Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Jèhófà Ní Lọ́kàn Máa Ṣẹ!

Ohun Tí Jèhófà Ní Lọ́kàn Máa Ṣẹ!

“Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.”​—AÍSÁ. 46:11.

ORIN: 147, 149

1, 2. (a) Kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀? (b) Kí lọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 46:​10, 11 àti 55:11 jẹ́ kó dá wa lójú?

ÀWỌN ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:1) Gbólóhùn yìí kò ṣòro lóye, àmọ́ ó kẹnú torí pé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá pọ̀ gan-an, àwọn nǹkan bí òfuurufú tó tẹ́ rẹrẹ, ìmọ́lẹ̀ àti agbára òòfà. Kódà èyí tá a mọ̀ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá kò ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ lọ. (Oníw. 3:11) Síbẹ̀, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé àti fún aráyé. Ó dá àwa èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní àwòrán ara rẹ̀, ó sì dá ayé lọ́nà táá fi dùn ún gbé fún wa. (Jẹ́n. 1:26) Ó fẹ́ ká jẹ́ ọmọ òun, kóun náà sì jẹ́ Baba wa.

2 Bí Bíbélì ṣe sọ ní orí kẹta ìwé Jẹ́nẹ́sísì, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ ṣèdíwọ́ fún ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn. (Jẹ́n. 3:​1-7) Síbẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lásán, kì í ṣe ohun tí kò lè yanjú torí pé kò sẹ́ni náà tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ ohun tó máa ṣe. (Aísá. 46:​10, 11; 55:11) Torí náà, ó dá wa lójú pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún wa máa ṣẹ lásìkò tó ní lọ́kàn gẹ́lẹ́!

3. (a) Àwọn kókó pàtàkì wo ló ṣe pàtàkì ká mọ̀ tá a bá máa lóye Bíbélì? (b) Kí nìdí tá a fi ń jíròrò nípa wọn báyìí? (d) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

3 Kò sí àní-àní pé a lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tí  Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá àwa èèyàn àti ayé yìí, bẹ́ẹ̀ náà la sì mọ ipa ribiribi tí Jésù Kristi ń kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ó ṣe pàtàkì kéèyàn lóye àwọn kókó yìí, ó sì dájú pé ó wà lára ohun tá a ti kọ́ nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwa náà ní láti jẹ́ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí. Bá a ṣe ń jíròrò àpilẹ̀kọ yìí, ó ṣe kedere pé a ti ń sa gbogbo ipá wa ká lè pe ọ̀pọ̀ èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (Lúùkù 22:​19, 20) Àwọn tó bá wá sí Ìrántí Ikú Kristi máa kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáráyé. Ní báyìí tọ́jọ́ náà kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ó yẹ ká máa ronú àwọn ìbéèrè tá a lè lò láti mú káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ túbọ̀ mọyì ohun tá a fẹ́ ṣe. Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìbéèrè mẹ́ta yìí: Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ayé àti àwa èèyàn? Kí nìdí tí nǹkan kò fi rí bó ṣe fẹ́ báyìí? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìràpadà tí Jésù san ló máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ?

OHUN TÍ JÈHÓFÀ NÍ LỌ́KÀN

4. Báwo làwọn ohun tí Jèhófà dá ṣe ń fògo fún un?

4 Àwọn nǹkan àgbàyanu ni Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa dá. Gbogbo nǹkan tó dá ni ò láfiwé. (Jẹ́n. 1:31; Jer. 10:12) Kí la lè rí kọ́ látinú àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà dá àti bí wọ́n ṣe wà létòlétò? Àwòdami-ẹnu ni gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá, látorí àwọn nǹkan bíńtín dórí àwọn nǹkan gàgàrà, gbogbo wọn ló sì nídìí tí Ọlọ́run fi dá wọn. Ǹjẹ́ kì í yà wá lẹ́nu nígbà tá a bá rí àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ṣe, irú bí ọ̀nà tó gbà dá àwa èèyàn, bí ọmọ jòjòló ṣe máa ń rí àti bójú ọ̀run ṣe máa ń rí tí oòrùn bá ń wọ̀? Àwọn nǹkan yìí máa ń wú wa lórí gan-an torí pé Jèhófà dá wa ká lè mọyì àwọn nǹkan tó lẹ́wà.​—Ka Sáàmù 19:1; 104:24.

