Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Pọkàn Pọ̀ Sórí Ọ̀rọ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Pọkàn Pọ̀ Sórí Ọ̀rọ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù

“Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”SM. 83:18.

ORIN: 46, 136

1, 2. (a) Ọ̀rọ̀ pàtàkì wo ló kan gbogbo aráyé? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run?

OWÓ lọ̀pọ̀ èèyàn kà sí pàtàkì jù lóde òní. Ohun tó jẹ wọ́n lógún kò ju bí wọ́n á ṣe dọlọ́rọ̀ tàbí bí ọlá wọn kò ṣe ní rẹ̀yìn. Ohun tó sì gba àwọn míì lọ́kàn kò ju ọ̀rọ̀ ìdílé wọn, ìlera wọn àti bí wọ́n ṣe máa mókè nínú nǹkan tí wọ́n dáwọ́ lé.

2 Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó gba aráyé lọ́kàn ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe jẹ́ kí ohun míì gbà wá lọ́kàn. Kí làwọn nǹkan míì tó tún lè gbà wá lọ́kàn? Ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu lè gbà wá lọ́kàn débi pé a lè má rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Àwọn ìṣòro wa sì lè gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní fohun tó ṣe pàtàkì jù yìí sọ́kàn mọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, ó máa rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro wa. Nípa bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ?

3. Kí ni Sátánì dọ́gbọ́n sọ nípa ìṣàkóso Ọlọ́run?

3 Sátánì Èṣù dọ́gbọ́n sọ pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ó fẹ̀sùn  kan Jèhófà pé kò nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ dénú àti pé ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso kò dáa. Kódà, ó dọ́gbọ́n sọ pé àwọn èèyàn á gbádùn tí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn, nǹkan á sì ṣẹnuure fún wọn. (Jẹ́n. 3:1-5) Sátánì tún sọ pé ojú ayé lásán ni ìjọsìn tá à ń ṣe fún Ọlọ́run àti pé tíyà bá jẹ wá, a máa gbàgbé Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5) Kí Jèhófà lè fi hàn pé ẹ̀sùn tí Èṣù fi kàn án kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ó fàyè gba àwa èèyàn láti ṣàkóso ara wa ká lè rí i pé nǹkan ò lè ṣẹnuure fún wa tá ò bá sí lábẹ́ òun.

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kí Jèhófà yanjú ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án?

4 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà mọ̀ pé irọ́ lẹ̀sùn tí Èṣù fi kan òun. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì pé kó fìdí ẹ̀sùn rẹ̀ múlẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ náà kan gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì. (Ka Sáàmù 83:18.) Ó ṣe tán, Ádámù àti Éfà kọ ìṣàkóso Jèhófà, ọ̀pọ̀ ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn náà. Ìyẹn lè mú kí ọ̀pọ̀ máa ronú pé bóyá òótọ́ lẹ̀sùn tí Èṣù fi kan Ọlọ́run. Kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó lè wà, àfi kí ọ̀rọ̀ náà yanjú, kó sì ṣe kedere sáwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, rúgúdù á ṣì máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn níbi gbogbo àti nínú ìdílé. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti yanjú ọ̀rọ̀ náà, gbogbo ẹ̀dá láá fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀ títí láé. Nípa bẹ́ẹ̀, àlàáfíà á wà láyé àti lọ́run.Éfé. 1:9, 10.

5. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè fi hàn pé a fara wa sábẹ́ àkóso Jèhófà?

5 Jèhófà á jẹ́ kó ṣe kedere pé òun nìkan lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, ìṣàkóso Sátánì àti tèèyàn á forí ṣánpọ́n, Ọlọ́run á sì palẹ̀ wọn mọ́. Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi máa ṣàṣeyọrí. Torí pé àwọn kan máa jẹ́ adúróṣinṣin, á ṣe kedere pé àwọn èèyàn lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kí wọ́n sì fara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀. (Aísá. 45:23, 24) Ṣé wàá fẹ́ wà lára irú àwọn adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀? Kò sí àní-àní pé wàá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà ká lè jẹ́ adúróṣinṣin, ó yẹ ká lóye bọ́rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó, ká má sì jẹ́ kóhun míì gbà wá lọ́kàn.

