ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ November 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti December 30, 2019 sí February 2, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Àwọn Ará Kí Òpin Tó Dé

Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ lára Jeremáyà torí pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tó ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù.

Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́

Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. Àmọ́ tá a bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ láyé wa, àwọn nǹkan mẹ́rin kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe.

Ṣé Ò Ń Bójú Tó “Apata Ńlá Ti Ìgbàgbọ́” Rẹ?

Bí apata tó máa ń dáàbò bo ọmọ ogun ni ìgbàgbọ́ wa rí. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí apata ìgbàgbọ́ wa dúró sán-⁠ún?

Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù

Àwọn òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ló wà nínú ìwé Léfítíkù. Òótọ́ ni pé àwa Kristẹni kò sí lábẹ́ àwọn òfin yẹn, síbẹ̀ wọ́n lè ṣe wá láǹfààní.

“Ẹ Parí Ohun Tí Ẹ Ti Bẹ̀rẹ̀”

Tá a bá tiẹ̀ ṣe ìpinnu tó dáa, nígbà mí ì ó máa ń ṣòro fún wa láti ṣe ohun tá a pinnu. Wo àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ táá jẹ́ kó o lè parí ohun tó o bẹ̀rẹ̀.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Iṣẹ́ wo làwọn ìríjú máa ń ṣe láyé àtijọ́?