ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Gbọ́ Àdúrà Mi

Jèhófà Gbọ́ Àdúrà Mi

LÁLẸ́ ọjọ́ kan, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, mo gbójú sókè wo àwọn ìràwọ̀ tó ń tàn yanran lójú ọ̀run. Ohun tí mo rí wọ̀ mí lọ́kàn débi pé mo kúnlẹ̀, mo sì gbàdúrà. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ni, àmọ́ mo sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún un. Àdúrà tí mo gbà lálẹ́ ọjọ́ yẹn ló jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sm. 65:2) Ní báyìí, ẹ jẹ́ kí n sọ ìdí tí mo fi gbàdúrà sí Ọlọ́run tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀.

ÌBẸ̀WÒ KAN TÓ YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ WA PA DÀ

December 22, 1929 ni wọ́n bí mi nílùú Noville, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn oko mẹ́sàn-án tó wà nítòsí agbègbè Bastogne, lórílẹ̀-èdè Belgium. Inú mi máa ń dùn tí mo bá rántí bí mo ṣe máa ń ṣeré lóko pẹ̀lú àwọn òbí mi ní kékeré. Èmi àti Raymond àbúrò mi la jọ máa ń fún wàrà àwọn màlúù wa lójoojúmọ́, àá sì gbé e lọ fáwọn òbí wa. Ní abúlé wa, gbogbo wa la jọ máa ń ran ara wa lọ́wọ́ gan-an.

Èmi àtàwọn ìdílé mi ń ṣiṣẹ́ nínú oko wa

Emile àti Alice lorúkọ àwọn òbí mi, Kátólíìkì paraku sì ni wọ́n. Gbogbo Sunday la máa ń lọ sí Máàsì. Àmọ́ nígbà tó dọdún 1939, àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan wá sí abúlé wa láti orílẹ̀-èdè England, wọ́n sì bi bàbá mi pé ṣé wọ́n á fẹ́ máa san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Consolation tá à ń pè ní Jí! báyìí. Kò pẹ́ rárá tí bàbá mi fi mọ̀ pé àwọn ti rí òtítọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Nígbà tí wọn ò lọ sí Máàsì mọ́, àwọn aládùúgbò wa tí wọ́n máa ń bá wa ṣeré tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wá gan-an. Wọ́n fúngun mọ́ bàbá mi pé kí wọ́n má kúrò nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n bára wọn jiyàn gan-an.

Ó máa ń dùn mí gan-an tí mo bá rí ìwà burúkú tí wọ́n ń hù sí bàbá mi. Ohun tó jẹ́ kí n gbàdúrà nìyẹn bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, mo bẹ Ọlọ́run gan-an pé kó ràn mí lọ́wọ́. Nígbà táwọn aládùúgbò wa ò ta ko bàbá mi mọ́, inú mi dùn gan-an. Ó wá dá mi lójú pé Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.”

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ WA NÍGBÀ OGUN ÀGBÁYÉ KEJÌ

Ní May 10, 1940, ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì gbógun wọ orílẹ̀-èdè Belgium, ìyẹn sì mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn sá kúrò nílùú. Torí náà, ìdílé wa sá lọ sí gúúsù orílẹ̀-èdè Faransé. Nígbà míì, a máa ń wà níbi táwọn ọmọ ogun Jámánì àtàwọn ọmọ ogun Faransé ti ń fìjà pẹẹ́ta.

Nígbà tá a pa dà sóko wa, a rí i pé wọ́n ti jí ọ̀pọ̀ ẹrù wa kó lọ. Bobbie ajá wa nìkan ló wá pàdé wa. Irú àwọn nǹkan báyìí ló mú kí n máa bi ara mi pé, ‘Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń jagun, tí ìyà sì pọ̀ tó báyìí?’

Èmi rèé nígbà tí mi ò tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún, ìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà

Lásìkò yẹn, Arákùnrin Emile Schrantz a tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti alàgbà máa ń bẹ̀ wá wò, ìbẹ̀wò wọn sì máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Wọ́n fi Bíbélì ṣàlàyé ìdí táwa èèyàn fi ń jìyà, wọ́n sì dáhùn àwọn ìbéèrè míì tí mo ní. Ìyẹn jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì dá mi lójú pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni.

Kódà kí ogun yẹn tó parí làwọn ará ti máa ń bẹ ìdílé wa wò déédéé. Ní August 1943, Arákùnrin José-Nicolas Minet wá sọ àsọyé lóko wa. Ó wá bi wá pé, “Ta ló wù lára yín kó ṣèrìbọmi?” Èmi àti bàbá mi nawọ́, a sì ṣèrìbọmi nínú odò kékeré kan nítòsí oko wa.

