Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ O LÈ PINNU BÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ ṢE MÁA RÍ?

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro: Èrò Òdì

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro: Èrò Òdì

ṢÉ INÚ rẹ máa ń bà jẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà tàbí inú máa ń bí ẹ tàbí o máa ń di ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́ sínú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá ẹ débi tó ò fi ní lókun tó pọ̀ tó láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. Kí lo lè ṣe sí i? *

ÀPẸẸRẸ INÚ BÍBÉLÌ: DÁFÍDÌ

Dáfídì Ọba ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ń kó o lọ́kàn sókè, lára ẹ̀ ni àníyàn àti ìbànújẹ́. Àmọ́, kí ló ràn án lọ́wọ́? Ńṣe ni Dáfídì kó gbogbo àníyàn rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́. (1 Sámúẹ́lì 24:​12, 15) Ó tún kọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ sílẹ̀. Ó sì máa ń gbàdúrà láìdabọ̀ torí pé ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. *

OHUN TÍ GREGORY ṢE

Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, Gregory ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìsoríkọ́ tó lékenkà. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni àníyàn máa ń gbà mí lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ.” Kí ni Gregory ṣe sí ìṣòro yìí? Ó sọ pé: “Kí n lè dín àníyàn mi kù, mo jẹ́ kí ìyàwó mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ràn mí lọ́wọ́. Mo tún lọ sọ́dọ̀ dókítà kí n lè mọ̀ sí i nípa ìṣòro mi. Nígbà tí mo ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé àníyàn kò fi bẹ́ẹ̀ gbà mí lọ́kàn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo ti mọ ohun tó ń fà á, mo sì mọ ohun tí mo lè ṣe láti gbé e kúrò lọ́kàn.”

“Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”​—Òwe 17:22

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tí ẹ̀dùn ọkàn bá pọ̀ lápọ̀jù fún ẹ, o lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí:

  • Kọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ sínú ìwé kan.

  • Sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ ẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ.

  • Má ṣe gba èrò òdì láyè. Bí àpẹẹrẹ, tí èrò òdì bá ń wá sí ẹ lọ́kàn, o lè bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ohun tí mò ń rò nípa ara mi yìí rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?’

  • Má ṣe jẹ́ kí àníyàn àti ìbínú gbà ẹ́ lọ́kàn. Má sì máa di àwọn èèyàn sínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní ni kó o máa fọkàn rò. *

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀: Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe ipò tá a wà ló ń fa ẹ̀dùn ọkàn. Ohun tó sábà máa ń fà á ni èrò òdì tá a ní nípa ara wa.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àìlera ló máa ń mú kéèyàn ní èrò òdì, ó sì yẹ kí ẹni tó bá ní irú ìṣòro yìí lọ rí dókítà fún ìtọ́jú tó yẹ. Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ irú ìtọ́jú pàtó tó yẹ kẹ́nì kan gbà. Kálukú ló máa pinnu irú ìtọ́jú tó bá ipò rẹ̀ mu.

^ ìpínrọ̀ 5 Àdúrà tí Dáfídì kọ sílẹ̀ ló pọ̀ jù nínú ìwé Sáàmù tó wà nínú Bíbélì.

^ ìpínrọ̀ 13 Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ pé, ““Bó O Ṣe Lè Borí Àníyàn,” in the July 1, 2015, issue of The Watchtower.