Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí, Láìka Kùdìẹ̀-Kudiẹ Mi Sí

Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ṣàṣeyọrí, Láìka Kùdìẹ̀-Kudiẹ Mi Sí

NÍGBÀ tí èmi àti ìyàwó mi dé sórílẹ̀- èdè Kòlóńbíà lọ́dún 1985, rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, ńṣe ló sì ń burú sí i. Lásìkò yẹn, ìjọba ń gbógun ti àwọn ẹgbẹ́ tó ń ta oògùn olóró láwọn ìlú tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba tún ń gbógun ti àwọn ẹgbẹ́ kan tó ń gbé lórí òkè torí pé wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Nílùú Medellín tá a ti pa dà ṣiṣẹ́ ìsìn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń gbébọn dání máa ń wà káàkiri àdúgbò. Wọ́n máa ń ta oògùn olóró, wọ́n máa ń fipá gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n á sì sọ fún wọn pé ìyẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n jà wọ́n lólè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn máa ń sanwó fún wọn kí wọ́n lè lọ bá wọn pààyàn. Àmọ́ kò sí ìkankan nínú àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn tó pẹ́ láyé. Ohun tá à ń rí lágbègbè yẹn ṣàjèjì sí wa gan-an, a ò rírú ẹ̀ rí.

Báwo lèmi àti ìyàwó mi tá a wá láti orílẹ̀-èdè Finland, tó wà lápá àríwá ayé ṣe wá dèrò South America? Àwọn nǹkan wo ni mo kọ́ nínú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ látọdún yìí wá? Ẹ jẹ́ n sọ fún yín.

ÌGBÀ TÍ MO WÀ LỌ́DỌ̀Ọ́ NÍ FINLAND

Ọdún 1955 ni wọ́n bí mi, èmi sì ni àbíkẹ́yìn lára àwa ọmọkùnrin mẹ́ta táwọn òbí mi bí. Etíkun tó wà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Finland ni mo gbé dàgbà, ìlú Vantaa ni wọ́n sì ń pe agbègbè yẹn báyìí.

Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí ìyá mi ṣèrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n bí mi. Àmọ́ bàbá mi ò fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò gbà kí ìyá mi máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì jẹ́ kó mú wa lọ sípàdé. Torí náà, tí bàbá wa ò bá sí nílé, ìyá wa máa ń kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì.

Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún méje ni mo ti máa ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́

Àtikékeré ni mo ti máa ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, olùkọ́ mi bínú sí mi gan-an torí pé mi ò jẹ kéèkì kan tí wọ́n máa ń fi ẹ̀jẹ̀ ṣe, tí wọ́n ń pè ní verilättyjä. Ló bá fi ọwọ́ ẹ̀ kan tẹ ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi kí ẹnu mi lè là, ó sì fi ọwọ́ kejì mú fọ́ọ̀kì kó lè fi gbé kéèkì náà sí mi lẹ́nu tipátipá. Mo ṣáà wọ́nà gbá fọ́ọ̀kì náà dà nù lọ́wọ́ ẹ̀.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlá (12), bàbá mi kú. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Àwọn ará fìfẹ́ hàn sí mi gan-an, ìyẹn sì jẹ́ kí n tẹ̀ síwájú. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lójoojúmọ́, mo sì ń fìtara kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, mo ṣèrìbọmi ní August 8, 1969, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14).

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, mo kó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù nílùú Pielavesi, tí kò jìnnà sí àárín orílẹ̀-èdè Finland.

Ìlú Pielavesi ni mo ti pàdé ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sirkka, òun ni mo sì fẹ́ nígbà tó yá. Ohun tó jẹ́ kí n fẹ́ràn Sirkka ni pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Kò wá ipò ńlá tàbí bó ṣe máa dolówó nínú ayé. Ó wu àwa méjèèjì pé ká fi gbogbo okun àti àkókò wa sin Jèhófà, a sì ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí ètò Ọlọ́run bá gbé fún wa. Nígbà tó di March 23, 1974, a ṣègbéyàwó. Dípò ká lọ gbafẹ́ ká sì gbádùn ara wa lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó, a lọ sílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Karttula torí pé wọ́n nílò àwọn oníwàásù níbẹ̀ ju ibi tí mo wà tẹ́lẹ̀ lọ.

Ilé tá a gbé ní Karttula, lórílẹ̀-èdè Finland

JÈHÓFÀ BÓJÚ TÓ WA

Mọ́tò tí ẹ̀gbọ́n mi gbé fún wa

Àtìgbà tá a ti ṣègbéyàwó ni Jèhófà ti ń jẹ́ ká rí i pé tá a bá fi Ìjọba òun sípò àkọ́kọ́, òun máa bójú tó wa. (Mát. 6:33) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a dé Karttula, a ò ní mọ́tò, kẹ̀kẹ́ la fi ń rìnrìn àjò. Àmọ́ tó bá dìgbà òtútù, kì í rọrùn fún wa torí òtútù náà máa ń lágbára gan-an. Torí pé ìpínlẹ̀ tí ìjọ wa ti ń wàásù tóbi gan-an, a nílò mọ́tò. Ṣùgbọ́n, a ò lówó tá a lè fi rà á.

