Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ O LÈ PINNU BÍ ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ ṢE MÁA RÍ?

Ṣé O Lè Pinnu Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Máa Rí?

Ṣé O Lè Pinnu Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Máa Rí?

KÁ SÒÓTỌ́, kò sẹ́ni tí kò níṣòro. Àmọ́ ohun tí kò ní jẹ́ kí ìṣòro náà paná ayọ̀ wa ni pé ká fara mọ́ ipò tá a bá ara wa, ká sì máa ṣe ohun tágbára wa ká lábẹ́ ipò yẹn. Ó máa dáa tí a kò bá jẹ́ kí àwọn ìṣòro náà mú wa rẹ̀wẹ̀sì. Nǹkan ayọ̀ ló sì máa jẹ́ tí nǹkan bá sunwọ̀n sí i. Àmọ́ láìpẹ́ ìgbà ọ̀tun máa dé.

Bíbélì ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tá a máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro, tí a sì máa lè pinnu bá a ṣe fẹ́ kí ìgbésí ayé wa rí. Tó bá dìgbà yẹn, a máa lè ṣe gbogbo ohun tọ́kàn wa ń fẹ́. Kò ní sí àjálù kankan tàbí wàhálà ojoojúmọ́ tàbí ẹ̀dùn ọkàn tó máa dí wá lọ́wọ́ àtiṣe ohun tá a fẹ́. (Aísáyà 65:​21, 22) Èyí ni Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn àkókó tí gbogbo wa máa wà ní àlàáfíà.​—1 Tímótì 6:19.

“Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”​—Aísáyà 65:​21, 22.