Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fi ‘Nǹkan Wọ̀nyí Lé Àwọn Olùṣòtítọ́ Lọ́wọ́’

Fi ‘Nǹkan Wọ̀nyí Lé Àwọn Olùṣòtítọ́ Lọ́wọ́’

“Nǹkan wọ̀nyí ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.”2 TÍM. 2:2.

ORIN: 123, 53

1, 2. Ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe?

ÀWỌN èèyàn sábà máa ń fi iṣẹ́ wọn yangàn. Àpọ́nlé nirú wọn kà á sí táwọn èèyàn bá so iṣẹ́ wọn mọ́ orúkọ wọn, bí Ẹnjiníà Lámọrín tàbí Dókítà Làkáṣègbè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà láwọn ilẹ̀ kan, táwọn méjì bá pàdé ara wọn fúngbà àkọ́kọ́, wọ́n sábà máa ń béèrè pé, “Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?”

2 Nígbà míì, Bíbélì máa ń fi irú iṣẹ́ tí ẹnì kan ń ṣe sọ irú ẹni tó jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “Mátíù agbowó orí,” ‘Símónì oníṣẹ́ awọ’ àti “Lúùkù oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Mát. 10:3; Ìṣe 10:6; Kól. 4:14) Bíbélì so iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fáwọn kan mọ́ orúkọ wọn. Àpẹẹrẹ àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Ọba Dáfídì, wòlíì Èlíjà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin yìí mọyì iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn. Torí náà, táwa náà bá láwọn iṣẹ́ kan tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run, ó yẹ ká mọyì wọn.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn àgbàlagbà dá àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

3 Ọ̀pọ̀ wa ló fẹ́ràn iṣẹ́ tá à ń ṣe, ó sì wù wá pé ká máa ṣe iṣẹ́ náà lọ. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé láti ìgbà ayé Ádámù ni nǹkan ti yí bìrí, tó wá di pé bí ìran kan ṣe ń darúgbó ni ìran míì ń bọ́ sójú  ọpọ́n. (Oníw. 1:4) Torí èyí, àwọn ìpèníjà kan ti yọjú láàárín àwa èèyàn Jèhófà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lójoojúmọ́, ó sì ń gbòòrò sí i. Bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan tuntun, bẹ́ẹ̀ là ń rí àwọn ọ̀nà tuntun tá a lè gbà ṣe wọ́n, kódà ó lè gba pé ká lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé nígbà míì. Torí náà, kì í rọrùn fáwọn tó ti dàgbà láti bójú tó àwọn iṣẹ́ tuntun tó ń yọjú yìí. (Lúùkù 5:39) Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn àgbàlagbà yìí lè ṣe àwọn iṣẹ́ náà, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà tó wọn lọ́jọ́ orí ṣì lágbára àti okun jù wọ́n lọ. (Òwe 20:29) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn àgbàlagbà dá àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́ láti bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run.Ka Sáàmù 71:18.

4. Kí nìdí tí kò fi rọrùn fáwọn kan láti gbé lára iṣẹ́ wọn fáwọn míì? (Wo àpótí náà, “ Ìdí Táwọn Kan Kì Í Fi Í Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́.”)

4 Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn tó ń múpò iwájú láti gbé lára iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí. Ìdí sì ni pé inú àwọn kan kì í dùn tó bá di pé kí wọ́n gbéṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn míì. Ó máa ń ká àwọn míì lára pé àwọn ò ní lè bójú tó àwọn ojúṣe kan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò dá wọn lójú pé àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí á lè ṣe iṣẹ́ náà dáadáa. Àwọn kan sì lè ronú pé àwọn ò lè ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Bó ti wù kó rí, kò yẹ káwọn tí kò tó àwọn àgbàlagbà lọ́jọ́ orí bínú bí wọn ò bá fún wọn láfikún iṣẹ́, ṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe sùúrù.

5. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

5 Ẹ jẹ́ ká jíròrò kókó méjì nípa fífaṣẹ́ léni lọ́wọ́. Kókó àkọ́kọ́ ni pé báwo làwọn tó ti dàgbà ṣe lè ran àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba àwọn àfikún iṣẹ́, kí nìdí tó sì fi ṣe pàtàkì? (2 Tím. 2:2) Èkejì, kí nìdí tó fi yẹ káwọn tá à ń gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ní èrò tó tọ́ bí wọ́n ṣe ń ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí Ọba Dáfídì ṣe múra ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan.