Ní December 1944, orílẹ̀-èdè Jámánì gbógun ja ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù, ogun yẹn ni wọ́n jà kẹ́yìn, wọ́n sì ń pè é ní Battle of the Bulge. Ibi tá à ń gbé ò jìnnà síbi tí wọ́n ti ń jagun yẹn, torí náà inú àjà ilẹ̀ ilé wa la wà fún odindi oṣù kan. Lọ́jọ́ kan tí mo ní kí n jáde lọ fún àwọn ẹran wa lóúnjẹ, wọ́n ju bọ́ǹbù sóko wa, bọ́ǹbù náà sì ṣí òrùlé ilé ìkẹ́rùsí wa. Ọmọ ogun Amẹ́ríkà kan tó wà nítòsí mi níbi tá à ń kó ẹran sí pariwo pé, “Dojú bolẹ̀!” Bí mo ṣe sáré lọ bá a nìyẹn, mo sì dọ̀bálẹ̀ síbi tó wà, ó wá fi akoto ẹ̀ dé mi lórí kí nǹkan kan má bàa ṣe mí.

ÀJỌṢE MI PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ Ń LÁGBÁRA SÍ I

Èmi àti ìyàwó mi rèé lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa

Lẹ́yìn ogun yẹn, a ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa jìnnà sáwọn ará ìjọ tó wà nílùú Liège. Láti ilé wa, ìlú yẹn wà ní nǹkan bí àádọ́rùn-ún (90) kìlómítà lápá àríwá. Nígbà tó yá, a dá àwùjọ kékeré kan ságbègbè Bastogne tá à ń gbé. Lẹ́yìn ìyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbowó orí, mo sì láǹfààní láti lọ kàwé kí n lè di lọ́yà. Nígbà tó yá, mo ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì ìjọba. Ní 1951, a ṣètò àpéjọ àyíká kan lágbègbè Bastogne. Àwa bí ọgọ́rùn-ún kan (100) la wá síbẹ̀, títí kan arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà onítara kan tó ń jẹ́ Elly Reuter. Kẹ̀kẹ́ ló gùn wá sí àpéjọ yẹn, àádọ́ta kìlómítà (50) ló sì fi rìnrìn àjò náà. Kò pẹ́ tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ ara wa, tá a sì pinnu pé a máa ṣègbéyàwó. Lẹ́yìn náà, wọ́n pe Elly pé kó wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó wá kọ lẹ́tà sí oríléeṣẹ́, ó sì ṣàlàyé ìdí tóun ò fi ní lè wá. Arákùnrin Nathan Knorr tó ń ṣàbójútó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn wá fèsì, ó sì sọ pé tó bá dọjọ́ kan, ó ṣeé ṣe kóun àti ọkọ ẹ̀ jọ wá sílé ẹ̀kọ́ náà. Nígbà tó di February 1953, a ṣègbéyàwó.

Elly àti Serge ọmọkùnrin wa

Lọ́dún yẹn kan náà, èmi àti Elly lọ sí àpéjọ New World Society Assembly tí wọ́n ṣe ní Yankee Stadium, nílùú New York. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé arákùnrin kan tó fi iṣẹ́ tó dáa lọ̀ mí, ó sì ní ká wá máa gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn témi àti Elly gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ náà, a pinnu pé a ò ní gbaṣẹ́ yẹn, dípò bẹ́ẹ̀, ṣe la máa pa dà sórílẹ̀-èdè Belgium, ká lè lọ ran àwùjọ kékeré tó wà ní Bastogne lọ́wọ́ torí pé nǹkan bí akéde mẹ́wàá péré ló wà níbẹ̀. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Jèhófà fi ọmọkùnrin kan dá wa lọ́lá, a sì sọ ọ́ ní Serge. Àmọ́ ó dùn wá gan-an pé lẹ́yìn oṣù méje, Serge ṣàìsàn, ó sì kú. A sọ bó ṣe dùn wá tó fún Jèhófà, lẹ́yìn ìyẹn ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé àwọn òkú máa jíǹde.

IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ KÍKÚN

Ní October 1961, mo ríṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ kan tó jẹ́ kí n ráyè máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ ọjọ́ yẹn kan náà ni arákùnrin tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Belgium pè mí lórí fóònù. Ó bi mí bóyá màá fẹ́ ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ àyíká (tá à ń pè ní alábòójútó àyíká báyìí). Mo wá bi í pé: “Ṣé a lè kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà díẹ̀ ká tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà?” Ó wá sọ pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tá a ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún oṣù mẹ́jọ, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká ní September 1962.

Lẹ́yìn ọdún méjì tá a ti ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, ètò Ọlọ́run ní ká wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brussels, October 1964 la sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìbùkún la rí lẹ́nu iṣẹ́ tuntun tá a bẹ̀rẹ̀ yìí. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Arákùnrin Knorr ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì wa ní 1965, ètò Ọlọ́run sọ mí di ìránṣẹ́ ẹ̀ka, ó sì yà mí lẹ́nu gan-an. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run pe èmi àti Elly sí kíláàsì kọkànlélógójì (41) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Knorr sọ lọ́dún mẹ́tàlá (13) sẹ́yìn ti wá ṣẹ báyìí! Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, a pa dà sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Belgium.

