Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Bẹ̀rù Jèhófà?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Bẹ̀rù Jèhófà?

“Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.”​—SM. 25:14.

ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Kí ni Sáàmù 25:14 sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà tímọ́tímọ́?

 ÀWỌN ìwà wo lo rò pé ó yẹ kó o ní tó o bá fẹ́ kí ìwọ àtẹnì kan di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́? Ó ṣeé ṣe kó o sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ó dájú pé táwọn méjèèjì bá máa di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, o ò ní ronú pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù ara wọn. Àmọ́ bí ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé ṣe sọ, àwọn tó bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ gbọ́dọ̀ máa “bẹ̀rù” rẹ̀.​—Ka Sáàmù 25:14.

2 Bóyá ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tàbí kò tíì pẹ́, gbogbo wa ló yẹ ká máa bẹ̀rù Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́ kí ló ń fi hàn pé ẹnì kan bẹ̀rù Ọlọ́run? Kí lá jẹ́ ká máa bẹ̀rù Jèhófà? Kí la lè kọ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run lára ìríjú kan tó ń jẹ́ Ọbadáyà, Àlùfáà Àgbà Jèhóádà àti Ọba Jèhóáṣì?

KÍ LÓ Ń FI HÀN PÉ ẸNÌ KAN BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN?

3. Ṣàlàyé ohun tó máa ń mú kẹ́rù bà wá àti ìpalára tó lè ṣe fún wa.

3 Ẹ̀rù lè bà wá tá a bá rí i pé nǹkan kan lè ṣe wá léṣe. Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ dáa torí á mú ká gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, o ò ní rìn ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kan kó o má bàa ṣubú. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá rí ohun tó lè ṣe wá léṣe, a máa sá fún un. Bákan náà, a ò ní sọ tàbí ṣe ohun tó máa dun ọ̀rẹ́ wa torí ẹ̀rù ń bà wá pé ìyẹn lè da àárín wa rú.

4. Báwo ni Sátánì ṣe fẹ́ ká máa bẹ̀rù Jèhófà?

4 Sátánì fẹ́ ká máa gbọ̀n jìnnìjìnnì tá a bá ti gbọ́ nípa Jèhófà. Irú èrò tí Élífásì ní nípa Jèhófà náà ni Sátánì fẹ́ káwa náà ní pé Jèhófà máa ń gbẹ̀san, ó máa ń bínú, kò sì sí bá a ṣe lè tẹ́ ẹ lọ́rùn. (Jóòbù 4:18, 19) Kódà, Sátánì fẹ́ ká bẹ̀rù Jèhófà débi tá ò fi ní jọ́sìn ẹ̀ mọ́. Torí náà, tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa, a gbọ́dọ̀ kọ́ bí àá ṣe máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, ká má sì ṣe ohun tó máa dùn ún.

5. Kí ló ń fi hàn pé ẹnì kan bẹ̀rù Ọlọ́run?

5 Ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an, kò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe àárín wọn jẹ́. Irú “ìbẹ̀rù Ọlọ́run” yìí ni Jésù ní. (Héb. 5:7) Kì í gbọ̀n jìnnìjìnnì torí Jèhófà. (Àìsá. 11:2, 3) Dípò bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu. (Jòh. 14:21, 31) Torí náà bíi ti Jésù, àwa náà ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, a sì bẹ̀rù ẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó gbọ́n, onídàájọ́ òdodo ni, ó sì lágbára. A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, inú ẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà ẹ̀. Torí náà, tá a bá ṣàìgbọràn sí Jèhófà, inú ẹ̀ ò ní dùn, àmọ́ tá a bá ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu, inú ẹ̀ máa dùn.​—Sm. 78:41; Òwe 27:11.