5. Kí ni Jèhófà ṣe tó mú káwọn nǹkan tó dá máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀?

5 Ó ṣe kedere pé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá ló ní ààlà ibi tí wọ́n lè dé. Báwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí ṣe lófin tí wọ́n ń tẹ̀ lé bẹ́ẹ̀ làwọn ohun abẹ̀mí náà lófin tí wọ́n ń tẹ̀ lé kí gbogbo nǹkan lè máa lọ létòletò. (Sm. 19:​7-9) Torí náà, gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá láyé àti lọ́run ló ní àyè tiẹ̀, wọ́n sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ dá wọn. Jèhófà fi àwọn ìlànà kan lélẹ̀ táwọn nǹkan tó dá gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, agbára òòfà ló jẹ́ kí òfuurufú wà níbi tó wà látọjọ́ yìí, òun náà ló ń darí òkun tó sì ń mú ká máa gbádùn àwọn nǹkan tó wà láyé. Àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ ló ń darí gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá, títí kan àwa èèyàn. Torí náà, báwọn nǹkan ṣe ń lọ létòletò yìí fi hàn pé Jèhófà lóhun kan lọ́kàn tó fi dá ayé yìí àtàwa èèyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá ń wàásù, á dáa ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Ẹni tó ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu yìí.​—Ìṣí. 4:11.

6, 7. Sọ díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà.

6 Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àwa èèyàn ni pé ká máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́n. 1:28; Sm. 37:29) Àìmọye ẹ̀bùn ni Jèhófà fi jíǹkí Ádámù àti Éfà táá jẹ́ kí wọ́n gbádùn ayé wọn. (Ka Jákọ́bù 1:17.) Jèhófà fún wọn ní òmìnira àti làákàyè, ó sì tún mú kí wọ́n lè fìfẹ́ hàn, kí wọ́n sì gbádùn àjọṣe alárinrin. Ọlọ́run máa ń bá Ádámù sọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kó mọ ohun tóun fẹ́ kó ṣe. Ádámù tún mọ bó ṣe lè bójú tó ara rẹ̀ àti  bó ṣe máa bójú tó àwọn ẹranko àti ilẹ̀ inú ọgbà náà. (Jẹ́n. 2:​15-17, 19, 20) Jèhófà ṣẹ̀dá Ádámù àti Éfà lọ́nà tó jẹ́ pé wọ́n lè gbóòórùn, wọ́n lè ríran, wọ́n lè tọ́ nǹkan wò, wọ́n lè gbọ́ràn, wọ́n sì lè mọ̀ bí ohun kan bá fara kàn wọ́n. Gbogbo nǹkan yìí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n gbádùn Párádísè ẹlẹ́wà tí wọ́n ń gbé. Ádámù àti Éfà láǹfààní àtiṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni, títí ayé ni wọ́n á máa kọ́ ẹ̀kọ́ mọ́ ẹ̀kọ́, tí wọ́n á sì máa ṣàwárí àwọn ohun tuntun.

7 Ohun míì wo ni Ọlọ́run tún ní lọ́kàn? Ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ tó pé pérépéré. Bákan náà ló fẹ́ káwọn ọmọ wọn náà bímọ títí èèyàn á fi kún ayé. Ó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà àtàwọn tó máa di òbí lẹ́yìn wọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn bí Jèhófà náà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn tó kọ́kọ́ dá. Ayé yìí ni Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé títí láé, ká sì máa ṣàmúlò àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀.​—Sm. 115:16.

KÍ NÌDÍ TÍ NǸKAN KÒ FI RÍ BÍ ỌLỌ́RUN ṢE FẸ́ BÁYÌÍ?

8. Kí nìdí tí Jèhófà fi fún Ádámù àti Éfà ní òfin tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:​16, 17?

8 Nígbà tó yá, nǹkan ò rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí. Kí nìdí? Jèhófà fún Ádámù àti Éfà ní òfin kan tó ṣe kedere táá jẹ́ kí wọ́n lè fi hàn bóyá wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn àbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́n. 2:​16, 17) Kò ṣòro fún Ádámù àti Éfà láti lóye òfin yẹn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ni wọ́n lára láti pa á mọ́. Ó ṣe tán, kì í ṣe èso igi yẹn nìkan ló wà nínú ọgbà, igi tí wọ́n lè jẹ èso rẹ̀ pọ̀ gan-an.

