Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Awọ Aláǹgbá Thorny Devil Ṣe Ń Fa Omi Mu

Bí Awọ Aláǹgbá Thorny Devil Ṣe Ń Fa Omi Mu

AWỌ aláǹgbá thorny devil (Moloch horridus) tó wọ́pọ̀ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà máa ń fa omi mu látinú ìrì, ọ̀rinrin àti ilẹ̀ tí ìrì sẹ̀ sí. Omi yẹn á wá ṣàn wá sí ẹnu rẹ̀ kó lè mu ún. Báwo ló ṣe ń ṣe é? Ó lè jẹ́ ọ̀nà àrà tí awọ ara rẹ̀ ń gbà ṣiṣẹ́ ló mú kí èyí ṣeé ṣe.

Àwọn ihò tóóró tó wà lára awọ aláǹgbá yìí tún so kọ́ àwọn ihò tóóró míì tó wà nínú awọ rẹ̀ kí omi lè ṣàn lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu rẹ̀

Rò ó wò ná: Ìpẹ́ ló kún ara aláǹgbá yìí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé tí ìrì bá ti sẹ̀ sára aláǹgbá yìí, omi ìrì náà máa ṣàn gba awọ ara rẹ̀ tó rí gbágungbàgun. Omi yìí á wá ṣàn wọ inú àwọn ihò tóóró tó wà láàárín ìpẹ́ ara rẹ̀. Ńṣe ni àwọn ihò yìí so kọ́ra, wọ́n sì lọ parí sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu aláǹgbá náà.

A mọ̀ pé agbára òòfà máa ń fa ohun tó wà lókè sísàlẹ̀, ṣùgbọ́n báwo ni aláǹgbá yìí ṣe ń ṣe é tí omi tó gba ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ara rẹ̀ wọlé fi ń gòkè lọ sí ẹnu rẹ̀? Báwo sì ni aláǹgbá yìí ṣe ń fi ikùn rẹ̀ fa omi tó wà lórí ilẹ̀ tí ìrì ti sẹ̀ sí?

Àwọn olùṣèwádìí ti ṣàwárí bí aláǹgbá yìí ṣe ń ṣe é. Àwọn ihò tóóró tó wà lára awọ aláǹgbá yìí tún so kọ́ àwọn ihò tóóró míì tó wà nínú awọ rẹ̀. Bí àwọn ihò tóóró yìí ṣe tò mú kó ṣeé ṣe fún ara aláǹgbá yìí láti fa omi láti ìsàlẹ̀ wá sókè láìka bí agbára òòfà ṣe ń fa nǹkan wálẹ̀. Ńṣe ni ara aláǹgbá yìí dá bíi fóòmù tó ń fa omi mu.

Janine Benyus tó jẹ́ ààrẹ àjọ Biomimicry Institute sọ pé, tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára bí awọ aláǹgbá yìí ṣe ń fa omi mu, àá lè ṣe àwọn ẹ̀rọ tí á máa fa omi ìrì àti ọ̀rinrin. Èyí máa dín ooru kù, á sì tún máa pèsè omi tó ṣe é mu.

Kí Lèrò Rẹ? Ṣé awọ aláǹgbá thorny devil tó ń fa omi mu kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?