Lọ́jọ́ kan, ṣàdédé ni ẹ̀gbọ́n mi wá kí wa. Nígbà tó rí i pé a ò ní mọ́tò, ló bá gbé mọ́tò ẹ̀ fún wa. Ó ti sanwó ìbánigbófò mọ́tò náà. Epo nìkan làá kàn máa rà sínú ẹ̀. Bá a ṣe ní mọ́tò tá à ń gbé kiri nìyẹn.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń bójú tó wa torí ohun tó ṣèlérí pé òun máa ṣe nìyẹn. Tiwa kàn ni pé ká fi Ìjọba ẹ̀ sípò àkọ́kọ́.

ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍLÍÁDÌ

Àwọn tá a jọ wà ní kíláàsì Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà lọ́dún 1978

Lọ́dún 1978, nígbà tá a wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà, Arákùnrin Raimo Kuokkanen a tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa gbà wá níyànjú pé ká gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Torí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ká lè kúnjú ìwọ̀n láti lọ sílé ẹ̀kọ́ yẹn. Àmọ́ lọ́dún 1980, kó tó di pé a gba fọ́ọ̀mù ilé ẹ̀kọ́ náà, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Finland. Nígbà yẹn, ètò Ọlọ́run ò tíì fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àmọ́, a ṣe tán láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà níbikíbi tó bá fẹ́, kì í ṣe ibi tó bá wù wá. Torí náà, a gbà láti lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Síbẹ̀, a ṣì ń kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì torí a ò lè sọ, a lè gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́jọ́ kan.

Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì lè gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la gba fọ́ọ̀mù náà tá a sì kọ̀rọ̀ sínú ẹ̀, àmọ́ kì í ṣe torí pé a ò láyọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì la fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ sìn níbikíbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù sí i, tí ètò Ọlọ́run bá rí i pé a kúnjú ìwọ̀n. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, a sì kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rin (79) ní September 1985. Lẹ́yìn tá a yege, orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà ni wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ.

IBI TÁ A TI KỌ́KỌ́ ṢIṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ

Nígbà tá a dé Kòlóńbíà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ni wọ́n ní ká ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún mi níbẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn ọdún kan, mo rí i pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà mọ́. Bí mo ṣe ní kí wọ́n gbé iṣẹ́ míì fún mi nìyẹn, mi ò sì sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ètò Ọlọ́run rí. Ni wọ́n bá ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nílùú Neiva, lágbègbè Huila.

Gbogbo ìgbà ni mo máa ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tí mi ò tíì ṣègbéyàwó, tí mò ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní Finland, mo máa ń wàásù láti àárọ̀ kùtù títí dalẹ́. Ohun kan náà lèmi àti Sirkka ìyàwó mi ń ṣe lẹ́yìn tá a ṣègbéyàwó. Tá a bá lọ wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó jìnnà gan-an, inú mọ́tò wa la máa ń sùn nígbà míì. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká tètè débi tá a ti máa wàásù lọ́jọ́ kejì.

Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì, a tún nírú ìtara tá a ní nígbà tá à ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn ará ń pọ̀ sí i nínú ìjọ tá a wà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ní Kòlóńbíà níwà ọmọlúwàbí, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì moore.

JÈHÓFÀ DÁHÙN ÀDÚRÀ MI LỌ́NÀ TÍ MI Ò LÉRÒ

Àwọn ìlú kan wà tí ò jìnnà sílùú Neiva tá a ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn, kò sì sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bi ara mi pé, ìgbà wo ni wọ́n máa gbọ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? Àmọ́ torí pé ẹgbẹ́ tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba ń jà lágbègbè yẹn, ibẹ̀ ò ṣe é gbé fáwọn tí kì í ṣe ọmọ ìlú náà. Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé, ó kéré tán kó jẹ́ kí ẹnì kan lára ọmọ ìlú náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lérò tèmi, mo gbà pé tẹ́nì kan bá máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ níbẹ̀, àfi kó máa gbé nílùú Neiva. Mo tún gbàdúrà pé lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi, kí Jèhófà jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, kó sì pa dà sí ìlú ẹ̀ kó lè lọ máa wàásù. Àmọ́ mi ò mọ̀ pé bí Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà mi yàtọ̀ pátápátá sóhun tí mo lérò.

Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Fernando González lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìlú Algeciras ló ń gbé, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn ìlú tí kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, Fernando máa ń rìnrìn àjò tó ju àádọ́ta (50) kìlómítà wá sílùú Neiva láti wá ṣiṣẹ́. Ó máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, torí náà kò pẹ́ rárá tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé. Kódà, ó yà mí lẹ́nu pé ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti ń kó àwọn èèyàn jọ nílùú ẹ̀, tó sì máa ń kọ́ wọn lóhun tó kọ́ nínú Bíbélì.

Èmi àti Fernando rèé lọ́dún 1993

Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí Fernando bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣèrìbọmi ní January 1990. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní báyìí tí ọmọ ìlú Algeciras kan ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sì ń gbé ibẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa lè rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ sí agbègbè yẹn. Torí náà, nígbà tó di February 1992, ètò Ọlọ́run dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀.

Àmọ́, ṣé ìlú Algeciras nìkan ni Fernando ti wàásù? Rárá! Lẹ́yìn tó ṣègbéyàwó, òun àti ìyàwó ẹ̀ kó lọ sílùú San Vicente del Caguán, ìyẹn ìlú míì tí kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n fìtara wàásù, ètò Ọlọ́run sì dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tó di ọdún 2002, ètò Ọlọ́run ní kí Fernando máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, òun àti Olga ìyàwó ẹ̀ ṣì ń ṣiṣẹ́ náà títí di báyìí.

Mo kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Ẹ̀kọ́ náà ni pé, tá a bá fẹ́ kí Jèhófà ṣe ohun kan fún wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká gbàdúrà tó ṣe pàtó lórí ọ̀rọ̀ náà torí Jèhófà lágbára láti ṣe ohun tá ò lè ṣe. Ó ṣe tán, iṣẹ́ ẹ̀ là ń ṣe, kì í ṣe tiwa.—Mát. 9:38.

JÈHÓFÀ MÚ KÓ ‘WÙ WÁ LÁTI GBÉ ÌGBÉSẸ̀, Ó SÌ FÚN WA NÍ AGBÁRA LÁTI ṢE É’

Nígbà tó di ọdún 1990, wọ́n ní ká lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Àyíká tá a kọ́kọ́ bẹ̀ wò wà ní ìlú Bogotá tó jẹ́ olú ìlú Kòlóńbíà. Ẹ̀rù bà wá nígbà tá a gba iṣẹ́ yìí, torí èmi àti ìyàwó mi ò ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ kankan. Yàtọ̀ síyẹn, a ò gbé ìlú táwọn èèyàn pọ̀ sí bẹ́yẹn rí. Àmọ́, Jèhófà ṣe ohun tó sọ nínú Fílípì 2:13 pé: “Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára nítorí ìdùnnú rẹ̀, ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.”

Nígbà tó yá, wọ́n rán wa lọ sí àyíká tó wà ní agbègbè Medellín, ìyẹn ìlú tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi. Rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ò tiẹ̀ jọ àwọn tó ń gbẹ́bẹ̀ lójú mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí mò ń kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, làwọn kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn níwájú ilé tá a wà. Ẹ̀rù bà mí gan-an, mo sì fẹ́ sáré dojú bolẹ̀, àmọ́ ńṣe lẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń kàwé lọ ní tiẹ̀. Nígbà tó kàwé tán, ó dìde, ó sì lọ síta. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ó wọlé pẹ̀lú àwọn ọmọ kékeré méjì, ó sì sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ má bínú o, mo ní kí n sáré kó àwọn ọmọ mi wọlé ni.”

Yàtọ̀ sọ́jọ́ yẹn, àwọn ọjọ́ míì wà tí Ọlọ́run kó wa yọ. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan tá à ń wàásù láti ilé dé ilé, ìyàwó mi sáré wá bá mi, ó sì hàn lójú ẹ̀ pé ẹ̀rù ń bà á. Ó sọ pé ẹnì kan yìnbọn sóun. Ohun tó sọ yẹn bà mí lẹ́rù gan-an. Ìgbà tó yá la wá mọ̀ pé ìyàwó mi kọ́ lẹni náà fẹ́ yìnbọn sí, ọkùnrin kan tó gba ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ kọjá ló yìn ín sí.

Nígbà tó yá, rògbòdìyàn tó máa ń ṣẹlẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ bà wá lẹ́rù mọ́. Bá a ṣe ń rí àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìlú náà tí wọ́n ń fara da rògbòdìyàn yẹn àtèyí tó le jù ú lọ, ńṣe nìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lágbára. Torí náà, a gbà pé tí Jèhófà bá lè jẹ́ kí wọ́n fara dà á, á jẹ́ káwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, gbogbo ìgbà la máa ń ṣe ohun táwọn alàgbà bá sọ fún wa, a máa ń yẹra fáwọn nǹkan tó lè pa wá lára, a sì gbà pé Jèhófà máa dáàbò bò wá.