KỌ́ BÉÈYÀN ṢE Ń BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN

6. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà kọ́ béèyàn ṣe lè ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. (Sáàmù 34:11)

6 Wọn ò bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run mọ́ wa, ṣe ló yẹ ká kọ́ ọ. (Ka Sáàmù 34:11.) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa kíyè sí àwọn nǹkan tó dá. Bá a bá ṣe ń rí ọgbọ́n Ọlọ́run, agbára rẹ̀ àti ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tó ní sí wa lára “àwọn ohun tó dá,” bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. (Róòmù 1:20) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Adrienne sọ pé, “tí mo bá ń wo gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá, ó máa ń jẹ́ kí n rí i pé ọlọ́gbọ́n ni. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí n gbà pé ó mọ ohun tó dáa jù fún mi.” Torí pé arábìnrin yìí ronú jinlẹ̀ nípa ọgbọ́n Jèhófà tó rí lára àwọn ohun tó dá, ó sọ pé, “Mi ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba àárín èmi àti Jèhófà jẹ́ torí pé òun ni Orísun ìwàláàyè mi.” Lọ́sẹ̀ yìí, ṣé o lè lo àkókò díẹ̀ láti fi ronú nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà dá? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, wàá sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.​—Sm. 111:2, 3

7. Báwo ni àdúrà ṣe lè jẹ́ ká máa bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tó tọ́?

7 Ọ̀nà míì tá a lè gbà kọ́ béèyàn ṣe ń bẹ̀rù Ọlọ́run ni pé ká máa gbàdúrà déédéé. Bá a bá ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa mọ irú ẹni tó jẹ́. Gbogbo ìgbà tá a bá ní kó fún wa lókun láti fara da ìṣòro làá máa rántí bí agbára tó ní ṣe pọ̀ tó. Tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó jẹ́ kí ọmọ ẹ̀ kú nítorí wa, ṣe là ń rán ara wa létí bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ṣe pọ̀ tó. Bákan náà, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ó máa ń jẹ́ ká rántí pé ọlọ́gbọ́n ni Jèhófà. Irú àwọn àdúrà yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. Àwọn àdúrà yẹn tún máa ń jẹ́ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́.

8. Kí la lè ṣe ká lè máa bẹ̀rù Ọlọ́run nìṣó?

8 Ká lè máa bẹ̀rù Ọlọ́run nìṣó, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn ló máa jẹ́ ká rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn tó hùwà rere àtàwọn tó hùwà burúkú nínú Bíbélì. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, ìyẹn Ọbadáyà tó jẹ́ ìríjú Ọba Áhábù àti Àlùfáà Àgbà Jèhóádà. Lẹ́yìn náà, a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára Ọba Jèhóáṣì ti ilẹ̀ Júdà tó ṣe dáadáa níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ tó fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà tó yá.

NÍGBOYÀ BÍI TI ỌBADÁYÀ TÓ BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN

9. Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà tí Ọbadáyà ní ṣe ràn án lọ́wọ́? (1 Àwọn Ọba 18:3, 12)

9 Nígbà tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Ọbadáyà, b ó sọ pé: “Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà gidigidi.” (Ka 1 Àwọn Ọba 18:3, 12.) Báwo ni ìbẹ̀rù tó tọ́ yìí ṣe ran Ọbadáyà lọ́wọ́? Ó ràn án lọ́wọ́ torí ó mú kó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó sì ṣeé fọkàn tán. Ìyẹn ló mú kí ọba fi ṣe alábòójútó agbo ilé rẹ̀. (Fi wé Nehemáyà 7:2.) Torí pé Ọbadáyà bẹ̀rù Jèhófà, ìyẹn tún jẹ́ kó nígboyà gan-an, ó sì dájú pé ó nílò ànímọ́ yìí. Ìdí ni pé ó gbé ayé lásìkò Ọba Áhábù tó ṣohun tó “burú lójú Jèhófà ju ti gbogbo àwọn [ọba] tí ó wà ṣáájú rẹ̀.” (1 Ọba 16:30) Bákan náà, Jésíbẹ́lì ìyàwó Áhábù tó ń sin Báálì kórìíra Jèhófà gan-an débi pé kò fẹ́ kí ọmọ Ísírẹ́lì èyíkéyìí tó wà ní ìjọba àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa sin Jèhófà. Kódà, ó pa ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì Ọlọ́run. (1 Ọba 18:4) Kò sí àní-àní pé nǹkan ò rọrùn fún Ọbadáyà lásìkò tó sin Jèhófà.

