mọ̀ bóyá apata ìgbàgbọ́ rẹ ṣì lágbára? Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.

MÁA FARA BALẸ̀ ṢÀYẸ̀WÒ APATA RẸ

Táwọn ọmọ ogun bá ti ogun dé, wọ́n máa ń tún apata wọn ṣe (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Kí làwọn ọmọ ogun máa ń ṣe sí apata wọn, kí sì nìdí?

3 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọmọ ogun sábà máa ń fi awọ bo apata wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń fi òróró pa á kí awọ náà má bàa bà jẹ́ kí apá tó jẹ́ irin lára ẹ̀ má sì dógùn-ún. Bí ọmọ ogun kan bá kíyè sí i pé apata òun ti ń bà jẹ́, á rí i pé òun tètè tún un ṣe kó lè múra sílẹ̀ de ogun. Báwo ni àpèjúwe yìí ṣe kan ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́?

4. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣàyẹ̀wò apata ìgbàgbọ́ rẹ, ọ̀nà wo lo sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

4 Bíi tàwọn ọmọ ogun ayé àtijọ́, ó ṣe pàtàkì kó o máa ṣàyẹ̀wò apata ìgbàgbọ́ rẹ déédéé, kó o sì máa ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ kó o lè wà ní sẹpẹ́. Ogun tẹ̀mí làwa Kristẹni ń jà, àwọn ẹ̀mí burúkú la sì ń bá jà. (Éfé. 6:10-12) Ìwọ fúnra ẹ lo máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ lágbára, kò sẹ́ni tó lè bá ẹ ṣe é. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o wà ní sẹpẹ́ nígbà tí àdánwò  ìgbàgbọ́ bá dé? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò kó o lè mọ̀ bóyá irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ kó o jẹ́ ni o jẹ́. (Héb. 4:12) Bíbélì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” (Òwe 3:5, 6) Pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, wá ronú nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ lẹ́nu àìpẹ́ yìí àtohun tó o ṣe nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o níṣòro ìṣúnná owó tó le gan-an? Ṣé o sì rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe nínú Hébérù 13:5 pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé”? Ǹjẹ́ ìlérí yẹn mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ò ń ṣe ohun tó yẹ láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ dúró digbí.

5. Tó o bá ṣàyẹ̀wò ìgbàgbọ́ rẹ, kí ló ṣeé ṣe kó o rí?

5 Tó o bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò bí ìgbàgbọ́ rẹ ṣe lágbára tó, ohun tó o máa rí lè yà ọ́ lẹ́nu. O lè wá rí i pé àwọn nǹkan kan ti ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó ò sì fura. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ìgbàgbọ́ rẹ máa jó rẹ̀yìn torí pé ò ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ tàbí torí ìrẹ̀wẹ̀sì. Ó sì lè jẹ́ torí irọ́ táwọn kan ń pa mọ́ àwa èèyàn Jèhófà. Tírú nǹkan yìí bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí lá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ pa dà lágbára, kó má sì jó rẹ̀yìn?

MÁ ṢÀNÍYÀN JÙ, MÁ JẸ́ KÍ WỌ́N FI IRỌ́ TÀN Ẹ́ JẸ, MÁ SÌ RẸ̀WẸ̀SÌ

6. Sọ àpẹẹrẹ àwọn àníyàn tó bójú mu.

6 Àwọn àníyàn kan bójú mu, wọ́n sì ṣàǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó bọ́gbọ́n mu ká ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa múnú Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ dùn. (1 Kọ́r. 7:32) Bákan náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo, a máa ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa pa dà ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà. (Sm. 38:18) Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa múnú ọkọ tàbí aya wa dùn, bá a ṣe máa bójú tó ìdílé wa àti bá a ṣe máa mára tu àwọn ará wa.​—1 Kọ́r. 7:33; 2 Kọ́r. 11:28.

