Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Tata Katydid Ṣe Ń Gbọ́ràn Jọni Lójú Gan-an

Bí Tata Katydid Ṣe Ń Gbọ́ràn Jọni Lójú Gan-an

TATA igbó kan wà tó ń jẹ́ katydid. Etí rẹ̀ kò ju bíńtín lọ, ńṣe làwọn etí ọ̀hún sì ń ṣiṣẹ́ bíi ti èèyàn. Tata yìí lè gbọ́ oríṣiríṣi ìró láti ibi tó jìnnà. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ ìyàtọ̀ láàárín ìró àwọn tata bíi tiẹ̀ àti ohùn gooro àwọn ẹyẹ àdán tó ń dọdẹ ohun tí wọ́n máa jẹ kiri.

Rò ó wò ná: Àwọn etí tata yìí wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì tó wà lọ́wọ́ iwájú. Bí etí tata yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ dà bíi ti èèyàn. Tó bá ti gbọ́ ìró kan, ìró yìí á wọ inú ihò róbótó kan ní etí rẹ̀, èyí tó dà bíi fèrè kan tí afẹ́fẹ́ kún inú rẹ̀. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ rí i nínú ìwádìí wọn pé, ńṣe ni ihò róbótó yìí dà bí èyí tó máa ń wà nínú etí àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú kan, àmọ́ ó kéré gan-an sí tiwọn. Ihò róbótó yìí ni ohun tó ń jẹ́ kí tata katydid máa gbọ́ ìró lọ́nà tó jọni lójú gan-an.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Daniel Robert, ti Yunifásítì Bristol School of Biological Sciences ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé àwárí tí wọ́n ṣe lára tata igbó yìí máa ran àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ lọ́wọ́ láti “ṣe àwọn ẹ̀rọ téèyàn lè fi gbọ́ oríṣiríṣi ìró, èyí tó máa kéré gan-an sí àwọn tó wà báyìí, àmọ́ tó máa jẹ́ èyí tó já fáfá jù lọ.” Àwọn olùṣèwádìí tún gbà pé lẹ́yìnwá ọ̀la, ìwádìí yìí á tún dá kún ìtẹ̀síwájú lágbo àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rọ téèyàn lè fi gbọ́ oríṣiríṣi ìró, títí kan ìtẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbé àwòrán jáde fún ìtọ́jú ní àwọn ilé ìwòsàn.

Kí Lèrò Rẹ? Ǹjẹ́ bí tata katydid yìí ṣe ń gbọ́ ìró lọ́nà tó jọni lójú yìí kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló dá a?