Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́ Ojú Wo Ló Yẹ Kó O Fi Wo Ìbáwí?

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́ Ojú Wo Ló Yẹ Kó O Fi Wo Ìbáwí?

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Tí ẹnì kan bá bá ẹ wí, ńṣe ni onítọ̀hún ń sọ fún ẹ pé nǹkan kan wà tó ò ń ṣe tí kò dára. Èmi ò sì rí ẹnì kan tó lè sọ pé, ‘Mo fẹ́ràn kí wọ́n máa sọ fún mi pé mò ń ṣe nǹkan tí kò dára.’”—Amy, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. a

Ńṣe ni ọ̀rọ̀ ẹni tó kọ̀ láti gba ìbáwí dà bí ti awakọ̀ òfuurufú tó kọ̀ láti gba ìtọ́ni tí wọ́n ń fún un láti ibi tí wọ́n ti ń darí ìrìn-àjò ọkọ̀ òfuurufú. Ìgbẹ̀yìn ẹ̀ kò ní dáa rárá.

Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti gba ìbáwí tí àwọn òbí, olùkọ́ àtàwọn àgbàlagbà míì bá fún ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Kò sẹ́ni tó kọjá ìbáwí.

“Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”—Jákọ́bù 3:2.

“Kò sóhun ìtìjú nínú pé wọ́n bá èèyàn wí nígbà tó bá ṣe ohun tí kò dára.”—Jessica.

Tí wọ́n bá bá ẹ wí, túmọ̀ sí pé èèyàn burúkú ni ẹ́.

“Ẹni tí Jèhófà b nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.”—Òwe 3:12.

“Tẹ́nì kan bá bá mi wí, mo máa ń ronú nípa bó ṣe máa ṣòro tó fún onítọ̀hún láti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún mi, mo sì tún máa ń ronú pé torí pé onítọ̀hún fẹ́ràn mi gan-an ló ṣe fún mi ní ìmọ̀ràn.”Tamara.

Tó o bá gba ìbáwí, ó máa mú kí ìwà rẹ túbọ̀ dára sí i.

“Ẹ fetí sí ìbáwí kí ẹ sì di ọlọ́gbọ́n.”—Òwe 8:33.

“Tó o bá fẹ́ dàgbà di èèyàn gidi, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa gba ìbáwí. Ó máa jẹ́ kó o mọ irú ojú táwọn èèyàn fi ń wò ẹ́, èyí á sì jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò dára tí ìwọ fúnra rẹ ò tiẹ̀ mọ̀ pé o ní.”—Deanne.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ náà. Tẹ́nì kan bá bá ẹ wí, ó lè kọ́kọ́ bí ẹ nínú. Àmọ́, ńṣe ni kó o fara balẹ̀. Ohun tó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o ronú pé ìwọ lò ń bá ẹnì kan wí lórí ohun kan náà, bóyá àbúrò ẹ kan. Ṣó o wá rí i báyìí pé ó kéré tán, ìdí pàtàkì kan wà tí ìbáwí náà fi pọn dandan? Ní báyìí, wá fi ojú kan náà wo ohun tí ẹni yẹn ń bá ẹ wí lé lórí.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 7:9.

“Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé inú lè bí ẹ gan-an tẹ́nì kan bá bá ẹ wí, débi tí wàá fi gbàgbé pé ńṣe lonítọ̀hún fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìwà ẹ lè dára sí i, kì í ṣe pé ó fẹ́ bà ẹ́ nínú jẹ́.”—Theresa.

Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga mú kó o kọ ìbáwí. Bákan náà, má ṣe jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ nítorí àwọn àtúnṣe tó yẹ kó o ṣe. Tó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, o ò ní kọ ìbáwí, o ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé wọ́n bá ẹ wí. Máa rántí pé: Ó lè jẹ́ pé ìbáwí tó dùn ẹ́ jù lọ ló máa ṣe ẹ́ láǹfààní jù lọ. Tó o bá sì kọ̀ láti gba irú ìbáwí bẹ́ẹ̀, ohun tó máa mú kó o di èèyàn gidi lo sọ nù yẹn.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 16:18.

Ó lè jẹ́ pé ìbáwí tó dùn ẹ́ jù lọ ló máa ṣe ẹ́ láǹfààní jù lọ

“Ohun pàtàkì kan tó ń sọni di èèyàn gidi ni kéèyàn máa gba ìbáwí. Tá a bá kọ̀ tá ò gba ìbáwí tá a sì ṣe bẹ́ẹ̀ dàgbà, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ kì í dáa rárá.”—Lena.

Máa dúpẹ́. Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún ẹ láti gba ìbáwí tẹ́nì kan fún ẹ, ó yẹ kó o ṣì dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ onítọ̀hún lógún gan-an ni, ó sì fẹ́ kó dáa fún ẹ.—Ìlànà Bíbélì: Sáàmù 141:5.

“Tẹ́nì kan bá bá ẹ wí tàbí pé ó tọ́ ẹ sọ́nà, kò sóhun tó máa fi ṣe ẹ́ tó o bá sọ pé ‘O ṣeun,’ ní pàtàkì tó bá jẹ́ pé ìbáwí náà wúlò fún ẹ. Tó o bá tiẹ̀ wá rò pé kò wúlò fún ẹ, ó yẹ kó o ṣì dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún, torí pé kì í ṣe ohun tó rọrùn láti ṣe.”—Carla.

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.