Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Wọ́n Fìtara Wàásù Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọkàn Tó Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”

“Wọ́n Fìtara Wàásù Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọkàn Tó Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ”

OHUN kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Friday kan lóṣù September 1922. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, ooru ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú nínú gbọ̀ngàn ńlá kan tí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] èèyàn pé jọ sí. Alága àpéjọ náà kéde pé mánigbàgbé ni àpéjọ yẹn máa jẹ́, àmọ́ bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jáde, kò sẹ́ni tó máa dí i lọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò ní sí àyè fún un láti pa dà wọlé mọ́.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ ọ̀pọ̀ orin níbẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà, Arákùnrin Joseph F. Rutherford bọ́ sórí pèpéle. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pé jọ ni ara wọn ti wà lọ́nà láti gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. Àmọ́, ṣe làwọn kan ń rìn lọ rìn bọ̀ nínú ooru yẹn. Olùbánisọ̀rọ̀ rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n wábi jókòó, kí wọ́n sì tẹ́tí sílẹ̀. Bí àsọyé náà ṣe ń lọ, kò dájú pé ẹnikẹ́ni kíyè sí aṣọ tí wọ́n ká jọ sí òkè téńté.

Àkòrí àsọyé Arákùnrin Rutherford ni “Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Nǹkan bíi wákàtí kan àtààbọ̀ ló fi sọ̀rọ̀, tí ohùn rẹ̀ sì rinlẹ̀ nínú gbọ̀ngàn ńlá náà bó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn wòlíì ìgbàanì tí wọ́n fìtara kéde Ìjọba Ọlọ́run láìbẹ̀rù. Nígbà tó máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó béèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbà gbọ́ pé Ọba ògo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?” Gbogbo àwọn tó pé jọ náà dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni!”

Arákùnrin Rutherford wá fìtara sọ pé, “Nígbà náà ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ẹ̀yin ọmọ Ọlọ́run tí í ṣe ẹni gíga jùlọ! Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere.”

Ọ̀rọ̀ yẹn ló ń sọ lọ́wọ́, bó ṣe di pé aṣọ tí wọ́n ká jọ sókè téńté bẹ̀rẹ̀ sí í tú nìyẹn, táwọn èèyàn sì rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára rẹ̀, pé: “Ẹ Fọn Rere Ọba Náà àti Ìjọba Rẹ̀.”

Ray Bopp sọ pé: “Ńṣe ni àtẹ́wọ́ ń ró lọ́jọ́ náà.” Anna Gardner sọ bí “àtẹ́wọ́ táwọn ará pa ṣe mú káwọn igi ìrólé ibẹ̀ mì.” Fred Twarosh sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó ní: “Ṣe ni gbogbo wa dìde dúró lẹ́ẹ̀kan náà.” Evangelos Scouffas náà sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé agbára ńlá kan ṣàdédé gbé gbogbo wa dìde lórí ìjókòó wa, a dìde dúró, omijé sì lé ròrò sójú wa.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ tó wà ní àpéjọ yẹn ló ti ń polongo ìhìn rere Ìjọba náà ṣáájú ìgbà yẹn, àmọ́ ní báyìí, ṣe ni wọ́n wá rí àkọ̀tun ìdí láti máa wàásù. Ethel Bennecoff sọ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í “fìtara wàásù, ìfẹ́ ọkàn tí wọ́n sì fi ń ṣe iṣẹ́ náà wá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni Arábìnrin Odessa Tuck nígbà yẹn, lẹ́yìn tó kúrò ní àpéjọ yẹn, ó pinnu láti jẹ́ ìpè náà pé, ‘Ta ni yóò lọ?’ Ó sọ pé: “Mi ò mọ bí nǹkan ṣe máa rí. Àmọ́ ohun tí mo mọ̀ ni pé, mo fẹ́ dà bí Aísáyà tó sọ pé, ‘Èmi nìyí! Rán mi.’ ” (Aísá. 6:⁠8) Ralph Leffler sọ pé: “Ọjọ́ aláyọ̀ yìí gan-an la bẹ̀rẹ̀ sí í fọn rere Ìjọba náà, ìkéde yìí sì ti wá kárí ayé báyìí.”

 Abájọ tí àpéjọ tá a ṣe lọ́dún 1922 ní Cedar Point, Ohio, fi jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà! George Gangas sọ pé, “Àpéjọ yẹn ni mo ti pinnu pé mi ò ní pa àpéjọ èyíkéyìí jẹ láé.” Bó sì ṣe rí náà nìyẹn, kò jọ pé ó pa àpéjọ kankan jẹ látìgbà yẹn. Arábìnrin Julia Wilcox sọ pé: “Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe máa ń dùn tó nígbàkigbà tí wọ́n bá mẹ́nu kan àpéjọ Cedar Point tọdún 1922 nínú ìwé wa. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń sọ pé, ‘O ṣé o Jèhófà tó o jẹ́ kí n wà níbẹ̀.’ ”

Bíi tàwọn ará yìí, ọ̀pọ̀ wa náà máa ń rántí àpéjọ kan tá a gbádùn gan-an, tó mú ká túbọ̀ máa fìtara wàásù, ká sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa àti Jésù Ọba wa. Nígbàkigbà tá a bá rántí irú àpéjọ bẹ́ẹ̀, àwa náà máa ń sọ pé, “O ṣé o Jèhófà tó o jẹ́ kí n wà níbẹ̀.”