7. Bó ṣe wà nínú Òwe 29:25, kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù èèyàn?

7 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àníyàn àṣejù lè mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ṣàníyàn ṣáá nípa bá a ṣe máa rí oúnjẹ tó tó àti aṣọ. (Mát. 6:31, 32) Ìyẹn lè mú ká máa sáré bá a ṣe máa kó ohun ìní rẹpẹtẹ jọ. Láìfura, a tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ owó. Tá a bá jẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, a ò ní fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà mọ́, àárín àwa pẹ̀lú rẹ̀ kò sì ní gún régé mọ́. (Máàkù 4:19; 1 Tím. 6:10) Ó sì lè jẹ́ ohun míì là ń ṣàníyàn nípa ẹ̀, ìyẹn bá a ṣe máa rí ojúure àwọn èèyàn. Ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí pé wọ́n á ṣenúnibíni sí wa lè mú ká ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Tá ò bá fẹ́ káwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí wa, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa nígbàgbọ́ àti ìgboyà tá a nílò ká lè borí àwọn ìṣòro yìí.​—Ka Òwe 29:25; Lúùkù 17:5.

(Wo ìpínrọ̀ 8) *

8. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá parọ́ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà?

8 Sátánì tí Bíbélì pè ní “baba irọ́” máa ń mú káwọn èèyàn ẹ̀ pa irọ́ mọ́ Jèhófà àtàwọn ará wa. (Jòh. 8:44) Bí àpẹẹrẹ, àwọn apẹ̀yìndà máa ń sọ ohun tí kò jóòótọ́ nípa ètò Jèhófà lórí ìkànnì, tẹlifíṣọ̀n, rédíò àti ìwé ìròyìn, nígbà míì sì rèé wọ́n máa ń yí ọ̀rọ̀ po. Àwọn nǹkan yìí wà lára “ọfà oníná” tí Sátánì máa ń lò. (Éfé. 6:16) Kí ló yẹ ká ṣe tẹ́nì kan bá pa irú irọ́ yìí lójú wa? Kò yẹ ká fetí sí i rárá! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì fọkàn tán àwọn ará wa. Kókó ibẹ̀ ni pé, a ò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà. Ká má ṣe tọ pinpin  torí pé a fẹ́ gbọ́ tẹnu wọn, ká má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun sún wa láti bá wọn jiyàn.

9. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?

9 Ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Òótọ́ kan ni pé kò sẹ́ni tí kò níṣòro, àwọn ìṣòro yìí sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Bó ti wù kó rí, kò wá yẹ ká máa ṣe bíi pé a ò níṣòro, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká fi wọ́n sílẹ̀ láì wá nǹkan ṣe sí i, kò tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, kò yẹ ká jẹ́ káwọn ìṣòro yẹn gbà wá lọ́kàn débi pé òun làá máa rò ṣáá. Tó bá jẹ́ pé ìṣòro wa ló gbà wá lọ́kàn, a lè má fọkàn sí àwọn ìlérí Jèhófà mọ́, ó sì lè mú ká sọ̀rètí nù. (Ìfi. 21:3, 4) Ńṣe ni ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń tánni lókun, kódà ó máa ń mú kéèyàn bọ́hùn. (Òwe 24:10) Àmọ́ kò yẹ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa.

10. Kí lo rí kọ́ nínú lẹ́tà tí arábìnrin kan kọ?

10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe tó fún un lókun lásìkò tí ọkọ rẹ̀ ń ṣàìsàn tó le gan-an. Arábìnrin yìí kọ lẹ́tà sí oríléeṣẹ́ wa, ó ní: “Àwọn ìgbà kan wà tí ìṣòro yìí tán wa lókun tó sì mú ká rẹ̀wẹ̀sì, síbẹ̀ a ò sọ̀rètí nù. A mọyì ìtọ́ni tá à ń rí gbà gan-an torí pé òun ló ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, tó sì ń gbé wa ró. Ó bọ́ sákòókò tá a nílò rẹ̀, ó ń fún wa lókun láti máa sin Jèhófà nìṣó, kò sì jẹ́ káwọn àtakò Sátánì bò wá mọ́lẹ̀.” Ó dájú pé ohun tí arábìnrin yìí sọ jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì. Torí náà, nígbàkigbà tó o bá níṣòro, gbà pé àǹfààní ló ṣí sílẹ̀ yẹn láti kọjú ìjà sí Sátánì. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Orísun ìtùnú, á sì tù ẹ́ nínú. Bákan náà, rí i pé o mọyì oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fún wa.

