OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ọkàn

Ọkàn

Oríṣiríṣi nǹkan làwọn ẹ̀sìn máa ń sọ nípa ọkàn àti ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá kú. Àmọ́, Bíbélì ṣe àlàyé tó ṣe kedere lórí kókó yìí.

Ṣé ọkàn kì í kú?

OHUN TÁWỌN ÈÈYÀN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọkàn kì í kú. Àwọn kan gbà pé ńṣe ni wọ́n máa ń tún ọkàn bí, á sì gbé ara míì wọ̀ lẹ́yìn tí ara ti tẹ́lẹ̀ bá ti kú. Àwọn míì gbà pé, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ọkàn náà á wá lọ sí ilẹ̀ àìrí, yálà ọrùn tàbí ọrùn àpáàdì.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kò sọ pé ọkàn kì í kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, léraléra ni Bíbélì sọ pé ọkàn máa ń kú. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì sọ pé, ọkàn tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ máa kú. Ibì kan tiẹ̀ wà tí Bíbélì ti pé òkú èèyàn ní “òkú ọkàn.” (Léfítíkù 21:11) Ó ṣe kedere pé Bíbélì kò kọ́ni pé ọkàn kì í kú.

“Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ òun gan-an ni yóò kú.”Ìsíkíẹ́lì 18:20.

Ṣé ọkàn àti ara yàtọ̀ sí ara wọn?

OHUN TÁWỌN ÈÈYÀN SỌ

Àwọn kan gbà pé, ọkàn máa ń gbé inú èèyàn tí ẹni náà bá wà láàyè. Àmọ́ tí ẹni yẹn bá kú, ọkàn yóò jáde kúrò lára rẹ̀.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ pé obìnrin kan bí “ọkàn,” ìyẹn odindi èèyàn, tó wà láàyè, tó sì ń mí. (Jẹ́nẹ́sísì 46:18) Kódà, ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí ọkàn nínú Bíbélì tún lè túmọ̀ sí “ẹni tó ń mí.” Nígbà míì, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn ẹranko pàápàá. Láfikún sí i, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọkàn tó fẹ́ jẹun. (Diutarónómì 12:20) Tó bá jẹ́ pé ọkàn yàtọ̀ sí ara, ṣé á máa mí táá sì tún máa jẹun? Ohun tí “ọkàn” túmọ̀ sí nínú Bíbélì ni ẹ̀dá alààyè kan, títí kan ara rẹ̀, ìmọ̀lára rẹ̀ àti irú ẹni tó jẹ́.

“Ó bí . . . ọkàn mẹ́rìndínlógún.Jẹ́nẹ́sísì 46:18.

Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn lẹ́yìn ikú?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ ni kedere pé, tí èèyàn bá kú ara rẹ̀ ti ṣègbé, “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [ìyẹn Sàréè].” (Oníwàásù 9:10) Ìwé Mímọ́ là á mọ́lẹ̀ pé bí èèyàn bá kú, “ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:4) Ọkàn tó bá ti kú kò mọ nǹkan kan rárá, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi máa ń sọ pé ńṣe ni ikú dà bí ìgbà tí èèyàn ń “sùn.”—Mátíù 9:24.

KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?

Tí èèyàn wa bá kú, àwọn ìbéèrè kan wà tó máa ń jẹ wá lọ́kàn, irú bí: Ibo ni wọ́n wà? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ṣé wọ́n ń jìyà ni? Bíbélì fi dá wa lójú pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan, torí náà ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn èèyàn wa tó ti kú kò jìyà níbikíbi. Jèhófà tún ṣèlérí pé láìpẹ́ òun máa jí àwọn ọkàn tó ti kú dìde, èyí sì máa ń tù wá nínú.—Aísáyà 26:19.

‘Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.’Oníwàásù 9:5.