Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 3 Torí Pé Ọ̀rọ̀ Rẹ Ò Kọjá Àtúnṣe

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 3 Torí Pé Ọ̀rọ̀ Rẹ Ò Kọjá Àtúnṣe

“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—SÁÀMÙ 37:11.

Bíbélì sọ pé ìgbésí ayé “kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Láyé tá a wà yìí, gbogbo èèyàn pátá ló ní ìṣòro kan tàbí òmíràn. Àmọ́ ìbànújẹ́ tó bá àwọn kan kọjá àfẹnusọ, ńṣe ló dà bíi pé òkùnkùn biribiri bo ìgbésí ayé wọn mọ́lẹ̀, kò sì jọ pé nǹkan lè dára fún wọn mọ́ láé. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀, torí Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ ò kọjá àtúnṣe rárá. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rọ̀ gbogbo aráyé pátá ò kọjá àtúnṣe. Bí àpẹẹrẹ:

  • Bíbélì kọ́ wa pé àwọn nǹkan tó dára gan-an wà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wa.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

  • Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa sọ ayé di Párádísè.—Aísáyà 65:21-25.

  • Ó dájú pé ìlérí yẹn máa ṣẹ. Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé:

    “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Ohun tí Bíbélì sọ yìí kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ o. Jèhófà Ọlọ́run ti múra tán láti ṣe é. Ó ní agbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì tún ń wù ú gan-an láti ṣe é. Ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ṣeé gbára lé, á sì jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe tí ayé kò fi ní sú ẹ.”

MÁA RÁNTÍ PÉ: Bí ìmọ̀lára rẹ bá tiẹ̀ dà bí ìgbà tí omi òkun ń ru gùdù tó sì ń bi ọkọ̀ kiri lójú omi, ńṣe ni ìròyìn tó ń fúnni nírètí tó wà nínú Bíbélì dà bí ìdákọ̀ró tó máa mú kí ọkàn rẹ balẹ̀.

OHUN TÓ O LÈ ṢE LÓNÌÍ: Bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè ní ìrètí tó dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. O lè rí wọn ládùúgbò rẹ tàbí kó o wá àwọn ìsọfúnni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ìkànnì wọn, ìyẹn, jw.org. a

a Àbá: Lọ sórí ìkànnì jw.org kó o sì wo abẹ́ ÌTẸ̀JÁDE > ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ. Tó o bá débẹ̀, wá àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìsoríkọ́” tàbí “para ẹni,” kó o lè rí ìrànlọ́wọ́.