Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Ara Wa Ṣe Ń Mú Kí Egbò Jiná

Bí Ara Wa Ṣe Ń Mú Kí Egbò Jiná

BÍ EGBÒ ṣe máa ń jiná wà lára ohun tó mú kí àwa èèyàn wà láàyè. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ téèyàn bá fara pa ni ara wa ti máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kó lè mú kí ojú egbò náà jiná.

Rò ó wò ná: Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó díjú làwọn sẹ́ẹ̀lì máa ṣe kí egbò kan tó lè jiná:

  • Àwọn sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀ máa lẹ̀ mọ́ àgbájọ àwọn sẹ́ẹ̀lì tó yí ojú egbò náà ká, èyí máa mú kí ẹ̀jẹ̀ tó wà níbẹ̀ dì, á sì dí iṣan tí ẹ̀jẹ́ ń gbà kọjá kí ẹ̀jẹ̀ tó ń tú jáde lè dáwọ́ dúró.

  • Kí àwọn ìdọ̀tí tó wọnú ara nígbà téèyàn fara pa lè jáde, ojú egbò náà á pọ́n, á sì wú. Èyí sì tún máa ń dènà àwọn kòkòrò àrùn tó bá fẹ́ wọlé.

  • Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì míì máa bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́pò àwọn sẹ́ẹ̀lì tó bà jẹ́, ojú egbò náà á bẹ̀rẹ̀ sí í pa dé, àwọn iṣan tí ẹ̀jẹ̀ ń gbà sì máa jiná.

  • Lẹ́yìn náà, àwọn sẹ́ẹ̀lì kan máa bo ojú egbò náà, ojú ọgbẹ́ náà á wá jiná.

Àwọn olùṣèwádìí ronú lórí bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń dì kí ojú egbò lè jiná, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ike kan. Tí apá kan lára ike náà bá fọ́, ńṣe lojú ibẹ̀ máa dí pa dà fúnra rẹ̀. Wọ́n fi àwọn túùbù tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n rọ oríṣi kẹ́míkà méjì sí sára àwọn ike náà. Tí ike náà bá fọ́ àwọn kẹ́míkà yìí máa ṣàn jáde. Táwọn kẹ́míkà náà bá wá pò pọ̀, ó máa gan mọ́ ojú ibi tí ike náà ti fọ́. Àwọn kẹ́míkà yìí máa bẹ̀rẹ̀ sí í yi títí tó fi máa le bí ike náà. Olùṣèwádìí kan sọ pé, àwọn fẹ́ wo àpẹẹrẹ bí ojú egbò nǹkan ẹlẹ́mìí ṣe máa ń jiná fúnra wọn láti fi ṣe nǹkan aláìlẹ́mìí táá máa ṣàtúnṣe ojú àpá rẹ̀.

Kí lèrò rẹ? Ṣé ara tó ń mú kí egbò jiná fúnra rẹ̀ kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?