Ṣé ò ń bójú tó “apata ńlá ti ìgbàgbọ́” rẹ? (Wo ìpínrọ̀ 11) *

11. Tó o bá fẹ́ mọ bí ìgbàgbọ́ rẹ ṣe lágbára tó, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ?

11 Ǹjẹ́ o kíyè sí àwọn ibi tó nílò àtúnṣe lára apata ìgbàgbọ́ rẹ? Jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Ǹjẹ́ àwọn ìgbà kan wà lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí o kò jẹ́ kí àníyàn bò ẹ́ mọ́lẹ̀? Ṣé ìgbà kan wà tó ṣe ẹ́ bíi pé kó o tẹ́tí sí irọ́ táwọn apẹ̀yìndà ń pa tàbí pé kó o bá wọn jiyàn, àmọ́ tó ò ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé a rí ìgbà tó o fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì àmọ́ tó o borí ẹ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ dúró sán-ún nìyẹn. Bó ti  wù kó rí, kò yẹ ká dẹra nù torí pé Sátánì ní àwọn nǹkan míì tó ń lò láti dán wa wò. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára wọn.

MÁ ṢE KÓ OHUN ÌNÍ TARA JỌ

12. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa kó ohun ìní tara jọ ló gbà wá lọ́kàn?

12 Ìfẹ́ fún ohun ìní tara lè mú ká má ṣe tó bó ṣe yẹ nínú ìjọsìn Jèhófà, ó sì lè jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọmọ ogun tó bá fẹ́ múnú ẹni tó gbà á sí iṣẹ́ ológun dùn, kò ní tara bọ òwò ṣíṣe.” (2 Tím. 2:4) Kódà, wọn ò fàyè gba àwọn ọmọ ogun Róòmù rárá láti ṣe òwò èyíkéyìí. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí ọmọ ogun kan ò bá tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí?

13. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ọmọ ogun kan máa ṣòwò?

13 Fojú inú wo ọ̀rọ̀ yìí ná. Ká sọ pé àwọn ọmọ ogun kan ń ṣe ìdánrawò láàárọ̀ ọjọ́ kan, àmọ́ ọ̀kan lára wọn ò sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn. Ibo ló wà? Ó wà nígboro níbi tó ti ń ta oúnjẹ. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ogun tó kù ń tún àwọn ìhámọ́ra wọn ṣe, wọ́n sì ń pọ́n idà wọn. Àmọ́ ọ̀rẹ́ wa tó ń tajà ń ṣe kùrùkẹrẹ ọjà tó máa tà lọ́jọ́ kejì. Nígbà tí ilẹ̀ máa fi mọ́, àwọn ọ̀tá ti gbógun dé láìròtẹ́lẹ̀. Èwo nínú àwọn ọmọ ogun yẹn lẹ rò pé ó máa ṣe ohun tó yẹ, tó sì máa ṣe nǹkan tó dùn mọ́ ọ̀gá wọn nínú? Ká sọ pé ìwọ náà wà níbẹ̀, ọmọ ogun wo ni wàá fẹ́ kó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ? Ṣé èyí tó ti múra ogun sílẹ̀ ni àbí èyí tó ń múra ọjà sílẹ̀?

14. Kí làwa ọmọ ogun Kristi kà sí pàtàkì?

14 Bíi tàwọn ọmọ ogun tó ti múra sílẹ̀ yẹn, ó yẹ káwa náà wà ní ìmúrasílẹ̀, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun míì gbà wá lọ́kàn ju iṣẹ́ tí Jèhófà àti Jésù gbé fún wa lọ. Bá a ṣe máa rí ojú rere wọn ṣe pàtàkì ju ohunkóhun míì tá a lè rí nínú ayé Sátánì yìí. Ó ṣe pàtàkì ká máa ya àkókò sọ́tọ̀ ká sì rí i dájú pé a wà ní sẹpẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Bákan náà, a tún gbọ́dọ̀ máa tọ́jú apata ìgbàgbọ́ wa àtàwọn ìhámọ́ra ogun míì tí Jèhófà fún wa.

15. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún wa, kí sì nìdí?

15 Kò yẹ ká dẹra nù rárá! Kí nìdí?  Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀” máa “ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 6:9, 10) Ọ̀rọ̀ náà “ṣìnà kúrò” fi hàn pé a lè ní ìpínyà ọkàn torí pé à ń wá bá a ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, a máa dẹni tó ní “ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára.” Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan yìí wà lára ohun tí Sátánì ń lò láti gbéjà kò wá, torí náà ká kíyè sára kí wọ́n má bàa jọba lọ́kàn wa.

16. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká ronú lé lẹ́yìn tá a ka ìtàn tó wà nínú Máàkù 10:17-22?