Ká sòótọ́, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ pé kò le tó bá a ṣe rò. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí mo gbọ́ ohùn kan tó dà bíi pé obìnrin méjì ń pariwo mọ́ ara wọn níwájú ìta ilé tí mo ti ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́. Kò wù mí kí n dá sọ́rọ̀ wọn, àmọ́ ẹni tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣáà ní kí n jẹ́ ká lọ síta. Ó yà mí lẹ́nu pé nígbà tá a débẹ̀, ẹyẹ ayékòótọ́ méjì ló ń sín àwọn ará àdúgbò yẹn jẹ.

A GBA ÀWỌN IṢẸ́ TUNTUN, ÀMỌ́ A BÁ ÌṢÒRO PÀDÉ LẸ́NU IṢẸ́ NÁÀ

Lọ́dún 1997, ètò Ọlọ́run ní kí n máa dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. b Inú mi máa ń dùn tí mo bá lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, àmọ́ mi ò rò ó rí pé lọ́jọ́ kan mo lè di ẹni táá máa dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́.

Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run sọ mí di alábòójútó agbègbè. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ pé kò ní sí iṣẹ́ alábòójútó agbègbè mọ́, wọ́n ní kí n máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ó ti lé ní ọgbọ̀n (30) ọdún báyìí tí mo ti ń gbádùn bí mo ṣe ń dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, tí mo sì ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ọ̀pọ̀ ìbùkún ni mo ti rí látìgbà tí mo ti ń ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run ń gbé fún mi. Àmọ́ kò rọrùn rárá torí oríṣiríṣi ìṣòro la bá pàdé. Ẹ jẹ́ kí n sọ díẹ̀ lára ẹ̀ fún yín.

Mo nígboyà, mo sì jẹ́ni tí kì í gbàgbàkugbà. Àwọn ànímọ́ yìí ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo bá àwọn ìṣòro kan pàdé. Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tí mo fọwọ́ tó le jù mú nǹkan nínú ìjọ nígbà tí mo fẹ́ ká ṣe àwọn àtúnṣe kan. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo fọ̀rọ̀ gún àwọn kan lára nínú ìjọ pé kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn, kí wọ́n sì máa fòye báni lò. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, bí mo ṣe sọ̀rọ̀ sí wọn yẹn fi hàn pé èmi gan-an ò fìfẹ́ hàn, mi ò sì fòye bá wọn lò.—Róòmù 7:21-23.

Tí mo bá ń rántí àwọn àṣìṣe tí mo ṣe, ó máa ń jẹ́ kí n rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. (Róòmù 7:24) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n fi iṣẹ́ míṣọ́nnárì sílẹ̀, kí n sì pa dà sí Finland. Àmọ́ nígbà tí mo lọ sípàdé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, ohun tí mo gbọ́ jẹ́ kí n pinnu pé mi ò ní fi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí mò ń ṣe sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ṣàtúnṣe àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí mo ní. Títí dòní, mo máa ń rántí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà mi torí ó jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n máa ṣiṣẹ́ náà nìṣó, ìyẹn sì wú mi lórí gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fìfẹ́ ràn mí lọ́wọ́ kí n lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí mo ní.

MO MỌ̀ DÁJÚ PÉ Ọ̀LA Ń BỌ̀ WÁ DÁA

Èmi àti Sirkka ìyàwó mi dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká láǹfààní láti fi ayé wa sin òun lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Mo tún dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi ní aya rere tá a jọ ń sìn ín láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Láìpẹ́, màá pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, torí náà mi ò ní láǹfààní láti dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ mọ́ nílé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, mi ò sì ní lè ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká mọ́. Àmọ́, ìyẹn ò mú kí n banú jẹ́. Kí nìdí tí mi ò fi banú jẹ́? Torí mo mọ̀ dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa gan-an tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa bá a ṣe ń sìn ín, tá à ń yìn ín tọkàntọkàn torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tá a sì mọyì àwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa. (Míkà 6:8; Máàkù 12:32-34) Torí náà, kò pọn dandan ká láǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ká tó lè múnú Jèhófà dùn.

Tí mo bá ń rántí àwọn iṣẹ́ tí mo ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mo máa ń rí i pé kì í ṣe pé mo sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ tàbí pé mo ní ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni mo ṣe láwọn àǹfààní yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí mi ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Òótọ́ ni pé mo láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, síbẹ̀ Jèhófà ò wòyẹn. Mo sì mọ̀ pé òun ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ náà láṣeyọrí. Torí náà, mo ti rí i pé Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ẹ̀ láṣeyọrí, láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wa sí.—2 Kọ́r. 12:9.

a Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Raimo Kuokkanen wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2006. Àkòrí ẹ̀ ni: “A Pinnu Láti Sin Jèhófà.”

b Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run là ń pè é báyìí.