Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

SÍPÉÈNÌ

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan gbà pé àfọwọ́fà àwọn èèyàn wà lára ohun tó mú kí ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé lọ́dún 2011 nílùú Lorca, ní gúúsù orílẹ̀-èdè Sípéènì. Àwọn mẹ́sàn-án ló kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn míì fara pa. Àwọn onímọ̀ nípa ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ti rí i pé lára ohun tó fa ìmìtìtì ilẹ̀ tó burú jáì yẹn ni báwọn kan ṣe fa omi púpọ̀ rẹpẹtẹ látinú ilẹ̀ lọ sínú oko tí wọ́n ti ń ṣọ̀gbìn.

ṢÁÍNÀ

Bílíọ̀nù méjìlélọ́gọ́rùn-ún dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn arìnrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè Ṣáínà ná sórí ìrìn-àjò káyé lọ́dún 2012. Àjọ tó ń rí sí ìrìn-àjò afẹ́ lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè sọ pé owó tabua tí wọ́n ná yìí ló mú kí orílẹ̀-èdè Ṣáínà jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ná iye tó pọ̀ jù lọ sórí ìrìn-àjò káyé. Àwọn orílẹ̀-èdè méjì tó tẹ̀ lé e ni Amẹ́ríkà àti Jámánì. Nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn arìnrìn-àjò láti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè méjì yìí ná sórí ìrìn-àjò káyé lọ́dún 2012.

JAPAN

Ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó dá lórí ìṣègùn, ìyẹn British Medical Journal sọ pé, nǹkan bí ọdún mẹ́tàlélógún làwọn kan fi ń ṣọ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́rin [68,000] èèyàn lórílẹ̀-èdè Japan. Àwọn olùṣèwádìí rí i pé ẹ̀mí àwọn obìnrin tí kì í mu sìgá tí wọ́n bí láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1945 fi ọdún mẹ́wàá gùn ju ti àwọn tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún. Ní ti àwọn ọkùnrin tó ń mu sìgá, ọdún mẹ́jọ ni ẹ̀mí wọn fi máa ń kúrú sí tàwọn tí kì í mu sìgá.

MAURITANIA

Ìjọba orílẹ̀-èdè Mauritania ti kéde pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kó láílọ́ọ̀nù wọ̀lú mọ́, ilé iṣẹ́ kankan ò gbọ́dọ̀ ṣe é mọ́, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ lò ó mọ́. Ìdí tí wọ́n fi ṣe òfin yìí ni pé tí àwọn ẹranko àti ẹran omi bá gbé àwọn láílọ́ọ̀nù yìí mì, ó lè ṣekú pa wọ́n. Ìjọba orílẹ̀-èdè náà wá rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa lo àwọn nǹkan tó lè tètè jẹrà, dípò láílọ́ọ̀nù.

KÁRÍ AYÉ

ìjì líle, àkúnya omi tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá míì bá wáyé, àwọn ilé iṣẹ́ ìbánigbófò máa ń ná nǹkan bí àádọ́ta bílíọ̀nù dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́dún kan fún àwọn oníbàárà wọn. Àmọ́, láàárín àkókò kan lẹ́yìn ọdún 1980 ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ pé torí owó ọjà tó ń fò sókè, owó yìí máa ń lé ní ìlọ́po méjì lọ́dún mẹ́wàá-mẹ́wàá.