16 Ẹ jẹ́ ká sọ pé a lówó láti ra ohunkóhun tá a bá fẹ́. Ṣó burú tá a bá ra àwọn nǹkan tá a fẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ nílò wọn? Ó lè má rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: Tá a bá tiẹ̀ lówó láti ra nǹkan kan, tá a bá rà á tán, ṣé a máa ráyè lò ó? Tó bá nílò àtúnṣe ńkọ́? Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ó ṣeé ṣe ká bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tara? Ṣé ìfẹ́ tá a ní fáwọn ohun ìní tara ò ní jẹ́ ká hùwà bíi ti ọ̀dọ́kùnrin tí kò gbà láti tẹ̀ lé Jésù torí àwọn nǹkan tó ní? (Ka Máàkù 10:17-22.) Ẹ wo bó ṣe máa bọ́gbọ́n mu tó tá a bá jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ká lè fi àkókò àti okun wa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run!

 MÁ ṢE JẸ́ KÍ APATA ÌGBÀGBỌ́ RẸ BỌ́ MỌ́ Ẹ LỌ́WỌ́

17. Kí ni kò yẹ ká gbàgbé láé?

17 Ó yẹ ká máa rántí nígbà gbogbo pé ojú ogun la wà, kò sì yẹ ká dẹra nù tàbí túra sílẹ̀ nígbà kankan. (Ìfi. 12:17) Kò sẹ́ni tó máa bá wa gbé apata ìgbàgbọ́ wa. Fúnra wa la máa di ìgbàgbọ́ wa mú, kò sì yẹ ká jẹ́ kó bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́.

18. Kí nìdí táwọn ọmọ ogun ayé àtijọ́ fi máa ń di apata wọn mú dáadáa?

18 Láyé àtijọ́, ṣe ni wọ́n máa ń gbé ọmọ ogun tó fakọ yọ lójú ogun gẹ̀gẹ̀, wọ́n sì máa ń yẹ́ ẹ sí. Àmọ́ ìtìjú ńlá ló máa jẹ́ fún un tó bá sọ apata rẹ̀ nù sójú ogun. Kódà, òpìtàn ará Róòmù kan tó ń jẹ́ Tacitus sọ pé: “Kò sí ohun tó tini lójú tó pé kí ọmọ ogun kan sọ apata rẹ̀ nù sójú ogun.” Ìdí nìyẹn táwọn ọmọ ogun fi máa ń rí i dájú pé àwọn di apata àwọn mú dáadáa.

Arábìnrin kan di apata ńlá ti ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú dáadáa ní ti pé ó ń ka Bíbélì, ó sì ń gbàdúrà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń lọ sípàdé déédéé, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 19)

19. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí apata ìgbàgbọ́ wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́?

19 Tá ò bá fẹ́ kí apata ìgbàgbọ́ wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ máa lọ sípàdé déédéé, ká sì máa sọ̀rọ̀ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ fáwọn míì. (Héb. 10:23-25) Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi àwọn ìtọ́ni rẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa. (2 Tím. 3:16, 17) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kò sí ohun ìjà Sátánì tó máa lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Àìsá. 54:17) “Apata ńlá ti ìgbàgbọ́” wa máa dáàbò bò wá. Àwa àtàwọn ará wa máa dúró gbọin, a ò sì ní bẹ̀rù. Yàtọ̀ sí pé a máa borí ogun tẹ̀mí tá à ń jà lójoojúmọ́, inú wa máa dùn, ohun iyì ló sì máa jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jésù la wà nígbà tó bá ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀.​—Ìfi. 17:14; 20:10.

ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn ọmọ ogun mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn gbé apata dání torí ó máa dáàbò bò wọ́n. Bí apata yìí ni ìgbàgbọ́ wa náà rí. Bó ti ṣe pàtàkì pé kí ọmọ ogun kan bójú tó apata rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì ká rí i pé ìgbàgbọ́ wa dúró sán-ún. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ kí “apata ńlá ti ìgbàgbọ́” wa dúró sán-ún.

^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Nígbà tí ìdílé kan ń wo tẹlifíṣọ̀n, àwọn apẹ̀yìndà gbé ìròyìn kan tí kì í ṣòótọ́ jáde nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ṣe ni wọ́n pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìjọsìn ìdílé, olórí ìdílé yẹn ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan kó lè fún ìgbàgbọ́ ìdílé rẹ̀ lókun.