MO GBÈJÀ Ẹ̀TỌ́ ÀWA ÈÈYÀN JÈHÓFÀ

Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni mo ti ń lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ òfin tí mo ní láti gbèjà àwa èèyàn Ọlọ́run ká lè lómìnira láti jọ́sìn nílẹ̀ Yúróòpù àti láwọn ibòmíì, àǹfààní ńlá nìyẹn sì jẹ́. (Fílí. 1:7) Iṣẹ́ yìí ti jẹ́ kí n pàdé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wá láti orílẹ̀-èdè tó lé ní márùndínlọ́gọ́ta (55) tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Tí mo bá fẹ́ sọ ẹni tí mo jẹ́ fún wọn, dípò kí n sọ pé amòfin ni mí, mo máa ń sọ fún wọn pé “òjíṣẹ́ Ọlọ́run” ni mí. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ mi sọ́nà torí mo mọ̀ pé “ọkàn ọba [tàbí adájọ́] dà bí odò ní ọwọ́ Jèhófà. Ibi tí Ó bá fẹ́ ló ń darí rẹ̀ sí.”—Òwe 21:1.

Mi ò lè gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan tí mo láǹfààní láti bá ọ̀kan lára àwọn tó wà ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Yúróòpù sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti sọ pé mo fẹ́ rí i, àmọ́ ó gbà láti rí mi lọ́jọ́ tá à ń wí yìí. Ó sọ pé, “Ìṣẹ́jú márùn-ún péré ni mo fún ẹ, kò sì ní jùyẹn lọ.” Ni mo bá tẹrí ba, mo sì gbàdúrà. Ẹ̀rù ba ọkùnrin náà, ló bá bi mí pé kí ni mò ń ṣe? Mo gbórí sókè, mo sì sọ pé: “Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ni, pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni yín.” Ó wá bi mí pé, “Kí lo ní lọ́kàn?” Mo fi ohun tó wà nínú Róòmù 13:4 hàn án. Ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì ló ń lọ, torí náà ẹsẹ Bíbélì yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú gbáko la fi jọ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ náà sì lójú. Kódà, ó sọ pé òun mọyì iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gan-an.

Ọ̀pọ̀ ọdún làwa èèyàn Jèhófà ti ń gbé onírúurú ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́ nílẹ̀ Yúróòpù. Lára ẹ̀ ni báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kí í ṣe dá sọ́rọ̀ ogun àti òṣèlú, ọ̀dọ̀ ẹni táwọn ọmọ máa gbé táwọn òbí ò bá gbé pa pọ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ owó orí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé mo wà lára àwọn tó ń fi òfin gbèjà ẹ̀tọ́ wa, inú mi sì dùn gan-an pé mo rí bí Jèhófà ṣe ń dá sọ́rọ̀ náà tó sì jẹ́ ká ṣàṣeyọrí. Ó ti lé ní ogóje (140) ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ti dá àwa èèyàn Jèhófà láre!

ÀWỌN ARÁ LÓMÌNIRA LÁTI JỌ́SÌN JÈHÓFÀ NÍ CUBA

Láwọn ọdún 1990, mo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Arákùnrin Philip Brumley láti oríléeṣẹ́ àti Arákùnrin Valter Farneti láti orílẹ̀-èdè Ítálì. A sapá gan-an láti ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè lómìnira láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó lórílẹ̀-èdè Cuba tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Mo kọ lẹ́tà sí ọ́fíìsì aṣojú ìjọba Cuba tó wà ní orílẹ̀-èdè Belgium, wọ́n sì rán ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba sí mi kó lè bójú tó ọ̀rọ̀ náà. A kọ́kọ́ pàdé láwọn ìgbà mélòó kan ká lè sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa, síbẹ̀ a ò rí ọ̀rọ̀ náà yanjú pátápátá.

Èmi àti Philip Brumley pẹ̀lú Valter Farneti nígbà tá a ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Cuba láwọn ọdún 1990

Lẹ́yìn tá a gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, a gbàṣẹ lọ́wọ́ ìjọba pé a fẹ́ kó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) Bíbélì wá sí orílẹ̀-èdè Cuba, wọ́n sì sọ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀. A rí àwọn Bíbélì náà gbà, a sì pín in fáwọn ará, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà gbọ́ àdúrà wa. Lẹ́yìn náà, a tún gbàṣẹ pé a fẹ́ kó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (27,500) Bíbélì wá sí orílẹ̀-èdè Cuba, wọ́n sì tún fọwọ́ síyẹn náà. Ohun tá a ṣe yìí jẹ́ káwọn ará wa ọ̀wọ́n lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lórílẹ̀-èdè Cuba ní Bíbélì tiwọn, ìyẹn sì múnú mi dùn gan-an.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti lọ sí órílẹ̀-èdè Cuba láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará, kí wọ́n lè túbọ̀ lómìnira láti jọ́sìn Jèhófà. Láwọn àsìkò yẹn, èmi àti ọ̀pọ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba di ọ̀rẹ́.