9, 10. (a) Ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan Jèhófà? (b) Ìpinnu wo ni Ádámù àti Éfà ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

9 Sátánì Èṣù lo ejò láti mú kí Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:​1-5; Ìṣí. 12:9) Sátánì sọ pé kò yẹ kí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn ò lè jẹ lára èso “gbogbo igi ọgbà”? Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé: ‘A jẹ́ pé ẹ ò lè ṣe ohun tó wù yín nìyẹn.’ Ó wá gbé irọ́ ńlá kan kalẹ̀, pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Ó sì wá bó ṣe máa yí Éfà lọ́kàn pa dà kó bàa rú òfin Ọlọ́run, ó ní: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là.” Sátánì dọ́gbọ́n sọ pé torí Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n rí ọ̀ọ́kán ló ṣe ní kí wọ́n má jẹ èso náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Sátánì gbé wọn gẹṣin aáyán pé wọn “yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”

10 Ọwọ́ Ádámù àti Éfà lọ̀rọ̀ kù sí báyìí. Ṣé ọ̀rọ̀ Jèhófà ni wọ́n á tẹ̀ lé àbí ti ejò? Wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn mú kí wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀. Wọ́n kọ Jèhófà ní Baba, wọ́n sì mú ara wọn kúrò lábẹ́ ààbò àti ìṣọ́ rẹ̀.​—Jẹ́n. 3:​6-13.

11. Kí nìdí tí Jèhófà kò fi gbójú fo ìwà ọ̀tẹ̀ tó wáyé?

11 Bí Ádámù àti Éfà ṣe dìtẹ̀ sí Jèhófà mú kí wọ́n di aláìpé. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí wọ́n di ọ̀tá Ọlọ́run torí pé Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi.” Torí náà, “kò lè gba ohun tí kò tọ́” láyè. (Háb. 1:13; Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ká ní Ọlọ́run gbójú fo ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù,  ó lè ṣèdíwọ́ fún àlááfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láyé àti lọ́run. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, tí Ọlọ́run kò bá ṣe ohunkóhun nípa ọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà Édẹ́nì, àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì ì bá ronú pé bóyá lọ̀rọ̀ Jèhófà ṣeé gbára lé. Àmọ́ ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀, kò sì ní yí i pa dà. (Sm. 119:142) Torí náà, ti pé Ádámù àti Éfà ní òmìnira kò ní kí wọ́n tàpá sí òfin Ọlọ́run. Torí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n kú, wọ́n sì pa dà di erùpẹ̀ tí Ọlọ́run fi dá wọn.​—Jẹ́n. 3:19.

12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù?

12 Nígbà tí Ádámù àti Éfà jẹ èso yẹn, ṣe ni wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn ò sí lára ìdílé Ọlọ́run mọ́. Torí náà, Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, wọn ò sì lè pa dà síbẹ̀ mọ́ láé. (Jẹ́n. 3:​23, 24) Ìyà tó tọ́ sí wọn ni Jèhófà fi jẹ wọ́n yẹn. (Ka Diutarónómì 32:​4, 5.) Torí pé wọ́n ti di aláìpé, wọn ò lè gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ lọ́nà pípé. Yàtọ̀ sí pé Ádámù fi ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ tàfàlà, ó tún sọ àwa àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di aláìpé, ó mú ká máa dẹ́ṣẹ̀ ká sì máa kú. (Róòmù 5:12) Ó mú kó ṣòro fáwa ọmọ rẹ̀ láti wà láàyè títí láé. Bákan náà, kò ṣeé ṣe fún Ádámù àti Éfà láti bí ọmọ pípé, àwa àtọmọdọ́mọ wọn náà ò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí Sátánì Èṣù ti sọ tọkọtaya náà di ọ̀tá Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ sí í tan ọmọ aráyé jẹ títí dòní olónìí.​—Jòh. 8:44.

ÌRÀPADÀ MÚ KÍ ARÁYÉ PA DÀ BÁ ỌLỌ́RUN RẸ́

13. Kí ni Ọlọ́run fẹ́ fún àwa èèyàn?

13 Àmọ́ o, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwa ọmọ èèyàn kò yẹ̀ rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà ṣì fẹ́ kí àárín òun àtàwa èèyàn gún régé. Kò wù ú pé ká máa kú. (2 Pét. 3:9) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn tí Sátánì àtàwọn tọkọtaya náà ṣọ̀tẹ̀ ni Ọlọ́run ṣètò bí aráyé ṣe lè pa dà bá òun rẹ́ láìsí pé ohunkóhun tẹ ìlànà òun lójú. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣe bẹ́ẹ̀?

14. (a) Bó ṣe wà nínú Jòhánù 3:​16, kí ni Jèhófà pèsè láti rà wá pa dà? (b) Ìbéèrè wo la lè bá àwọn tó fìfẹ́ hàn jíròrò?

14 Ka Jòhánù 3:16. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ló mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lórí. Àmọ́ ìbéèrè náà ni pé, Báwo ni ikú Jésù ṣe mú kó ṣeé ṣe fún aráyé láti ní ìyè àìnípẹ̀kun? A máa láǹfààní láti dáhùn ìbéèrè pàtàkì yìí bá a ṣe ń pe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Wọ́n á túbọ̀ lóye ìdáhùn ìbéèrè yẹn tí wọ́n bá wá sí Ìrántí Ikú Kristi àti nígbà tá a bá pa dà lọ bẹ̀ wọ́n wò. Inú àwọn èèyàn á dùn gan-an bí wọ́n bá ṣe túbọ̀ ń lóye pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní ló mú kó pèsè ìràpadà náà, ó sì tún gbé ọgbọ́n rẹ̀ yọ. Àwọn kókó wo nípa ìràpadà la lè bá wọn sọ?