DÁFÍDÌ MÚRA SÓLÓMỌ́NÌ SÍLẸ̀

6. Kí ni Ọba Dáfídì fẹ́ ṣe, àmọ́ kí ni Jèhófà sọ fún un?

6 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Dáfídì fi sá kiri torí Sọ́ọ̀lù, ó di Ọba ó sì ń gbé nínú ààfin tó tuni lára. Kò dùn mọ́ ọn nínú pé kò sí “ilé”  tàbí tẹ́ńpìlì kankan fún Jèhófà, torí náà ó wù ú pé kóun kọ́ ilé fún Jèhófà. Ó wá sọ fún wòlíì Nátánì pé: “Kíyè sí i, èmi ń gbé inú ilé kédárì, ṣùgbọ́n àpótí májẹ̀mú Jèhófà wà lábẹ́ àwọn aṣọ àgọ́.” Nátánì dáhùn pé: “Ohun gbogbo tí ó bá wà ní ọkàn-àyà rẹ ni kí o ṣe, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ.” Àmọ́ ohun tí Jèhófà sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Jèhófà ní kí Nátánì sọ fún Dáfídì pé: ‘Ìwọ kọ́ ni wàá kọ́ ilé tí màá gbé.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an tó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun á bù kún un, síbẹ̀ Jèhófà sọ fún un pé Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Dáfídì?1 Kíró. 17:1-4, 8, 11, 12; 29:1.

7. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tí Jèhófà sọ pé ọmọ rẹ̀ ló máa kọ́lé náà?

7 Dáfídì kò torí ìyẹn káwọ́ gbera, kó wá máa bínú pé wọn ò kúkú ní dárúkọ òun nígbà tí wọ́n bá ń sọ ẹni tó kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Ká sòótọ́, tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ni wọ́n pe ilé náà, kì í ṣe ti Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má dùn mọ́ Dáfídì nínú pé Jèhófà ò jẹ́ kóun ṣe ohun tó wà lọ́kàn òun, síbẹ̀ tọkàntara ló fi ṣètò àwọn òṣìṣẹ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí tí wọ́n sì kó irin, bàbà, fàdákà àti wúrà jọ títí kan àwọn igi kédárì. Bákan náà, ó tún fún Sólómọ́nì níṣìírí pé: “Wàyí o, ọmọkùnrin mi, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, kí o sì ṣe àṣeyọrí sí rere, kí o sì kọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.”1 Kíró. 22:11, 14-16.

8. Kí nìdí tí Dáfídì fi lè ronú pé bóyá ni Sólómọ́nì á lè ṣe iṣẹ́ náà, àmọ́ kí ló ṣe?

8 Ka 1 Kíróníkà 22:5. Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì ronú pé Sólómọ́nì kò ní lè bójú tó iṣẹ́ ńlá náà. Ó ṣe tán, tẹ́ńpìlì náà máa jẹ́ “ọlọ́lá ńlá lọ́nà títa yọ ré kọjá.” Sólómọ́nì ní tiẹ̀ ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Síbẹ̀, Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà á ran Sólómọ́nì lọ́wọ́ kíṣẹ́ náà lè di ṣíṣe. Torí náà, Dáfídì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó lè ṣe, ó sì kó àwọn ohun èlò tí wọ́n máa lò jọ rẹpẹtẹ.

JẸ́ KÍNÚ RẸ MÁA DÙN LÁTI DÁ ÀWỌN MÍÌ LẸ́KỌ̀Ọ́

Inú wa máa ń dùn bá a ṣe ń rí àwọn tí kò tíì di àgbàlagbà tí wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Kí láá jẹ́ kínú àwọn àgbàlagbà máa dùn bí wọ́n ṣe ń faṣẹ́ lé àwọn míì lọ́wọ́? Ṣàpèjúwe.

9 Kò yẹ káwọn tó ti dàgbà banú jẹ́ tó bá di pé kí wọ́n gbé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kí nǹkan tẹ̀ síwájú tí wọ́n bá kọ́ àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí kí wọ́n lè bójú tó iṣẹ́. Ó yẹ kínú àwọn àgbàlagbà máa dùn bí wọ́n ṣe ń rí i táwọn tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń bójú tó iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Ká sọ pé bàbá kan fẹ́ kọ́ ọmọ rẹ̀ ní mọ́tò wíwà. Nígbà tọ́mọ náà ṣì kéré, ṣe lá máa wo bí bàbá rẹ̀ ṣe ń wa mọ́tò. Bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, bàbá náà á máa ṣàlàyé béèyàn ṣe ń wa mọ́tò fún un. Tọ́mọ náà bá ti dàgbà tó ẹni tí òfin gbà láyè láti wa mọ́tò, á bẹ̀rẹ̀ sí í wa mọ́tò, bàbá náà á sì tún máa tọ́ ọmọ náà sọ́nà. Lẹ́yìn náà, bàbá yìí lè pinnu pé òun àtọmọ òun á jọ máa pín mọ́tò náà wà, àmọ́ bọ́jọ́ ogbó ṣe ń dé sí bàbá náà, ó lè jẹ́ pé ọmọ rẹ̀ láá máa wa bàbá náà lọ síbi tí bàbá náà bá fẹ́ lọ. Ó  dájú pé inú bàbá náà máa dùn pé ọmọ òun lè wa mọ́tò, kò sì ní máa ronú pé òun lòun gbọ́dọ̀ máa wa mọ́tò náà ṣáá. Bákan náà ni orí àwọn àgbàlagbà máa ń wú bí wọ́n ṣe ń rí i táwọn tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń bójú tó onírúurú iṣẹ́ nínú ètò Ọlọ́run.

