Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Wẹ́rẹ́ Ni Ẹyẹ Albatross Máa Ń Fò

Wẹ́rẹ́ Ni Ẹyẹ Albatross Máa Ń Fò

Àwọn ẹyẹ tó máa ń fo lọ sókè réré lójú òfúrufú lè jẹ́ kí atẹ́gùn máa gbé wọ́n lọ láìlo okun tó pọ̀. Ọ̀kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni ẹyẹ albatross tó máa ń fò káàkiri. Ìyẹ́ apá rẹ̀ lásán gùn tó ẹsẹ̀ bàtà mọ́kànlá, òun fúnra rẹ̀ sì wọ̀n tó kìlógíráàmù mẹ́jọ àtààbọ̀. Ẹyẹ yìí lè fo ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà láìlo okun tó pọ̀. Ohun tó sì jẹ́ kí èyí rọrùn fún un ni ọ̀nà àrà tí ara rẹ̀ ń gbà ṣiṣẹ́ àti ọgbọ́n tó máa ń dá nígbà tó bá ń fò.

Rò ó wò ná: Tí ẹyẹ yìí bá ń fò lọ, ó máa ń na gbogbo ìyẹ́ apá rẹ̀ tán pátápátá, kí àwọn iṣan rẹ̀ lè sinmi. Ohun míì tó tún jẹ́ kí ẹyẹ yìí lè fò fún ọ̀pọ̀ wákàtí ni bó ṣe máa ń lo afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ lórí òkun lọ̀nà àrà.

Tí ẹyẹ albatross bá ń fò lórí òkun, ó lè fò lọ sókè, kó yí pa dà bó ṣe ń fò lọ, kó tún máa já bọ̀ wálẹ̀ ṣòòròṣò tá a sì máa yí sọ́tùn yí sósì, ohun tó ń ṣe yìí máa sọ agbára rẹ̀ dọ̀tun. Àìpẹ́ yìí làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó mọ bí ẹyẹ yìí ṣe lè máa dá irú àrà yẹn. Wọ́n lo àkànṣe ètò orí kọ̀ǹpútà àti àwọn irinṣẹ́ ìgbàlódé tó lágbára gan-an tó lè ta wọ́n lólobó ibi tí ohun tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ wà. Wọ́n wá rí i pé kì í sábà rẹ àwọn ẹyẹ albatross tí wọ́n bá ń fò torí pé wọ́n máa ń jẹ́ kí atẹ́gùn gbé wọn lọ sókè, wọ́n sì mọ ibi tí wọ́n ti lè yí pa dà láìjẹ́ kí atẹ́gùn tún darí wọn mọ́. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé: “Kò sì pé ẹyẹ náà ń janpata rárá láti fò.” Èyí máa jẹ́ kí ẹyẹ náà máa fò lọ fún ọ̀pọ̀ wákàtí lójú òfúrufú láì ju ìyẹ́ apá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo!

Òye táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní nípa ẹyẹ yìí lè ran àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀rọ lọ́wọ́ láti ṣe ọkọ̀ òfuurufú tí kò ní máa lo epo púpọ̀, kódà wọ́n lè fi ṣe ọkọ̀ òfúrufú táá máa fò láìlo ẹ́ńjìnnì.

Kí lèrò rẹ? Ǹjẹ́ bí ẹyẹ albatross ṣe ń fò wẹ́rẹ́ lójú òfuurufú àti ọ̀nà àrà tí ara rẹ̀ gbà ń ṣiṣẹ́ kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?