Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Àmúmọ́ra

Àmúmọ́ra

Ẹni tó bá ní àmúmọ́ra tó sì máa ń dárí jini máa lè bá àwọn míì gbé láìsí wàhálà. Àmọ́, ṣé gbogbo nǹkan ló yẹ ká máa gbà mọ́ra?

Kí ló lè mú ká ní àmúmọ́ra?

BÍ NǸKAN ṢE RÍ LÓNÌÍ

Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí kì í rí ara gba nǹkan sí. Ohun tó sì máa ń fà á ni, ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ẹ̀tanú sí àwọn tó ń ṣe ìsìn mìíràn. Ìwà yìí sì ti gbèèràn kárí ayé.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Irú ìwà yìí gbòde kan nígbà ayé Jésù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà kórìíra ara wọn gan-an. (Jòhánù 4:9) Wọ́n tún máa ń hùwà sí àwọn obìnrin bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù sì máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn mẹ̀kúnnù. (Jòhánù 7:49) Àmọ́, ìwà Jésù Kristi yàtọ̀ sí tiwọn. Àwọn alátakò rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé: “Ọkùnrin yìí fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.” (Lúùkù 15:2) Jésù jẹ́ onínúure, ó ní sùúrù, ó sì rára gba nǹkan sí. Ìdí sì ni pé ó wá sáyé kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kì í ṣe kó lè dá wọn lẹ́jọ́. Ìfẹ́ tí Jésù ní sáwọn èèyàn ló mú kó bá àwọn èèyàn lò lọ́nà bẹ́ẹ̀.​—Jòhánù 3:17; 13:34.

Ìfẹ́ ló máa ń jẹ́ ká lè rí ara gba nǹkan sí, ó sì máa ń jẹ́ ká lè gbójú fo ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ẹlòmíì. Ìwé Kólósè 3:13 sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”

“Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”​1 Pétérù 4:8.

Ṣé gbogbo nǹkan ló yẹ ká gbà mọ́ra?

BÍ NǸKAN ṢE RÍ

Kí nǹkan lè wà létòletò, ìjọba máa ń ṣe àwọn òfin tó máa dènà àwọn ìwà tí kò yẹ ọmọlúàbí.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“[Ìfẹ́] kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu.” (1 Kọ́ríńtì 13:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù rí ara gba nǹkan sí, síbẹ̀ kò gbójú fo àwọn ìwà tí kò tọ́, irú bí àbòsí àtàwọn ìwà burúkú míì. Ńṣe ló bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. (Mátíù 23:13) Ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù kórìíra ìmọ́lẹ̀ [òtítọ́].”​—Jòhánù 3:20.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) Ohun tí òun náà sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tí kì í ṣe Júù, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù fìfẹ́ bá wọn wí. (Gálátíà 2:​11-14) Ó mọ̀ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” torí náà, kò ní fàyè gba kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín àwọn èèyàn Rẹ̀.​—Ìṣe 10:34.

Lónìí, àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ ìwà rere. (Aísáyà 33:22) Fún ìdí yìí, wọn kì í gbójú fo ìwà àìtọ́ nínú ìjọ. Torí pé ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́, wọn kì í fàyè gba ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú ìjọ. Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń tẹ̀ lé àṣẹ Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.”​—1 Kọ́ríńtì 5:​11-13.

“Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú.”​Sáàmù 97:10.

Ṣé Ọlọ́run máa jẹ́ kí ìwà burúkú máa báa nìṣó?

OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́

Ìwà burúkú ò lè kúrò nínú ìṣe wa torí èèyàn léèyàn á máa jẹ́.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Wòlíì Hábákúkù gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n . . . wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ?” (Hábákúkù 1:3) Ọlọ́run fi wòlíì yìí lọ́kan bálẹ̀, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun máa fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú. Ọlọ́run wá sọ pé, ìlérí yìí “yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́!”​—Hábákúkù 2:3.

Ní báyìí ná, Ọlọ́run fún àwọn èèyàn burúkú láǹfààní láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì tún ìwà wọn ṣe. “‘Èmi ha ní inú dídùn rárá sí ikú ẹni burúkú,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘bí kò ṣe pé kí ó yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè ní ti tòótọ́?’” (Ìsíkíẹ́lì 18:23) Àwọn tó bá yíwà pa dà, tí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa láǹfààní láti rí ojúure rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ìwé Òwe 1:33 sọ pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”

“Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​Sáàmù 37:​10, 11.