10. Báwo ló ṣe rí lára Mósè nígbà tí Ọlọ́run fún àwọn míì nírú ẹ̀bùn tó ní?

10 Àmọ́ o, àwọn àgbàlagbà gbọ́dọ̀ kíyè sára kí wọ́n má ṣe máa jowú. Ṣé a rántí ohun tí Mósè ṣe nígbà táwọn kan ń ṣe bíi wòlíì nínú ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Ka Númérì 11:24-29.) Jóṣúà tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Mósè fẹ́ kí Mósè dá àwọn èèyàn náà lẹ́kun. Ó ronú pé wọ́n máa gba iyì Mósè mọ́ ọ lọ́wọ́. Àmọ́ Mósè dáhùn pé: “Ṣé o ń jowú fún mi ni? Rárá, ì bá wù mí kí gbogbo àwọn ènìyàn Jèhófà jẹ́ wòlíì, nítorí pé Jèhófà yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ sára wọn!” Mósè mọ̀ pé Jèhófà ló ń darí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Torí pé Mósè kò wá ògo fún ara rẹ̀, ó sọ fún Jóṣúà pé inú òun á dùn tí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá nírú ẹ̀bùn tí Jèhófà fún òun. Á dáa kí inú tiwa náà máa dùn bíi ti Mósè, pé àwọn míì ń rí iṣẹ́ gbà nínú ètò Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù wá pé kó jẹ́ àwa ni wọ́n gbéṣẹ́ náà fún.

11. Kí ni arákùnrin kan sọ nígbà tí ètò Ọlọ́run ní kó gbéṣẹ́ tó ń ṣe fún ẹlòmíì?

11 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tó wà láàárín wa ló ti ń sìn takuntakun fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọ́n sì ti dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Peter. Ó ti lé lọ́dún mẹ́rìnléláàádọ́rin [74] tó ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó sì lo márùndínlógójì [35] nínú rẹ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan nílẹ̀ Yúróòpù. Ní gbogbo ìgbà yẹn, òun ni alábòójútó Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run ní kí Arákùnrin Paul, tí kò tó o lọ́jọ́ orí máa bójú tó iṣẹ́ náà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táwọn méjèèjì ti jọ ṣiṣẹ́ pọ̀. Nígbà tí wọ́n bi Arákùnrin Peter pé báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ pé ẹlòmíì ló ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ báyìí, ó ní, “Inú mi dùn pé a láwọn arákùnrin tí ètò Ọlọ́run ti dá lẹ́kọ̀ọ́ láti bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì, ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, wọ́n ń ṣe gudugudu méje òun yààyàà mẹ́fà.”

Ó YẸ KÁ MỌYÌ ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN WA

12. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Rèhóbóámù?

12 Lẹ́yìn ikú Sólómọ́nì, Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ ló jọba. Nígbà kan tí Rèhóbóámù fẹ́ bójú tó ọ̀rọ̀ kan, ó pe àwọn àgbààgbà pé kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn. Àmọ́, ṣe ló fọwọ́ rọ́ ìmọ̀ràn náà tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn àwọn ẹmẹ̀wà tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ bíi tiẹ̀ ló tẹ̀ lé. Ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà ò sì dáa rárá. (2 Kíró. 10:6-11, 19) Kí lèyí kọ́ wa? Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà, torí pé wọ́n ní ìrírí tó pọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ káwọn tí wọ́n faṣẹ́ lé lọ́wọ́ rò pé àwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan gẹ́lẹ́ báwọn àgbàlagbà yẹn ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ wọn ò gbọ́dọ̀ fojú kéré ìmọ̀ràn táwọn àgbà bá fún wọn.