Ó ṢE PÀTÀKÌ JU ÌGBÀLÀ WA LỌ

6. Báwo lọ̀rọ̀ bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ti ṣe pàtàkì tó?

6 Bá a ṣe sọ, ọ̀rọ̀ pàtàkì tó kan àwa èèyàn ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Kódà, ó ṣe pàtàkì ju bó ṣe máa yanjú ìṣòro tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ní lọ. Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé ìgbàlà wa ò ṣe pàtàkì tàbí pé Jèhófà kò rí tiwa rò? Rárá. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.

7, 8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí Ọlọ́run mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?

7 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an, ó sì mọyì wa. Tinútinú ló fi yọ̀ǹda kí Ọmọ rẹ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa ká lè rí ìgbàlà àti ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16; 1 Jòh. 4:9) Tí Jèhófà ò bá mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Èṣù á fìyẹn kẹ́wọ́, á sọ pé irọ́ ni Ọlọ́run ń pa àti pé alákòóso tí kò fẹ́ ire fáwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ni. Ìyẹn á tún fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ àwọn alátakò tó ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.” (2 Pét. 3:3, 4) Torí náà, Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, á sì rí i dájú pé àwọn olóòótọ́ èèyàn rí ìgbàlà nígbà tó bá fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. (Ka Aísáyà 55:10, 11.) Ohun míì ni pé ìfẹ́ ni Jèhófà fi ń ṣàkóso. Torí náà, ó dá wa lójú pé títí láé ni Jèhófà á máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, á sì máa ṣìkẹ́ wọn.Ẹ́kís. 34:6.

8 A gbà pé bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run lọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù. Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé a  fojú kéré ìgbàlà wa tàbí pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Ńṣe la wulẹ̀ ń fi hàn pé jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run ṣe pàtàkì ju ìgbàlà wa lọ. Tá a bá fi èyí sọ́kàn, á jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà, ká sì fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run la fara mọ́.

BÁ A ṢE LÈ NÍ ÈRÒ TÓ TỌ́ BÍI TI JÓÒBÙ

9. Kí ni Sátánì sọ nípa Jóòbù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

9 Nínú ìwé Jóòbù tó wà lára àwọn ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ kọ nínú Bíbélì, a rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn ní òye tó tọ́ nípa ìṣòro tó ń dé bá wa. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì sọ pé tí ojú bá pọ́n Jóòbù gan-an, á gbàgbé Ọlọ́run. Sátánì tiẹ̀ dábàá pé kí Jèhófà fúnra rẹ̀ fìyà jẹ Jóòbù. Àmọ́ Jèhófà ò ṣe bẹ́ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló gba Sátánì láyè láti dán Jóòbù wò. Jèhófà sọ pé: “Ohun gbogbo tí ó ní wà ní ọwọ́ rẹ.” (Ka Jóòbù 1:7-12.) Bí ìṣòro ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ lura fún Jóòbù nìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kú, gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ run pátápátá, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá sì kú. Sátánì kọlu Jóòbù lọ́nà tó mú kó dà bíi pé Ọlọ́run gan-an ló ń fìyà jẹ ẹ́. (Jóòbù 1:13-19) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sátánì fi àìsàn burúkú kọlu Jóòbù. (Jóòbù 2:7) Ẹ̀dùn ọkàn tó bá Jóòbù tún peléke nígbà tí ìyàwó rẹ̀ fún un nímọ̀ràn tí kò bọ́gbọ́n mu táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta sì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i.Jóòbù 2:9; 3:11; 16:2.

10. (a) Báwo ni Jóòbù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run? (b) Àṣìṣe wo ni Jóòbù ṣe?

10 Kí wá la lè sọ nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jóòbù? Ó ṣe kedere pé irọ́ ni ẹ̀sùn náà já sí. Ìdí sì ni pé Jóòbù kò fi Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 27:5) Àmọ́ o, àwọn ìgbà kan wà tí Jóòbù ṣí inú rò, tó sì ṣi ọ̀rọ̀ sọ. Ó ní olódodo lòun, òun ò sì rídìí tó fi yẹ kóun máa jìyà. Kódà ó ní kí Ọlọ́run jẹ́ kóun mọ ìdí tíyà fi ń jẹ òun. (Jóòbù 7:20; 13:24) A lè lóye ìdí tí Jóòbù fi ronú lọ́nà yẹn, ó ṣe tán ìyà kì í ṣe omi ọbẹ̀. Síbẹ̀ Ọlọ́run rí i pé ó yẹ kóun tún èrò Jóòbù ṣe. Kí ni Jèhófà sọ fún un?

