Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 1 Torí Pé Nǹkan Máa Ń Yí Pa Dà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 1 Torí Pé Nǹkan Máa Ń Yí Pa Dà

“A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá.”​—2 KỌ́RÍŃTÌ 4:8.

Àwọn kan sọ pé ńṣe ni pípara ẹni dà bí ìgbà tí èèyàn fi orí bíbẹ́ ṣe oògùn orí fífọ́. Tí ìṣòro ńlá kan bá ń bá èèyàn fínra, pàápàá tó dà bíi pé ó ti kọjá agbára onítọ̀hún, ó ṣì lè ní àtúnṣe. Ohun tá a sọ yìí lè má rọrùn láti gbà gbọ́ o, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé nǹkan ṣì lè yí pa dà láìrò tẹ́lẹ̀.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ sọ pé,  “Ìbànújẹ́ Wọn Dayọ̀.”

Ká tiẹ̀ wá sọ pé nǹkan ò tíì yí pa dà, ohun tó dára jù ni pé kó o máa wá ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.”—Mátíù 6:34.

Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣe ẹ́ kò ní àtúnṣe ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àìsàn kan tó lágbára ló ń ṣe ẹ́. Tó bá jẹ́ pé ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kọ ara yín sílẹ̀ tàbí pé èèyàn rẹ kan kú ńkọ́?

Kódà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ohun kan wà tó o lè yí pa dà, ìyẹn ojú tó o fi ń wo ìṣòro náà. Tí o kò bá da ara rẹ láàmú mọ́ lórí àwọn ìṣòro tó kọjá agbára rẹ, wàá lè máa ronú lọ́nà tó tọ́. (Òwe 15:15) Wàá tún kọ́ bó o ṣe lè fara da àwọn ìṣòro náà dípò tí wàá fi máa ronú láti gbẹ̀mí ara rẹ. Kí wá nìyẹn máa yọrí sí? Wàá rí i pé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá nǹkan ṣe sí ìṣòro tó dà bíi pé kò látunṣe rárá.—Jóòbù 2:10.

MÁA RÁNTÍ PÉ: O ò lè gun òkè kan lọ́wọ́ kan, àmọ́ o lè máa gùn ún díẹ̀díẹ̀. O lè ṣe ohun kan náà láti yanjú púpọ̀ jù lọ lára àwọn òkè ìṣòro tó ń bá ẹ fínra.

OHUN TÓ O LÈ ṢE LÓNÌÍ: Sọ ìṣòro rẹ fún ẹnì kan, ì báà jẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí rẹ kan. Ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìṣòro tó ń bá ẹ fínra má bàa mú kó o ṣinú rò.—Òwe 11:14.