10. Báwo ni Ọbadáyà ṣe fi hàn pé òun nígboyà gan-an?

10 Báwo ni Ọbadáyà ṣe fi hàn pé òun nígboyà gan-an? Nígbà tí Jésíbẹ́lì ń wá àwọn wòlíì Ọlọ́run káàkiri kó lè pa wọ́n, Ọbadáyà kó ọgọ́rùn-ún (100) lára wọn, ó fi wọ́n pa mọ́ ‘ní àádọ́ta-àádọ́ta sínú ihò, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ àti omi.’ (1 Ọba 18:13, 14) Ohun tí Ọbadáyà ṣe yìí gba ìgboyà, àmọ́ ká sọ pé Jésíbẹ́lì gbọ́ nípa ẹ̀ ni, ṣe ló máa pa á. Ká sòótọ́, ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Ọbadáyà torí pé kò fẹ́ kú. Àmọ́ Ọbadáyà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn tó ń sìn ín ju ẹ̀mí ara ẹ̀ lọ.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa, arákùnrin kan fìgboyà kó àwọn ìwé wa lọ fáwọn ará (Wo ìpínrọ̀ 11) c

11. Báwo làwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ṣe fìwà jọ Ọbadáyà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Lónìí, ọ̀pọ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, a máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìjọba, àmọ́ bíi ti Ọbadáyà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí ò fi Jèhófà sílẹ̀. (Mát. 22:21) Wọ́n fi hàn pé Ọlọ́run làwọn bẹ̀rù torí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí i dípò èèyàn. (Ìṣe 5:29) Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé wọ́n ń wàásù, wọ́n sì ń ṣèpàdé níkọ̀kọ̀. (Mát. 10:16, 28) Àwọn ará ń rí i dájú pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn ń rí ìwé ètò Ọlọ́run gbà torí ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Henri tó ń gbé lórílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa láwọn àkókò kan. Lásìkò yẹn, Henri yọ̀ǹda ara ẹ̀ kó lè máa pín àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì fáwọn ará. Ó sọ pé: “Mo máa ń tijú. Àmọ́, ó dá mi lójú pé bí mo ṣe ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà gan-an ló jẹ́ kí n nígboyà tí mo fi ṣiṣẹ́ náà.” Ṣé ìwọ náà lè nígboyà bíi ti Henri? Bẹ́ẹ̀ ni, o lè nígboyà tó o bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́.

JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ BÍI TI ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ JÈHÓÁDÀ TÓ BẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN

12. Kí ni Àlùfáà Àgbà Jèhóádà àtìyàwó ẹ̀ ṣe tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

12 Àlùfáà Àgbà Jèhóádà bẹ̀rù Jèhófà. Ìyẹn ló mú kó jẹ́ olóòótọ́, kó sì tún gba àwọn míì níyànjú pé kí wọ́n máa jọ́sìn Jèhófà. Ó fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí Ataláyà ọmọbìnrin Jésíbẹ́lì fipá gbàjọba nílẹ̀ Júdà. Àwọn èèyàn bẹ̀rù ẹ̀ gan-an torí pé èèyàn burúkú ni. Kódà, torí pé ó fẹ́ di ọbabìnrin, ó pa àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀ ọkùnrin torí kó lè máa ṣàkóso lọ! (2 Kíró. 22:10, 11) Àmọ́ kò rí Jèhóáṣì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀ pa torí pé Jèhóṣábéátì ìyàwó Jèhóádà dáàbò bò ó. Òun àti ọkọ ẹ̀ ló gbé ọmọ náà pa mọ́, wọ́n sì ń tọ́jú ẹ̀. Ohun tí Jèhóádà àti Jèhóṣábéátì ṣe yìí ló jẹ́ kí àwọn ọmọ Dáfídì máa jọba nìṣó. Lásìkò yẹn, Jèhóádà ti dàgbà, àmọ́ ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kò sì bẹ̀rù.​—Òwe 29:25.

13. Kí ni Jèhóádà tún ṣe nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje tó fi hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?