13. Báwo làwọn táwọn àgbàlagbà faṣẹ́ lé lọ́wọ́ ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn?

13 Àwọn ìgbà míì wà táwọn tí wọ́n faṣẹ́ lé lọ́wọ́ á máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ táwọn tó ti dàgbà ń ṣe. Ní báyìí táwọn tá a faṣẹ́ lé lọ́wọ́ ti ń ṣe iṣẹ́ tuntun, á bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó ti dàgbà kí wọ́n tó ṣèpinnu. Arákùnrin Paul tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan pé ó gbaṣẹ́ àbójútó lọ́wọ́ Arákùnrin Peter sọ pé: “Mo máa ń lọ bá Arákùnrin Peter pé kó gbà mí nímọ̀ràn, mo sì máa ń rọ àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀.”

14. Kí la rí kọ́ nínú bí Tímótì àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe jọ ṣiṣẹ́?

14 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Tímótì àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi jọ ṣiṣẹ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì kò tó  Pọ́ọ̀lù lọ́jọ́ orí. (Ka Fílípì 2:20-22.) Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: ‘Mò ń rán Tímótì sí yín, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa; yóò sì rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mo gbà ń ṣe nǹkan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń kọ́ni níbi gbogbo nínú gbogbo ìjọ.’ (1 Kọ́r. 4:17) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn gan-an. Pọ́ọ̀lù fara balẹ̀ kọ́ Tímótì ní ‘àwọn ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.’ Ó ṣe kedere pé Tímótì fara balẹ̀ gbẹ̀kọ́ débi pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Tímótì á lè bójú tó ohun táwọn ará Kọ́ríńtì nílò nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fáwọn alàgbà lónìí, báwọn náà ṣe ń dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè múpò iwájú nínú ìjọ!

GBOGBO WA LA NÍ IṢẸ́ LÁTI ṢE

15. Tí ìyípadà tó ń wáyé nínu ètò Ọlọ́run bá kàn wá, báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

15 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń yí pa dà lásìkò wa yìí. Apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà náà ò sì dúró sójú kan, ṣe ló ń gbèrú sí i, ìyẹn sì ń béèrè pé ká yí ọ̀pọ̀ nǹkan pa dà. Bí ìyípadà náà bá sì kàn wá, ẹ jẹ́ ká fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, torí pé ire tiwa kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, kàkà bẹ́ẹ̀ ire Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ ká máa rò. Tá a bá lérò tó tọ́, á jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pín ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara nínú ara kan, ṣùgbọ́n tí gbogbo ẹ̀yà ara náà kò ní ẹ̀yà iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.”Róòmù 12:3-5.

16. Kí làwọn àgbàlagbà, àwọn tí wọ́n faṣẹ́ lé lọ́wọ́ àtàwọn aya lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà nínú ètò Jèhófà?

16 Ìyípadà yòówù kó dé bá wa, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ire Ìjọba Jèhófà lè túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú. Ẹ̀yin àgbàlagbà, ẹ máa dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. Ẹ̀yin arákùnrin tá a faṣẹ́ lé lọ́wọ́, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà tẹ́ ẹ jọ wà. Ẹ̀yin aya, ẹ fara wé Pírísílà tó jẹ́ aya Ákúílà tó máa ń ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣí kiri tí ipò wọn sì ń yí pa dà.Ìṣe 18:2.

17. Kí ló dá Jésù lójú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ṣe, iṣẹ́ wo ló sì fẹ́ kí wọ́n ṣe?

17 Tó bá di pé kéèyàn dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó ojúṣe tó pọ̀ sí i, àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ ni ti Jésù. Ó mọ̀ pé iṣẹ́ tóun wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé máa tó parí, ó sì mọ̀ pé àwọn míì lá máa bá iṣẹ́ náà lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀, Jésù fọkàn tán wọn, ó sì sọ fún wọn pé wọ́n máa ṣe ju iṣẹ́ tóun ṣe lọ. (Jòh. 14:12) Ó fara balẹ̀ dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, wọ́n sì wàásù ìhìn rere náà débi gbogbo táwọn èèyàn ń gbé nígbà yẹn.Kól. 1:23.

18. Kí la máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, kí ló sì yẹ ká máa ṣe báyìí?

18 Lẹ́yìn tí Jésù ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ, Jèhófà jí i dìde sọ́run, ó sì gbé iṣẹ́ tó pọ̀ sí i fún un, ó wá wà nípò tó “ré kọjá gbogbo ìjọba àti ọlá àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa.” (Éfé. 1:19-21) Tá a bá fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà dójú ikú kí Amágẹ́dọ́nì tó dé, Jèhófà máa jí wa dìde sínú ayé tuntun. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló sì máa wà níbẹ̀ fún wa láti ṣe. Àmọ́ ní báyìí ná, iṣẹ́ pàtàkì kan wà tó yẹ kí gbogbo wa máa ṣe, iṣẹ́ náà sì ni pé ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. Torí náà, a rọ gbogbo wa lọ́mọdé lágbà pé ká ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.”1 Kọ́r. 15:58.