OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ
Nípa Àyíká
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ayé wa máa ń pèsè oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀, omi tó ṣe é mu àti afẹ́fẹ́ tó tura, síbẹ̀ àwọn èèyàn túbọ̀ ń ba àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wá ń sapá gan-an láti wá ojútùú sí ìṣòro yìí.
ỌSIRÉLÍÀ
Wọ́n fojú bù ú pé alagbalúgbú omi tí kò ní iyọ̀ tó fẹ̀ tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́fà máìlì (500,000 cu km) ló wà nísàlẹ̀ agbami òkun kárí ayé. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Vincent Post láti Yunifásítì Flinders ní ìpínlẹ̀ Adelaide sọ pé “omi òkun kò pọ̀ tó bó ṣe tó lónìí.” Èyí fi hàn pé àwọn etíkun kò kún tó báyìí tẹ́lẹ̀. Nígbà tó yá, omi òjò bẹ̀rẹ̀ sí i “kún àwọn orísun omi, èyí tó wà ní ìsàlẹ̀ òkun lóde òní.” Ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé ni kò láǹfààní láti rí omi tó mọ́. Àmọ́, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní ìrètí pé omi tó wà lábẹ́ òkun yìí máa ṣe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láǹfààní tó bá yá.
AṢÁLẸ̀ SÀHÁRÀ
Ìdajì àwọn ẹranko ńlá tó wà ní aṣálẹ̀ Sàhárà ló ti di àwátì. Ó sì lè jẹ́ pé ìwọ̀nba ibi díẹ̀ ló ṣẹ́ kù tí wọ́n máa ń jẹ̀ sí. Bí nǹkan ṣe ń yí pa dà láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń jẹ̀ àti àwọn ọdẹ tó ń pa àwọn ẹranko yìí wà lára ohun tó fà á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹranko ṣe pọ̀ nínú igbó náà ni ẹranko pọ̀ ní aṣálẹ̀, àwọn olùṣèwádìí sọ pé, “àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò dá sí àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀ torí pé kò sí owó tí ó tó láti fi tọ́jú wọn.” Torí náà, ó ṣòro fún àwọn tó ń bójú tó àyíká láti dáàbò bo àwọn ẹranko yìí.
KÁRÍ AYÉ
Wọ́n fojú bù ú pé afẹ́fẹ́ olóró ló pa ìdá kan nínú mẹ́jọ àwọn tó kú lọ́dún 2012. Àjọ Ìlera Àgbáyé wá sọ pé, “lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, afẹ́fẹ́ olóró ni ìṣòro àyíká tó gba iwájú jù lọ nínú àwọn ìṣòro àyíká tó ń kó bá ìlera wa.”