Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Àṣírí Okùn Aláǹtakùn

Àṣírí Okùn Aláǹtakùn

OKÙN tí aláǹtakùn máa ń ta lágbára gan-an débi pé ó lè lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ara ògiri. Ó sì tún lè ta okùn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ lẹ̀ mọ́ ilẹ́ kó lè fà sókè tí ìjẹ kan bá kó sínú rẹ̀. Báwo ni aláǹtakùn ṣe ń ta okùn tó lágbára láti lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ara ògiri, síbẹ̀ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ lẹ̀ mọ́ ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ bákan náà ló gbà ń ta àwọn méjèèjì?

Okùn tí aláǹtakùn ń ta mọ́ ara ògiri

Rò ó wò ná: Bí aláǹtakùn ṣe máa ń ta okùn mọ́ ara ògiri, òrùlé tàbí ara ibòmíì ni pé ó máa hun okùn náà lọ́nà tó díjú débi pé ó máa lágbára láti mú ìjẹ tó fẹ́ fò kọjá tí kò fi ní lè bọ́. Àwọn olùṣewádìí kan ní yunifásítì ìlú Akron, tó wà nípìnlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rí i nínú ìwádìí wọn pé ọ̀nà tí aláǹtakùn máa ń gbà ta àwọn okùn tó ta mọ́ ilẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe máa ń ta á mọ́ ara ogìri. Awọn okùn tó máa ń ta mọ́ ilẹ̀ kì í pọ̀, èyí sì máa jẹ́ kí okùn náà ṣí kúrò nílẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn kó sì fà lọ sókè níṣẹ̀ẹ́jú akàn ní gbàrà tí ìjẹ kan bá kó sínú okùn náà.

Okùn tí aláǹtakùn ń ta mọ́ ilẹ̀

Ìròyìn tá a gbọ́ láti yunifásítì tó wà nílùú Akron ni pé, àwọn olùṣèwádìí tí wọ́n ṣàwárí ohun àrà yìí “ti ń gbìmọ̀ pọ̀ lórí bí wọ́n ṣe máa lo irú àrà tí aláǹtakùn ń dá yìí láti ṣe gọ́ọ̀mù táá lè máa lẹ nǹkan dáadáa.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń wò ó pé àwọn á lè ṣe gọ́ọ̀mù tó máa ń wà lára aṣọ tí wọ́n fi máa ń di ọgbẹ́, tí wọ́n sì lè fi tọ́jú egungun tó bá dá.

Kí lèrò rẹ? Ǹjẹ́ bí aláǹtakùn ṣe lè ta okùn tó ń lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ara ògiri àtèyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ̀ mọ́ ilẹ̀ kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló dá a?