11, 12. Kí ni Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù mọ̀, kí wá ni Jóòbù ṣe?

11 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jóòbù sọ kún odindi orí mẹ́rin nínú ìwé Jóòbù, ìyẹn orí 38 sí 41. Síbẹ̀, kò síbi tí Jèhófà ti sọ ohun tó fa ìyà tó ń jẹ Jóòbù fún un. Jèhófà ò ṣàlàyé ìdí tí Jóòbù fi ń jìyà fún un bí ẹni pé Jèhófà fẹ́ gbèjà ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà fẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé kò ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ ní ìfiwéra sí òun. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún mú kí Jóòbù rí i pé ọ̀rọ̀ míì wà tó ṣe pàtàkì ju ìyà tó ń jẹ ẹ́ lọ, ìyẹn ló sì yẹ kó fọkàn sí. (Ka Jóòbù 38:18-21.)  Ohun tí Jèhófà ṣe yẹn mú kí Jóòbù tún inú rò, ó sì wá ní èrò tó tọ́.

12 Ṣé ìbáwí tó sojú abẹ níkòó tí Jèhófà fún Jóòbù yẹn kò le jù pẹ̀lú gbogbo ohun tójú Jóòbù ti rí? Rárá, kódà Jóòbù alára kò sọ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà le. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà náà ò dẹrùn, síbẹ̀ ó mọrírì ìbáwí tí Jèhófà fún un. Ó tiẹ̀ sọ pé: ‘Mo yíhùn pa dà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.’ Jèhófà sojú abẹ níkòó lóòótọ́, àmọ́ ó tu Jóòbù lára. (Jóòbù 42:1-6) Ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Élíhù náà tún èrò Jóòbù ṣe. (Jóòbù 32:5-10) Lẹ́yìn tí Jóòbù gba ìbáwí tí Jèhófà fún un tó sì tún èrò rẹ̀ pa, Jèhófà jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé inú òun dùn bí Jóòbù ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí òun láìka àdánwò tó kojú.Jóòbù 42:7, 8.

13. Báwo ni ìbáwí tí Jèhófà fún Jóòbù ṣe máa ṣe é láǹfààní kódà lẹ́yìn tó bọ́ nínú àdánwò náà?

13 Ìbáwí tí Jèhófà fún Jóòbù máa ṣe é láǹfààní kódà lẹ́yìn tó bọ́ nínú àdánwò náà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn nǹkan pa dà bọ̀ sípò fún Jóòbù. Ìdí sì ni pé ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ló “wá ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta.” (Jóòbù 42:12-14) Kò sí àní-àní pé Jóòbù á máa ṣàárò àwọn ọmọ rẹ̀ tí Sátánì pa. Ó ṣeé ṣe kó máa rántí ìyà tó jẹ. Ká tiẹ̀ sọ pé ó wá pàpà lóye ẹni tó wà lẹ́yìn ìyà tó jẹ ẹ́, ó lè máa rò ó pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á pé kóun jẹ adúrú ìyà yẹn. Èyí ó wù kó máa rò, ó dájú pé tó bá ń ronú lórí ìbáwí tí Ọlọ́run fún un, á jẹ́ kó máa fojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ tó ṣẹlẹ̀ náà, ìyẹn á sì tù ú nínú.Sm. 94:19.

Ṣé a lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ṣe pàtàkì jù dípò àwọn ìṣòro wa? (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù?

14 Tá a bá ń ronú lórí ìtàn Jóòbù, àwa náà máa ní èrò tó tọ́, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìtùnú. Ó ṣe tán, Jèhófà mú kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìtàn náà “fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù? Kókó pàtàkì ibẹ̀ ni pé: Ká má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ara wa gbà wá lọ́kàn débi tá a fi máa gbàgbé ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà, ìyẹn bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Ká sì máa rántí pé gbogbo wa pátá lọ̀rọ̀ náà kàn ní ti pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò bíi ti Jóòbù.

15. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ lábẹ́ àdánwò, kí nìyẹn máa fi hàn?

15 A máa rí ìtùnú tá a bá ń ronú lórí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, a mọ ìdí tá a fi ń kojú àdánwò. Kì í ṣe pé Jèhófà ń bínú sí wa la ṣe ń kojú àdánwò, kàkà bẹ́ẹ̀ àdánwò ń jẹ́ ká lè fi  hàn pé a fara wa sábẹ́ àkóso Ọlọ́run. (Òwe 27:11) Tá a bá fara da àdánwò, a máa wà ní “ipò ìtẹ́wọ́gbà,” èyí sì máa jẹ́ kí ìrètí wa túbọ̀ dájú. (Ka Róòmù 5:3-5.) Ìtàn Jóòbù jẹ́ ká rí i pé “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Ják. 5:11) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa san àwa àti gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ lẹ́san. Tá a bá ń fi kókó yìí sọ́kàn, èyí á mú ká lè ‘fara dà á ní kíkún, ká sì ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’Kól. 1:11.

RÍ I PÉ O PỌKÀN PỌ̀

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bá a ṣe máa fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run la fara mọ́?

16 Ká sòótọ́, tá a bá ń kojú ìṣòro, kì í rọrùn láti fi sọ́kàn pé bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso lohun tó ṣe pàtàkì jù. Kódà àwọn ìṣòro tí ò tó nǹkan lè di bàbàrà lójú wa tá ò bá gbọ́kàn kúrò lórí wọn. Torí náà, ó yẹ ká máa rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bá a ṣe máa fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run la fara mọ́ tá a bá ń kojú àdánwò.

17. Tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà?

17 Tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, àá lè pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Renee ní àrùn rọpárọsẹ̀, ará máa ń ro ó gan-an, ó sì tún ní àrùn jẹjẹrẹ. Tó bá wà nílé ìwòsàn, ó máa ń wàásù fáwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn, àwọn aláìsàn míì àtàwọn àlejò tó ń wá síbẹ̀. Kódà nílé ìwòsàn kan, ọgọ́rin [80] wákàtí ló fi wàásù láàárín ọ̀sẹ̀ méjì àtààbọ̀ péré. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Renee mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú, bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ló gbà á lọ́kàn, èyí sì fún un lókun láti fara da àwọn ìṣòro rẹ̀.

18. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan ṣe jẹ́ ká rí i pé àǹfààní wà nínú kéèyàn pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà?

18 Tá a bá ń kojú kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé àtàwọn àníyàn ojoojúmọ́, ó lè má rọrùn láti pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù náà. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer lo ọjọ́ mẹ́ta gbáko ní pápákọ̀ òfuurufú kan torí ó ń dúró de ọkọ̀ òfuurufú tó máa gbé e lọ sílé. Tó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àkókò tí wọ́n máa gbéra, wọ́n á tún ní ọkọ̀ òfuurufú náà ò lọ mọ́. Kò mọ ẹnikẹ́ni níbẹ̀, ó sì ti rẹ̀ ẹ́, ká sòótọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè pinni lẹ́mìí. Àmọ́ ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún òun lókun kóun lè ran àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìṣòro náà lọ́wọ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Jennifer wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì fi ọ̀pọ̀ ìwé síta. Ó wá sọ pé, “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ mí lásìkò yẹn, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, ó sì fún mi lókun láti gbé orúkọ rẹ̀ ga.” Láìka ìṣòro sí, arábìnrin yìí pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà.

19. Ìṣàkóso tani àwa èèyàn Jèhófà fara mọ́?

19 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, èyí sì mú ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké. Ọjọ́ pẹ́ táwa èèyàn Ọlọ́run ti fara wa sábẹ́ ìṣàkóso Jèhófà torí pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Torí náà, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run.

20. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ohun tó ò ń ṣe láti mú káwọn míì gbà pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso?

20 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe láti mú káwọn míì gbà pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ ìsìn rẹ àti ìfaradà rẹ. (Sm. 18:25) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, wàá túbọ̀ mọ ìdí tó fi yẹ kó o fara rẹ sábẹ́ àkóso Jèhófà pátápátá àti ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.