Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ O LÈ PINNU BÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ ṢE MÁA RÍ?

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro: Ojúṣe Tó Ń Wọni Lọ́rùn

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro: Ojúṣe Tó Ń Wọni Lọ́rùn

O FẸ́ gbọ́ tàwọn ọmọ rẹ, lẹ́sẹ̀ kan náà, ọkọ rẹ ń pè ọ́. Ọ̀gá rẹ ti ń retí rẹ níbi iṣẹ́, o sì tún fẹ́ lọ wo ìyá rẹ tó ń ṣàìsàn. Kì í ṣe bó o ṣe fẹ́ kí nǹkan rí fún ẹ nìyí, síbẹ̀ ohun tí ò ń bá yí lójoojúmọ́ nìyẹn. O lè máa ronú pé: “Kò sóhun tí mo lè ṣe sí i, mi ò ṣáà lè yẹ ojúṣe mi sílẹ̀!” Tó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá fẹ́ lo fẹ́ ṣe, o lè dá ara rẹ lágara, ìyẹn ò sì ní ṣe ìwọ àtàwọn ẹni náà láǹfààní. Ọgbọ́n wo lo lè dá sí ìṣòro yìí?

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: MÓSÈ

Mósè ló ń dá ṣe ìdájọ́ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó ṣeé sẹ kó máa ronú pé ojúṣe òun ni òun ń bójú tó. Àmọ́ bàbá ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Bí o ṣe ń ṣe yìí kò dára. Dájúdájú, agara yóò dá ọ.” Ó wá dábàá pé kí Mósè yan àwọn ọkùnrin tó dáńgájíá tó máa lè ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà, ẹjọ́ tó bá sì ta kókó nìkan ni wọ́n máa gbé wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe Mósè? Bàbá ìyàwó rẹ̀ sọ pé: ‘Ìwọ yóò lè kojú rẹ̀ àti pé gbogbo ènìyàn yìí yóò dé àyè tiwọn fúnra wọn ní àlàáfíà.’​—Ẹ́kísódù 18:​17-23.

OHUN TÍ DELINA ṢE

Bá a ṣe sọ ní àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, Delina ní àrùn dystonia, ìyẹn àrùn inú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kí iṣan ara ṣiṣẹ́ dáadáa. Ó tún ń tọ́jú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara. Delina sọ pé: “Téèyàn ò bá da àníyàn tòní pọ̀ mọ́ ti ọ̀la, tí kò sì fi nǹkan falẹ̀, ìdààmú ọkàn rẹ̀ máa dínkù.” Ó tún sọ pé: “Bí mi ò ṣe fi ọ̀rọ̀ mi pamọ́ ti jẹ́ kí ọkọ mi àtàwọn míì lè ràn mí lọ́wọ́. Bákan náà, mo máa ń wáyè láràárọ̀ láti tún ọgbà wa ṣe, èyí sì máa ń fún mi láyọ̀.”

“Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.”​—Oníwàásù 3:1

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tí ojúṣe rẹ bá ń wọ̀ ẹ́ lọ́rùn, o lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí:

  • Wá ìrànlọ́wọ́ àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ní àwọn ọmọ, á dáa kó o yan iṣẹ́ fún wọn. O tún lè ní kí àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó ń gbé nítòsí ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tó o fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tí iṣẹ́ rẹ bá pọ̀ jù, o lè ní kí ọ̀gá rẹ dín iṣẹ́ rẹ kù. Àmọ́, má ṣe halẹ̀ mọ́ ọn pé wàá fi iṣẹ́ sílẹ̀. O lè ṣàlàyé adúrú nǹkan tó wà lọ́rùn rẹ fún un. Ọ̀gá rẹ lè gba tìẹ rò, kó sì dín iṣẹ́ rẹ kù.

  • Kọ àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀. Ǹjẹ́ èyíkéyìí wà tó o lè ní kí ẹlòmíì bá ẹ ṣe?

  • Kì í ṣe gbogbo àpèjẹ tí wọ́n bá pè ẹ́ sí ló yẹ kó o lọ. Tí o kò bá ráyè tàbí tágbára rẹ kò gbé e, sọ fún ẹni náà pé o kò ní lè wá.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀: Tó o bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan, wàá dá ara rẹ lágara.