15. Kí ló mú kí Jésù yàtọ̀ sí Ádámù?

15 Jèhófà pèsè ọkùnrin pípé kan tó lè rà wá pa dà. Ọkùnrin náà ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kó sì ṣe tán láti fẹ̀mí rẹ̀ ra aráyé pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:​17-19) Jèhófà wá ta àtaré ẹ̀mí ẹni tó kọ́kọ́ dá ìyẹn Jésù láti ọ̀run wá sáyé. (Jòh. 1:14) Torí náà, Jésù di èèyàn pípé bíi ti Ádámù. Àmọ́ Jésù kò ṣe bíi ti Ádámù ní tiẹ̀, ohun tí Jèhófà retí pé kí ẹni pípé ṣe náà ló ṣe. Kódà nígbà tí Jésù kojú àdánwò tó lágbára, kò dẹ́ṣẹ̀, kò sì rú òfin Ọlọ́run kankan.

16. Kí nìdí tí ìràpadà fi jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye?

16 Torí pé ẹni pípé ni Jésù, ikú rẹ̀ lè gba àwa èèyàn là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹni pípé ni Jésù, ó sì jẹ́ olóòótọ́  sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, ohun tó yẹ kí Ádámù náà ṣe nìyẹn. (1 Tím. 2:6) Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kí ‘ọ̀pọ̀ ènìyàn,’ lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà lè wà láàyè títí láé. (Mát. 20:28) Ó wá ṣe kedere nígbà náà pé ìràpadà tí Jésù san ló máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. (2 Kọ́r. 1:​19, 20) Ìràpadà yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun.

JÈHÓFÀ MÚ KÁ PA DÀ SỌ́DỌ̀ RẸ̀

17. Kí ni ìràpadà mú kó ṣeé ṣe?

17 Kì í ṣe ohun kékeré ló ná Jèhófà láti pèsè ìràpadà náà. (1 Pét. 1:19) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an débi pé ó gbà kí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kú nítorí wa. (1 Jòh. 4:​9, 10) Nípa bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé Jésù ti wá di bàbá wa dípò Ádámù. (1 Kọ́r. 15:45) Yàtọ̀ sí pé Jésù mú ká ní ìyè, ó tún jẹ́ ká pa dà di ara ìdílé Ọlọ́run. Torí ìràpadà tí Jésù san, Jèhófà gba àwa èèyàn pa dà sínú ìdílé rẹ̀ láìfọwọ́ rọ́ ìlànà òdodo rẹ̀ tì. Ẹ wo bó ṣe máa dùn tó nígbà táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bá di pípé! Nígbà yẹn, àwọn tó wà nínú ìdílé Ọlọ́run, láyé àti lọ́run yóò wà níṣọ̀kan. Àá wá di ọmọ Ọlọ́run ní ti gidi.​—Róòmù 8:21.

18. Ìgbà wo ni Jèhófà máa di “ohun gbogbo fún olúkúlùkù”?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ṣọ̀tẹ̀, ìyẹn ò ní kí Jèhófà má nífẹ̀ẹ́ wa mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní káwa èèyàn má jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. Jèhófà máa lo ẹbọ ìràpadà náà láti mú kí gbogbo àwa tá a jẹ́ ọmọ rẹ̀ di pípé. Ẹ wo bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo àwọn tó “rí Ọmọ tí ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀” bá ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 6:40) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, á lo ọgbọ́n rẹ̀ láti mú kí aráyé di pípé, ìyẹn sì lohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀. Nígbà yẹn, Jèhófà Baba wa máa di “ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”​—1 Kọ́r. 15:28.

19. (a) Tá a bá mọyì ìràpadà, kí la máa ṣe? (Wo àpótí náà, “ Ẹ Jẹ́ Ká Máa Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn.”) (b) Kí la tún máa jíròrò nípa ìràpadà nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

19 Tá a bá mọyì ìràpadà, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú káwọn míì jàǹfààní ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run fún wa yìí. Ó yẹ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìràpadà ni Jèhófà fìfẹ́ pèsè kí aráyé lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, àǹfààní tí ìràpadà náà ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jíròrò bí ẹbọ ìràpadà Jésù ṣe yanjú àwọn ọ̀ràn kan tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì.