JUNE 22-28, 2026
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
Máa Tu Àwọn Èèyàn Nínú Bíi ti Jèhófà “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
“Kí a lè fi ìtùnú tí a gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ tu àwọn míì nínú.”—2 KỌ́R. 1:4.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí bí Jèhófà ṣe ń tu àwọn èèyàn nínú àti báwọn míì ṣe ń fara wé e. Ìyẹn á jẹ́ ká mọ báwa náà ṣe lè tu àwọn èèyàn nínú.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tu àwọn èèyàn nínú?
Nínú ayé yìí, ‘oríṣiríṣi àdánwò ló ń kó ìdààmú bá wa,’ ìdí nìyẹn tá a fi nílò ìtùnú látìgbàdégbà. (1 Pét. 1:6) Bó ṣe jẹ́ pé inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá tù wá nínú, ó yẹ kó máa yá àwa náà lára láti máa tu àwọn míì nínú tí wọ́n bá níṣòro. (Mát. 7:12) Jèhófà “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” ti jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè “tu àwọn míì nínú lábẹ́ àdánwò èyíkéyìí tí wọ́n bá wà.” Torí náà, tá a bá ń “tu ara [wa] nínú,” à ń fara wé Jèhófà nìyẹn. (2 Kọ́r. 1:3, 4; 1 Tẹs. 4:18) Ìdí tá a fi ń tu àwọn ará wa nínú ni pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í kàn ṣe torí pé Bíbélì ní ká ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa (1) àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ìtùnú, (2) bá a ṣe lè tu àwọn èèyàn nínú, àti (3) ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ káwọn míì tù wá nínú.
ÀLÀYÉ TÍ BÍBÉLÌ ṢE NÍPA ÌTÙNÚ
2. Bó ṣe wà nínú Bíbélì, kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìtùnú” lè túmọ̀ sí?
2 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìtùnú” ní ìtumọ̀ tó pọ̀. Ohun tí ẹsẹ Bíbélì kan dá lé ló sì máa ń pinnu ìtumọ̀ tó jẹ́. Ó lè túmọ̀ sí “ìṣírí,” “ìyànjú,” tàbí “pàrọwà.” (Róòmù 12:8; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “encourages” nínú nwtsty-E) Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ní tààràtà ni pé “ká dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnì kan láti ràn án lọ́wọ́.” Ṣe lọ̀rọ̀ yẹn dà bíi ti ẹnì kan tó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ń jìyà kó lè dúró tì í, kó sì ràn án lọ́wọ́. Ọ̀nà yòówù kí ẹni yìí gbà ran ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó níṣòro lọ́wọ́, ó dájú pé ara máa tu ọ̀rẹ́ ẹ̀, ọkàn ẹ̀ á sì balẹ̀.
3. Báwo ni Bánábà ṣe tu àwọn èèyàn nínú, kí la sì lè kọ́ lára ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì. Kristẹni kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù sábà máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ débi pé àwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Bánábà, tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú.” (Ìṣe 4:36) Orúkọ yẹn rò ó débi pé Bíbélì ò pè é lórúkọ àbísọ ẹ̀ mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bánábà fi hàn pé ọmọ ìtùnú lòun lóòótọ́ torí pé ó máa ń ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ tí wọ́n bá níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Sọ́ọ̀lù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn wá sí Jerúsálẹ́mù kó lè pàdé àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù, ṣe ni ẹ̀rù ń ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn torí pé wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Bánábà fọkàn tán Sọ́ọ̀lù, ó sì mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì.—Ìṣe 9:26-28.
Bánábà máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ìyẹn sì mú kí orúkọ ẹ̀ rò ó (Wo ìpínrọ̀ 3)
BÁ A ṢE LÈ TU ÀWỌN ÈÈYÀN NÍNÚ
4. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gba tu àwọn èèyàn nínú? (Róòmù 1:11, 12)
4 Lọ sọ́dọ̀ wọn tó bá ṣeé ṣe. Jèhófà máa ń lo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ láti tu àwọn èèyàn nínú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wòlíì Èlíjà rẹ̀wẹ̀sì, Jèhófà lo áńgẹ́lì kan làti tù ú nínú. (1 Ọba 19:4-7) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa lọ sọ́dọ̀ àwọn ará kó lè fún wọn níṣìírí. (Ka Róòmù 1:11, 12.) Tó o bá lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan láti tù ú nínú, má ṣe máa kánjú. (1 Kọ́r. 16:7) Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò lè lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan láti tù ú nínú, o lè pè é lórí fóònù tàbí kó o kọ lẹ́tà sí i. Yàtọ̀ síyẹn, o lè fi ọ̀rọ̀ tàbí káàdì ránṣẹ́ sí í. Ó dájú pé ìyẹn máa fún ẹni náà lókun. Ìbéèrè náà ni pé, ṣé wàá jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ láti tu àwọn èèyàn nínú?
5. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i láyé, kí ló lè ṣòro fún wa láti ṣe?
5 Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé yìí, ó lè túbọ̀ ṣòro fún wa láti máa lọ sọ́dọ̀ àwọn ará wa ká lè tù wọ́n nínú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, Ónẹ́sífórù tó wá láti Éfésù wá Pọ́ọ̀lù kàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè fi òun náà sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa á. (2 Tím. 1:16-18) Bíi ti Ónẹ́sífórù, àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà náà ń tu àwọn ará tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí nínú. Tí wọ́n bá fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ àwọn ará nílé ẹjọ́, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa wá síbẹ̀ láti dúró tì wọ́n bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá lè mú àwọn náà. Kí la lè ṣe báyìí láti tu àwọn ará wa nínú tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wọn? A lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ àti lóde òní ṣe ń tu ara wọn nínú nígbà ìṣòro tí wọ́n sì ń láyọ̀ láìka inúnibíni sí.
6. Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jèhófà tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Nígbà tí wòlíì Èlíjà rí i pé ẹ̀mí òun wà nínú ewu, ó sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà. Torí pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó fara balẹ̀ gbọ́ bí Èlíjà ṣe ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ ohun tó ń kó wòlíì náà lọ́kàn sókè. Kódà, Jèhófà fi sùúrù tẹ́tí sí i bó ṣe ń tẹnu mọ́ ohun kan náà ṣáá! (1 Ọba 19:9, 10, 14) Ohun tí Jèhófà ṣe fún wòlíì Hábákúkù náà nìyẹn. Ó gba wòlíì náà láyè láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, kódà wòlíì náà sọ ọ́ bíi pé Jèhófà ò ṣe nǹkan kan sí ìwà burúkú tó ń ṣẹlẹ̀. (Háb. 1:2, 3) Bákan náà lónìí, Jèhófà máa ń fara balẹ̀ gbọ́ àdúrà àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ ohun tá a fẹ́ ká tó béèrè. Táwa náà bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ará wa, ṣe là ń fìwà jọ Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká máa “yára láti gbọ́rọ̀” wọn, ká má bínú sì wọn, ká má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu kódà tọ́rọ̀ wọn bá fẹ́ bí wa nínú tàbí tí wọ́n ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá.—Jém. 1:19; Oníw. 7:9.
Tó o bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn ará, ṣe lò ń fìwà jọ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 6)
7. Báwo la ṣe lè fòye mọ ohun tẹ́nì kan fẹ́ tó bá níṣòro?
7 Fòye mọ ohun tẹ́ni náà fẹ́ kó o ṣe fóun. Àwa ò mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà, àmọ́ tá a bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, a lè fòye mọ ohun tá a lè ṣe tó máa mára tù wọ́n. Má ṣe rò pé o ti mọ ohun tẹ́ni náà fẹ́ torí pé o mọ ohun tíwọ máa fẹ́ tó bá jẹ́ pé ìwọ nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. Rántí pé gbogbo wa ò rí bákan náà. Torí náà, má kánjú rárá, fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni náà, kó o sì fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tẹ́ni náà máa fẹ́ kó o ṣe fóun.—Òwe 20:5.
8. Báwo ni Jésù ṣe tu Màtá àti Màríà nínú nígbà tí Lásárù kú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù ṣe kó lè tu Màtá àti Màríà nínú nígbà tí Lásárù arákùnrin wọn kú. Àwọn méjèèjì ni ìbànújẹ́ sorí wọn kodò, àmọ́ bí Jésù ṣe tu ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú yàtọ̀ síra. Nígbà tí Màtá wá bá a, ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ni Jésù bá a sọ, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ dá a lójú pé àwọn òkú máa jíǹde. Àmọ́ nígbà tí Màríà wá bá a tó sì ń sunkún, Jésù ò bá a sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe lòun náà bú sẹ́kún ó sì béèrè ibi tí wọ́n tẹ́ Lásárù sí. (Jòh. 11:20-35) Kí lohun tí Jésù ṣe yìí kọ́ wa? Ohun tá a kọ́ ni pé tá a bá fẹ́ tu àwọn èèyàn nínú, ó yẹ ká fòye mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa fẹ́ ká ṣe dípò kó jẹ́ pé ọ̀nà kan náà la máa gbà tu àwọn tó bá níṣòro nínú.
Tó o bá ń tu àwọn ará nínú, gbìyànjú láti fòye mọ ohun tí wọ́n nílò (Wo ìpínrọ̀ 8) a
9. Báwo la ṣe lè fi Bíbélì tu àwọn èèyàn nínú? (Róòmù 15:4, 5)
9 Máa lo Bíbélì. Tá a bá fi Ìwé Mímọ́ tu ẹnì kan nínú, ìyẹn máa jẹ́ kó nírètí. (Ka Róòmù 15:4, 5.) Ìrètí yìí máa tu ẹni náà nínú á sì jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀. (Àìsá. 40:31) Báwo lo ṣe lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o lè fi tu àwọn èèyàn nínú? Àwọn kan ti kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè lò síbì kan, irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bẹ́ẹ̀ wà lábẹ́ àkòrí náà “Ìtùnú” nínú ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bó o ṣe lè máa fi Bíbélì tu àwọn èèyàn nínu. Ó dájú pé ẹ̀mí Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o lè lò nígbà tó bá yẹ.—Jòh. 14:26.
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tuni lára tá a bá ń gba ẹnì kan níyànjú?
10 Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń tuni lára. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìtùnú” nínú Bíbélì tún lè túmọ̀ sí “ìyànjú” tàbí “pàrọwà.” Láwọn ìgbà míì, ó lè gba pé ká gba ẹni tá a fẹ́ tù nínú níyànjú tàbí ká pàrọwà fún un kó lè tún èrò ẹ̀ ṣe. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀ kọ́rọ̀ ẹ lè tu ẹni náà nínú dípò táá fi múnú bí i. (Òwe 12:18) Jèhófà jẹ́ ká rí bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń bá wòlíì Èlíjà sọ̀rọ̀. Èlíjà rò pé òun nìkan lòun ń sin Jèhófà àti pé láìka gbogbo iṣẹ́ tóun ṣe àwọn èèyàn náà ṣì ń bọ̀rìṣà. Àmọ́ kàkà kí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn àṣìṣe ẹ̀ fún un, ṣe ló fi sùúrù tún èrò ẹ̀ ṣe. (1 Ọba 19:15-18) Ìwọ náà lè tu àwọn ará nínú tó o bá ń ronú kó o tó sọ̀rọ̀, tó o sì ń sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Tó o bá ń sọ àsọyé tàbí dáhùn nípàdé, rí i dájú pé o sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tuni lára, kí ọ̀rọ̀ ẹ sì gbé àwọn ará ró.
11. Kí làwọn tó níṣòro sábà máa ń nílò lọ́pọ̀ ìgbà? (1 Jòhánù 3:18)
11 Ṣe ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Táwọn èèyàn bá níṣòro, yàtọ̀ sí pé ká sọ̀rọ̀ tó máa tù wọ́n lára, ó tún gba pé ká ṣe nǹkan kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka 1 Jòhánù 3:18.) Bí àpẹẹrẹ ìgbà kan wà tí Bánábà ta lára ilẹ̀ tó ní, ó sì kó owó ilẹ̀ náà wá fáwọn àpọ́sítélì kí wọ́n lè fi ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lọ́wọ́. (Ìṣe 4:36, 37) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa lónìí náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí omíyalé ba ilé Arábìnrin Gabriela tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Poland jẹ́, inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an, ọkàn ẹ̀ ò sì balẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ mi làwọn òbí mi ń gbé, ẹ̀rù bà wá gan-an gbogbo nǹkan sì tojú sú wa. Mi ò tiẹ̀ mọ ohun tí mo lè ṣe rárá. Àmọ́ àwọn ará láti àwọn ìjọ tó wà nítòsí ṣe gudugudu méje, wọ́n bá wa tún ilé wa ṣe láàárín ọjọ́ kan péré. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára, ó sì jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn ẹ̀ kí wọ́n lè máa tu àwọn tó níṣòro nínú.
12. Àǹfààní wo làwọn ará wa máa rí tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà ìṣòro?