MO RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ NÍ RÙWÁŃDÀ

Lọ́dún 1994, àwọn tó ju mílíọ̀nù kan (1,000,000) lọ ni wọ́n pa nígbà tí wọ́n fẹ́ pa ẹ̀yà Tutsi run lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ará wa kan kú nígbà yẹn. Kò pẹ́ rárá tí ètò Ọlọ́run fi sọ pé káwọn arákùnrin kan ṣètò bí wọ́n ṣe máa fi oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì ṣèrànwọ́ fáwọn ará lórílẹ̀-èdè náà.

Ètò Ọlọ́run rán àwa kan lọ síbẹ̀ láti ṣèrànwọ́, àmọ́ nígbà tá a dé sí Kigali, ìyẹn olú ìlú orílẹ̀-èdè Rùwáńdà, a rí i pé wọ́n ti fi ìbọn ba ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè jẹ́, títí kan ibi tá à ń kó àwọn ìwé wa sí. Ó bà wá nínú jẹ́ gan-an nígbà tá a gbọ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni wọ́n fi àdá ṣá pa. Àmọ́ inú wa dùn gan-an nígbà tá a gbọ́ báwọn ará ṣe fìfẹ́ hàn síra wọn lásìkò yẹn. Bí àpẹẹrẹ, a pàdé arákùnrin kan tó jẹ́ ẹ̀yà Tutsi tí ìdílé kan tó jẹ́ ẹ̀yà Hutu fi pa mọ́ sínú ihò abẹ́ ilẹ̀ fún ọjọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28). Níbi ìpàdé kan tá a ṣe pẹ̀lú àwọn ará ní Kigali, a sọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) lọ.

Apá òsì: Ọ̀kan lára àwọn ìwé tí ìbọn bà ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè

Apá ọ̀tún: Mò ń ṣiṣẹ́ níbi tá a ti ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù

Nígbà tó yá, a kọjá sí Zaire (ìyẹn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pè ní Democratic Republic of the Congo báyìí) ká lè lọ wá ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rùwáńdà tí wọ́n sá lọ sí àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò nílùú tó wà nítòsí ìlú Goma. Àmọ́ a ò rí wọn, a wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká rí wọn. Kò pẹ́ sígbà yẹn, a rí ẹnì kan tó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ wa, a wá bi í bóyá ó mọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan. Ló bá dá wa lóhùn pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, inú mi á dùn láti mú yín lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́.” Lẹ́yìn tá a ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ náà, a fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) níṣìírí, a sì fi Bíbélì tù wọ́n nínú. Yàtọ̀ síyẹn, a tún ka lẹ́tà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí kọ sí wọn. Orí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn wú gan-an, ọkàn wọn sì balẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé: “Ojoojúmọ́ là ń gbàdúrà nítorí yín, ó sì dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi yín sílẹ̀.” A dúpẹ́ pé àdúrà Ìgbìmọ̀ Olùdarí ò já sásán lórí wọn. Ní báyìí, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fayọ̀ sin Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Rùwáńdà!

MO PINNU PÉ MI Ò NÍ FI JÈHÓFÀ SÍLẸ̀

Lẹ́yìn témi àti Elly ìyàwó mi ọ̀wọ́n ti ṣègbéyàwó fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58), ó kú lọ́dún 2011, ó sì dùn mí gan-an. Mo sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára mi fún Jèhófà, ó sì tù mí nínú. Nǹkan míì tó jẹ́ kára tù mí ni pé mo máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún báyìí, mo ṣì máa ń wàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, inú mi dùn pé mo láǹfààní láti máa ran Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Belgium lọ́wọ́, mo máa ń sọ ìrírí mi fáwọn ará, mo sì máa ń bẹ àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin wò ní Bẹ́tẹ́lì.

Nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) sẹ́yìn ni mo kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà. Àtìgbà yẹn ni mo ti mọ Jèhófà, inú mi sì dùn pé mo túbọ̀ ń sún mọ́ ọn. Mo mà dúpẹ́ o pé látìgbà yẹn títí di báyìí, Jèhófà ń gbọ́ àdúrà mi.—Sm. 66:19. b

a Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Schrantz wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 1975 ojú ìwé 211.

b Arákùnrin Marcel Gillet kú ní February 4, 2023, nígbà tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́.