Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Rí Bó O Ṣe Rò

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bí Ìgbéyàwó Rẹ Kò Bá Rí Bó O Ṣe Rò

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Kó tó di pé ìwọ àti ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ṣègbéyàwó, ó jọ pé ẹ mọwọ́ ara yín dáadáa. Àmọ́ ní báyìí, o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àṣìṣe lo ṣe bó o ṣe fẹ́ ẹ. Ó wá di pé àjọgbé yín ò fẹ́ rọgbọ mọ́, àfi bí ìgbà tí wọ́n ti ẹ̀yin méjèèjì mọ́nú yàrá ẹ̀wọ̀n kan náà.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o mú kí àjọṣe yín sunwọ̀n sí i. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó lè mú kó o máa ronú pé àṣìṣe lo ṣe bó o ṣe fẹ́ ẹ.

ÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢẸLẸ̀

Àwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ọmọ títọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn àna lè mú kí nǹkan nira fún tọkọtaya. Bákan náà, àwọn ìṣòro kan wà téèyàn ò retí tó lè fayé ni tọkọtaya lára, irú bí ọ̀rọ̀ owó tàbí ìtọ́jú ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an nínú ìdílé.

Ó jọ pé ọ̀rọ̀ yín ò bára mu. Tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà, wọ́n sábà máa gbójú fo àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣègbéyàwó tán ni wọ́n máa ń rí i bí ọ̀rọ̀ wọn ò ṣe bára mu tó láwọn ọ̀nà kan, irú bí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá ara wọn sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ìnáwó àti béèyàn ṣe ń yanjú ìṣòro. Àwọn nǹkan tó jẹ́ pé tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣì ń fẹ́ra sọ́nà, ńṣe ni wọ́n á kàn bínú síra wọn níwọ̀nba, ó ti wá di ohun tí wọn ò lè mú mọ́ra mọ́ báyìí.

Ẹ ò sún mọ́ra mọ́ bíi ti ìgbà kan. Tó bá jẹ́ pé fún àwọn àkókò kan, tọkọtaya kan ti sọ̀rọ̀ tàbí tí wọ́n ti hùwà tí kò dára sí ara wọn tí wọn ò sì yanjú èdèkòyédè àárín wọn, èyí lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jìnnà sí ara wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lójú síta.

Ohun tó o fọkàn sí ti pọ̀ jù. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé èrò tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó ni pé àwọn ti rí ẹnì kan ṣoṣo tí Ọlọ́run yàn mọ́ àwọn. Òótọ́ ni pé irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ń dùn mọ́ni, àmọ́ ó lè wá fa ìbànújẹ́ nígbà tó bá yá. Tí ìṣòro bá wá dé, ìyàlẹ́nu ló máa jẹ́ fún wọn pé ẹni táwọn ronú pé àwọn mọwọ́ ara àwọn gan-an ló ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún àwọn, èyí á wá mú káwọn méjèèjì máa ronú pé àṣìṣe gbáà ni ìgbéyàwó àwọn jẹ́.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Àwọn ìwà tó dára tí ọkọ tàbí aya rẹ ní ni kó o máa wò. Gbìyànjú èyí wò ná: Kọ ìwà mẹ́ta tó dára tí ọkọ tàbí aya rẹ ní. Jẹ́ kí ohun tó o kọ yìí máa wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà gbogbo, o lè kọ ọ́ sẹ́yìn ọ̀kan lára fọ́tò ìgbéyàwó yín tàbí kó o tẹ̀ ẹ́ sínú ẹ̀rọ alágbèéká kan. Máa wo àwọn nǹkan tó o kọ sílẹ̀ yìí nígbà gbogbo, kó lè máa rán ẹ létí ìdí tó o fi fẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìwà tó dára tí ọkọ tàbí aya rẹ ní lo máa ń rò, wàá rí i pé àlàáfíà á jọba nínú ìdílé yín, èyí á sì mú kẹ́ ẹ lè máa fara da kùdìẹ̀-kudiẹ tí kálukú yín ní. —Ìlànà Bíbélì: Róòmù 14:19.

Ẹ ṣètò láti lo àkókò pa pọ̀. Kẹ́ ẹ tó ṣègbéyàwó, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ máa ń ya àwọn àkókò kan sọ́tọ̀ tẹ́ ẹ fi máa ń ṣe àwọn nǹkan kan pa pọ̀. Àkókò tẹ́ ẹ máa ń lò pa pọ̀ nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra sọ́nà gbádùn mọ́ yín gan-an, àmọ́ kì í ṣe pé ó kàn dédé rí bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ máa ń ṣètò rẹ̀. Ẹ ò ṣe ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ báyìí? Ẹ máa ṣètò àkókò tí ẹ̀yin méjèèjì á fi wà pa pọ̀ láti gbádùn ara yín, bí ìgbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra sọ́nà. Èyí á mú kẹ́ ẹ túbọ̀ sún mọ́ ara yín, ẹ ó sì lè jọ kojú àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ tó bá yọjú.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 5:18.

Ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí lára yín. Tí ọkọ tabí aya rẹ bá ti sọ̀rọ̀ kan tàbí tó hùwà kan tó dùn ẹ́, ṣé o lè gbójú fò ó, kó o sì gbàgbé ẹ̀? Tó bá ṣòro fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀, má ṣe bá ọkọ tàbí aya rẹ yan odì, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún un, má sì ṣe jẹ́ kó pẹ́ rárá. Tó bá ṣeé ṣe má ṣe jẹ́ kó di ọjọ́ kejì.—Ìlànà Bíbélì: Éfésù 4:26.

Tí ọkọ tàbí aya rẹ bá ti sọ̀rọ̀ kan tàbí tó hùwà kan tó dùn ẹ́, ṣé o lè gbójú fò ó, kó o sì gbàgbé ẹ̀?

Fòye mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí nǹkan ṣe rí lára rẹ àti ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ń fẹ́. Kò dájú pé ẹnì kankan láàárín ẹ̀yin méjèèjì á fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun ẹnì kejì rẹ̀. O lè mú kí èyí dá ọkọ tàbí aya rẹ lójú tó o bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì ẹ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ti ṣe ohun tó dùn ún. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan pàtó tẹ́ ẹ lè ṣe kẹ́ ẹ má bàa máa ṣẹ ara yín láìmọ̀. Ẹ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Éfésù 4:32.

Má ṣe máa retí ohun tó pọ̀ jù. Bíbélì sọ pé àwọn tó bá ṣègbéyàwó “yóò ní ìpọ́njú.” (1 Kọ́rínǹtì 7:28) Tí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ bá dé, má ṣe torí ìyẹn rò pé àṣìṣe ni ìgbéyàwó yín jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ̀yin méjèèjì jọ ṣiṣẹ́ lórí bẹ́ ẹ ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro yín, kẹ́ ẹ sì “máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Kólósè 3:13.