Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìwà Ipa

Ìwà Ipa

Láti ọjọ́ táláyé ti dáyé ni àwọn èèyàn ti ń hùwà ipá. Ṣé bí ìwà burúkú yìí yóò ṣe máa bá a lọ rèé?

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìwà ipá?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn tó gba ẹ̀sìn pàápàá, máa ń sọ pé wèrè la fi ń wo wèrè. Bákan náà, wọ́n gbà pé kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn máa wo àwọn fíìmù tó kún fún ìwà ipá.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Àwókù ìlú alágbára kan wà ní ìtòsí ìlú Mosul ní àríwá orílẹ̀-èdè Ìráàkì. Nínéfè lorúkọ ìlú yìí, òun sì ni olú-ìlú ilẹ̀ Ásíríà ìgbàanì. Nígbà tí nǹkan ṣì rọ̀ṣọ̀mù ní ìlú yẹn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa “sọ Nínéfè di ahoro.” (Sefanáyà 2:13) Bíbélì pe ìlú Nínéfè ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀.” Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi sọ nípa rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì gbé ọ kalẹ̀ bí ìran àpéwò.” (Náhúmù 1:1; 3:1, 6) Ìwé Sáàmù 5:6 sọ pé Jèhófà kórìíra “ẹni ìtàjẹ̀sílẹ̀.” Àwókù ìlú Nínéfè jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

Orí Sátánì Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run àti ọ̀tá àwa èèyàn ni ìwà ipá ti bẹ̀rẹ̀. Sátánì yìí kan náà ni Jésù pè ní “apànìyàn.” (Jòhánù 8:44) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá bíi ti Sátánì, wọ́n tiẹ̀ máa ń gbádùn àwọn eré tí ìwà ipá kún inú rẹ̀ fọ́fọ́. Ohun tó sì fà á ni pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ká tó lè múnú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ kórìíra ìwà ipá, ká sì nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́. * Àmọ́, ṣé ìyẹn ṣeé ṣe?

“Jèhófà . . . kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”Sáàmù 11:5.

Ṣé àwọn tó ń hùwà ipá lè yí pa dà?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Wọ́n ní ìwà jàgídíjàgan ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa. Torí náà, kò ṣe é yí pa dà.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ẹ jáwọ́ nínú “ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn.” Ó tún sọ pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:8-10) Ṣé ohun tí Ọlọ́run ń béèrè yìí pọ̀ jù fún wa? Rárá o. Torí pé èèyàn lè yíwà pa dà. * Lọ́nà wo?

Ohun àkọ́kọ́ ni pé kí èèyàn ní ìmọ̀ tòótọ́ nípa Ọlọ́run. (Kólósè 3:10) Tí ẹni tó lọ́kàn tó dáa bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìwà tó ń fani mọ́ra tí Ẹlẹ́dàá wa ní àti àwọn ìlànà rẹ̀, ó máa wu ẹni náà láti sún mọ́ Ọlọ́run kó sì máa ṣe ohun tó fẹ́.—1 Jòhánù 5:3.

Ohun kejì ni pé ká ṣọ́ra fún àwọn tá à ń bá rìn. Bíbélì sọ pé: ‘Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́; má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn. Kí ìwọ má baà kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ á sì gba ìdẹkùn fún ara rẹ.’—Òwe 22:24, 25. BIBELI YORUBA ATỌ́KA.

Ohun kẹta ni pé kí èèyàn máa ronú jinlẹ̀ dáadáa. Tó o bá rò ó dáadáa, wà á rí i pé àìlè-kóra-ẹni-níjàánu ló ń mú kí àwọn èèyàn hùwà ipá. Àmọ́, àwọn tó lẹ́mìí àlàáfíà máa ń kó ara wọn níjàánu. Ìdí nìyẹn tí ìwé Òwe 16:32 fi sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.”

“Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”Hébérù 12:14.

Ǹjẹ́ ìwà ipá lè dópin láé?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Kì í ṣe òní, kì í ṣe àná ni ìwà ipá bẹ̀rẹ̀, bí á sì ṣe máa wà lọ nìyẹn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:10, 11) Fún ìdí yìí, ohun tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn ará Nínéfè ìgbàanì náà ló máa ṣe fún àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá, kó lè dáàbò bo àwọn èèyàn àlááfíà àti àwọn ọlọ́kàn tútù. Lẹ́yìn ìyẹn, a ò tún ní gbúròó ìwà ipá mọ́ títí láé!—Sáàmù 72:7.

‘Àwọn onínú tútù ni yóò jogún ilẹ̀ ayé.’—Mátíù 5:5

Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti máa wá ojú rere Ọlọ́run, kí a sì kọ́ bá a ṣe lè jẹ́ èèyàn àlááfíà. Ìwé 2 Pétérù 3:9 sọ pé: “Jèhófà . . . ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”

“Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.”Aísáyà 2:4.

^ ìpínrọ̀ 7 Ọlọ́run gbà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ máa jagun kí wọ́n lè dáàbò bo ìlú wọn. (2 Kíróníkà 20:15, 17) Àmọ́, gbogbo ìyẹn yí pa dà lẹ́yìn tí Ọlọ́run wọ́gi lé májẹ̀mú tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá, tó sì dá ìjọ Kristẹni tí kò ní ààlà ilẹ̀ sílẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 11 Àpẹẹrẹ àwọn tó ti jáwọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan wà nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́.