Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bí Ìfẹ́ Yín Ṣe Lè Jinlẹ̀ Sí I

Bí Ìfẹ́ Yín Ṣe Lè Jinlẹ̀ Sí I

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Lọ́jọ́ ìgbéyàwó yín, o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún ẹni tó o fẹ́. Ìlérí tó o ṣe lọ́jọ́ náà jẹ́ àdéhùn tí o kò gbọ́dọ̀ yẹ̀. O pinnu lọ́jọ́ náà pé wàá dúró ti ẹnì kejì rẹ, o sì máa yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú.

Àmọ́ bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, èdèkòyédè tó ń wáyé ti fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ láàárín yín. Ṣé ìfẹ́ tó o ní fún ẹnì kejì rẹ ò ti máa tutù báyìí?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ńṣe ni àdéhùn dà bí ìdákọ̀ró tó máa jẹ́ kí ìgbéyàwó yín dúró sán-ún

Àdéhùn tó o ṣe kọ́ ni ìṣòro, ojútùú ló jẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí kò gbà pé ó yẹ kéèyàn dúró lórí àdéhùn tó ṣe lọ́jọ́ ìgbéyàwó. Àwọn kan sọ pé ńṣe ni irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ dàbí ìgbà tí wọ́n fi okùn so èèyàn méjì pọ̀ tipátipá. Dípò tí wàá fi ní irú èrò bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa wo àdéhùn tó o ṣe fún ẹnì kejì rẹ bí ohun tó máa mú kí ìgbéyàwó yín fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ìyàwó kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Megan sọ pé: “Tí àìgbọ́ra-ẹni-yé bá wà láàárín tọkọtaya, àdéhùn tẹ́ ẹ ti ṣe fún ara yín, kò ní jẹ́ kó o máa ronú pé kẹ́ ẹ kọ ara yín sílẹ̀.” * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohunkóhun ló lè dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín tọkọtaya, tẹ́ ẹ bá pinnu pé kò sí ohun tó máa yà yín, ó máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè yanjú ìṣòrò náà láàárín ara yín.—Wo àpótí náà “ Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ẹnì Kejì Rẹ.”

Kókó ibẹ̀ ni pé: Tí ìṣòrò bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ, àkókò rèé fún ẹ láti pinnu pé bí iná ń jó bí ìjì ń jà, o kò ní fi ẹnì kejì rẹ sílẹ̀. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ronú nípa ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Òwe kan sọ pé: “Èkùrọ̀ ni alábàákú ẹ̀wà.” Ṣé ọ̀rọ̀ yìí mú kó o ronú pé o ti há, àbí ó mú kó o ronú pé kò séwu? Nígbà tí ìṣòrò bá wáyé láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ, ṣé o kì í ronú pé àbí kí ẹ kúkú kọ ara yín sílẹ̀? Kí ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹnì kejì rẹ lè túbọ̀ wọ̀ dáadáa, ó ṣe pàtàkì kó o pinnu pé kò sóhun tó máa yà yín.—Ìlànà Bíbélì: Mátíù 19:6.

Ronú nípa ìgbésí ayé rẹ àtẹ̀yìnwá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn òbí rẹ lè nípa lórí àjọṣe ìwọ àti ẹnì kejì rẹ. Ìyàwó kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lea sọ pé: “Àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀ nígbà tí mo ṣì wà ní kékeré, ìyẹn sì mú kó máa ṣe mí bí i pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ láàárín èmi àti ọkọ mi.” Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè mú kí ìgbéyàwó rẹ kẹ́sẹ járí ju tàwọn òbí rẹ lọ. Ti pé àwọn òbí rẹ kọ ara wọn sílẹ̀, kò túmọ̀ sí pé ìwọ àti ẹnì kejì rẹ náà máa kọ ara yín sílẹ̀!—Ìlànà Bíbélì: Gálátíà 6:4, 5.

Ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ. Bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín yín, má ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ tó o máa kábàámọ̀. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bí i “Màá kó jáde ńlé fún ẹ!” tàbí “Màá lọ fẹ́ ẹlòmíì!” Irú ọ̀rọ̀ báyìí kì í jẹ́ kí ìṣòrò tán nílẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló máa burú sí i, ìyẹn sì lè tú ìdílé ká. Torí náà, dípò tí wàá fi máa sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé, o lè sọ pé: “Inú ti ń bí àwa méjèèjì báyìí. Àmọ́, kí la lè ṣe láti yanjú ìṣòrò yìí?”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 12:18.

Máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹnì kejì rẹ ló ṣe pàtàkì jù sí ẹ. Gbé fọ́tò ẹnì kejì rẹ sí orí tábìlì rẹ ní ibi iṣẹ́. Ohun tó dáa ní kó o máa sọ nípa ìdílé rẹ fún àwọn ẹlòmíì. Tí o bá rìnrìn àjò, rí i dájú pé ojoojúmọ́ lò ń pe ẹnì kejì rẹ. Nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀, máa lo ọ̀rọ̀ tó máa kó ìwọ àti ẹnì kejì rẹ pọ̀ bí “àwa,” “èmi àtìyàwó mi” tàbí “èmi àtọkọ mi.” Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá tẹ̀ ẹ́ mọ́ ara rẹ àti àwọn míì lọ́kàn pé ẹnì kejì rẹ ló ṣe pàtàkì jù sí ẹ.

Àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ni kó o máa fara wé. Máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tọkọtaya tí wọ́n dúró ti ara wọn nígbà ìṣòro. Bi wọ́n láwọn ìbéèrè bíi, “Kí ló ràn yín lọ́wọ́ tí ìfẹ́ yín ò fi jó rẹ̀yìn?” Bíbélì sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17) Tó o bá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí, wàá jàǹfààní látinú ìrírí àwọn tí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí?

^ ìpínrọ̀ 7 Bíbélì sọ pé tọkọtaya lè kọ ara wọn sílẹ̀ tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣe panṣágà. Wo àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ojú Ìwòye Bíbélì—Panṣágà” nínú ìwé yìí.