12 Máa fara da ìṣòro. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Tẹsalọ́níkà pé inú òun dùn, ara sì tu òun, nígbà tóun gbọ́ bí wọ́n ṣe fara da ìṣòro wọn. Ó rí i pé iṣẹ́ tóun ṣe láti wàásù fún wọn kò já sí asán. (1 Tẹs. 3:5-8) Pọ̀ọ́lù gbà pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́ láìka àwọn ìṣòro tóun ní sí, ìyẹn á jẹ́ káwọn ará náà lè fara wé òun títí kan àwọn tí kò rí òun lójúkojú. (Kól. 2:1, 2) Bákan náà, táwọn ará wa bá rí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, á jẹ́ kó dá wọn lójú pé ìṣòro yòówu káwọn náà ní, Jèhófà ò ní dá wọn dá a.
13. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú?
13 Máa ní sùúrù. Nígbà míì, tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá níṣòro tá a sì ṣe ohun kan láti tù ú nínú, ó lè gba àkókó díẹ̀ kó tó túra ká. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé ‘ká máa fún ara wa níṣìírí.’ Ọ̀rọ̀ náà ‘máa fún níṣìírí’ fi hàn pé ohun tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbà gbogbo ni. (1 Tẹs. 5:11) Torí náà tá a bá ń tu àwọn èèyàn nínú, ó ṣe pàtàkì ká máa ní sùúrù. (1 Tẹs. 5:14) Àmọ́ nígbà míì, àwa náà lè nílò ìtùnú. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè ṣe?
OHUN TÓ O LÈ ṢE TÓ O BÁ NÍLÒ ÌTÙNÚ
14-15. Kí ló yẹ ká ṣe tí nǹkan bá tojú sú wa tàbí tọ́kan wa ò balẹ̀?
14 Gbàdúrà sí Jèhófà. Tí nǹkan bá tojú sú ẹ tàbí tọ́kan ẹ ò balẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó tù ẹ́ nínú. (Sm. 94:19) Sọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe fún ẹ, má sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. (Sm. 62:8) Òótọ́ ni pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, kódà kó o tó sọ ọ́ jáde. Àmọ́ tó o bá sọ gbogbo bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún un, ìyẹn á fi hàn pé o nígbàgbọ́ pé ó ń gbọ́ ẹ, ó sì máa dáhùn àdúrà ẹ. Ó dájú pé tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, ó máa dáhùn àdúrà wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Máàkù 11:24) Fílípì 4:6, 7 sọ pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.”
15 Jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tàbí alágbà kan tó o fọkàn tán. Àwọn ará lè tù ẹ́ nínú àmọ́ wọ́n lè má mọ ohun tó o nílò àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ àfi tó o bá sọ fún wọn. (Òwe 14:10) Torí náà, o lè sọ fún wọn pé nǹkan kan wà lọ́kàn ẹ tó o fẹ́ sọ, o sì lè ní kí wọ́n sọ ẹsẹ Bíbélì tàbí àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n ti kà tó sì tù wọ́n nínú fún ẹ.
16. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn ará bá fẹ́ tù ẹ́ nínú, àmọ́ kí ló yẹ ká máa rántí?
16 Ṣe sùúrù, kó o sì máa dárí jini. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lè ṣàṣìṣe nígbà tí wọ́n bá fẹ́ tù ẹ́ nínú. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí wọ́n sọ tàbí ṣe lè dùn ẹ́ gan-an, dípò kó tù ẹ́ lára. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe sùúrù. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Jémíìsì 3:2 sọ pé: “Tí ẹnì kan kì í bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, á jẹ́ pé ẹni pípé ni.” Torí náà, dípò kó o máa wo ohun tí wọ́n ṣe tó dùn ẹ́, máa rántí pé ṣe ni wọ́n fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má gbàgbé ohun tí Bíbélì sọ pé “ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”—Mát. 26:41.
17. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?
17 Gbogbo wa la nílò ìtùnú àti ìṣírí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí. Ìdí ni pé ṣe ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i, àwọn alátakò sì túbọ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa. Ẹ ò rí i pé àkókò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ máa tu ara wa nínú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa tu ara wa nínú.
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Alàgbà kan ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí arákùnrin kan tí ìyàwó ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Nígbà tó yá, alàgbà náà tún lọ sọ́dọ̀ arákùnrin míì tí ìyàwó ẹ̀ ti kú tipẹ́, wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí arábìnrin náà ṣe kó tó kú.