13 Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà tún fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ó dá ọgbọ́n kan. Tí ọgbọ́n náà bá ṣiṣẹ́, Jèhóáṣì máa di ọba, á sì jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì, àmọ́ tí ọgbọ́n náà ò bá ṣiṣẹ́, ó ṣeé ṣe kí Jèhóádà fikú ṣèfà jẹ. Ṣùgbọ́n Jèhófà ràn án lọ́wọ́, ọgbọ́n tó dá yìí ṣiṣẹ́. Àwọn ìjòyè ní Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ Léfì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jèhóádà, wọ́n fi Jèhóáṣì jọba, wọ́n sì pa Ataláyà. (2 Kíró. 23:1-5, 11, 12, 15; 24:1) Jèhóádà wá “dá májẹ̀mú láàárín Jèhófà àti ọba àti àwọn èèyàn náà, pé àwọn á máa jẹ́ èèyàn Jèhófà nìṣó.” (2 Ọba 11:17) Jèhóádà “tún fi àwọn aṣọ́bodè sí àwọn ẹnubodè ilé Jèhófà kí aláìmọ́ èyíkéyìí má bàa wọlé.”​—2 Kíró. 23:19.

14. Báwo ni wọ́n ṣe bọlá fún Jèhóádà torí pé ó bọlá fún Jèhófà?

14 Jèhófà ti sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: “Àwọn tó ń bọlá fún mi ni màá bọlá fún.” Ohun tí Jèhófà sì ṣe fún Jèhóádà nìyẹn, ó san èrè fún un. (1 Sám. 2:30) Bí àpẹẹrẹ, ó ní kí wọ́n kọ iṣẹ́ rere tí àlùfáà àgbà yìí ṣe sínú Bíbélì ká lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀. (Róòmù 15:4) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jèhóádà kú, wọ́n bọlá fún un lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé wọ́n sin ín “sí Ìlú Dáfídì níbi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí, nítorí ó ti ṣe dáadáa ní Ísírẹ́lì sí Ọlọ́run tòótọ́ àti sí ilé Rẹ̀.”​—2 Kíró. 24:15, 16.

Tá a bá bẹ̀rù Jèhófà bíi ti Àlùfáà Àgbà Jèhóádà, àá máa ran àwọn ará wa lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 15) d

15. Kí la kọ́ nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhóádà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhóádà lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ ká lè máa bẹ̀rù Jèhófà bó ṣe tọ́. Àwọn alábòójútó nínú ìjọ lè fara wé Jèhóádà tí wọ́n bá ń wà lójúfò, tí wọ́n sì ń dáàbò bo àwọn ará ìjọ. (Ìṣe 20:28) Àwọn àgbàlagbà náà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhóádà pé táwọn bá ń bẹ̀rù Jèhófà, táwọn sì jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà lè lo àwọn láti mú ìfẹ́ Rẹ̀ ṣẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà ò pa yín tì. Ẹ̀yin ọ̀dọ́ náà lè kíyè sí bí Jèhófà ṣe hùwà tó dáa sí Jèhóádà, kẹ́ ẹ sì fara wé e. Ó yẹ kẹ́yin náà máa hùwà tó dáa sáwọn àgbàlagbà, kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn, pàápàá àwọn tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Òwe 16:31) Paríparí ẹ̀, gbogbo wa la lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìjòyè àtàwọn ọmọ Léfì tó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jèhóádà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ‘àwọn tó ń ṣàbójútó’ wa, ká sì máa ṣègbọràn sí wọn.​—Héb. 13:17.

MÁ FÌWÀ JỌ ỌBA JÈHÓÁṢÌ

16. Kí ló fi hàn pé Ọba Jèhóáṣì ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú?

16 Ọba Jèhóáṣì jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere Jèhóádà. (2 Ọba 12:2) Ìyẹn jẹ́ kó lè máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà látìgbà tó ti wà lọ́dọ̀ọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhóádà kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sáwọn ìjòyè Júdà tí ò sin Jèhófà mọ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Òun àtàwọn èèyàn ilẹ̀ náà “bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn òpó òrìṣà àti àwọn òrìṣà.” (2 Kíró. 24:4, 17, 18) Ọ̀rọ̀ náà dun Jèhófà gan-an, torí náà, “ó ń rán àwọn wòlíì sáàárín wọn léraléra láti mú wọn pa dà wá . . . , àmọ́ wọn ò gbọ́.” Kódà, wọn ò fetí sí Sekaráyà tó jẹ́ ọmọ Jèhóádà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wòlíì àti àlùfáà ni, tó sì tún jẹ́ mọ̀lẹ́bí Jèhóáṣì. Ó ṣeni láàánú pé dípò tí Ọba Jèhóáṣì ò bá fi moore ohun tí ìdílé Jèhóádà ṣe fún un, ńṣe ló ní kí wọ́n lọ pa Sekaráyà.​—2 Kíró. 22:11; 24:19-22.

17. Kí ló gbẹ̀yìn Jèhóáṣì?

17 Jèhóáṣì ò bẹ̀rù Jèhófà lọ́nà tó tọ́, ìdí nìyẹn tí ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò fi dáa. Jèhófà ti sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: “Màá kórìíra àwọn tí kò kà mí sí.” (1 Sám. 2:30) Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ogun Síríà tí ò tó nǹkan ṣẹ́gun Jèhóáṣì àtàwọn ‘ọmọ ogun ẹ̀ tó pọ̀ gan-an,’ ó sì fara ‘gbọgbẹ́ yán-na-yàn-na.’ Lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun Síríà lọ, àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pa á torí pé ó pa Sekaráyà. Torí pé ọba yìí burú gan-an, “wọn ò sin ín sí ibi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí.”​—2 Kíró. 24:23-25; wo “son of Barachiah” nínú àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mátíù 23:35 nwtsty-E.

18. Kí ni Jeremáyà 17:7, 8 sọ tó jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká fìwà jọ Jèhóáṣì?

18 Kí la kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jèhóáṣì? Ṣe ni Jèhóáṣì dà bí igi ńlá kan tí gbòǹgbò ẹ̀ ò lágbára, tí wọ́n wá fi igi kan tì í kó má bàa ṣubú. Tí atẹ́gùn bá fẹ́, ṣe ni igi náà máa wó lulẹ̀. Nígbà tí Jèhóádà tó ń ran Jèhóáṣì lọ́wọ́ kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sáwọn tí ò sin Jèhófà mọ́, bí òun náà ò ṣe sin Jèhófà mọ́ nìyẹn. Àfiwé yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá fẹ́ bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́, ìrànlọ́wọ́ táwọn tá a jọ ń sin Jèhófà àtàwọn ará ilé wa ń ṣe fún wa nìkan kọ́ ló yẹ ká gbára lé. Kí àjọṣe wa àti Jèhófà lè máa lágbára sí i, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ká máa ṣàṣàrò, ká sì máa gbàdúrà. Ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un.​—Ka Jeremáyà 17:7, 8; Kól. 2:6, 7.

19. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe?

19 Jèhófà ò retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe wà nínú Oníwàásù 12:13, ó sọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni gbogbo ojúṣe èèyàn.” Tá a bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run, àá lè fara da àwọn àdánwò tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, àá sì jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Ọbadáyà àti Jèhóádà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sóhun tó máa ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

a Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìbẹ̀rù” nínú Bíbélì. Ohun tí ìjíròrò náà bá dá lé ló máa fi hàn bóyá ohun tó ń kó jìnnìjìnnì bá èèyàn ni wọ́n ń sọ, ó sì lè jẹ́ ọ̀wọ̀ tàbí ẹ̀rù ni wọ́n ń sọ nípa ẹ̀. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká ní ìbẹ̀rù táá mú ká jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà Baba wa ọ̀run, ká sì nígboyà.

b Ọbadáyà tá à ń sọ yìí kì í ṣe wòlíì Ọbadáyà tó gbé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn wòlíì tó kọ ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ Ọbadáyà.

c ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí bí arákùnrin kan ṣe ń kó ìwé lọ fáwọn ará níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa.

d ÀWÒRÁN: Arábìnrin ọ̀dọ́ kan ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ arábìnrin àgbàlagbà kan, kó lè mọ bá á ṣe máa wàásù lórí fóònù; arákùnrin àgbàlagbà kan ń wàásù níbi àtẹ ìwé, ó sì fi hàn pé òun nígboyà; arákùnrin kan tó mọṣẹ́ gan-an ń dá àwọn arákùnrin míì lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa tún Ilé Ìpàdé ṣe.