Yorùbá
Kí Ni Ìwọ Ń Fẹ́ Kó Dáa?
/assets/ct/79e1b14fff/images/syn_placeholder_sqr.png
g 10/12 ojú ìwé 2-3
Kí Ni Ìwọ Ń Fẹ́ Kó Dáa?

Kí Ni Ìwọ Ń Fẹ́ Kó Dáa?

Èwo nínú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ayé yìí ló máa ń dun ìwọ jù?

EBI

ÀÌLÓWÓ LỌ́WỌ́

ÀRÙN

ÌWÀ Ọ̀DARÀN

ÌRẸ́JẸ

OGUN

ÌBÀYÍKÁJẸ́

Ẹ̀TANÚ

Èwo nínú àwọn àyípadà rere yìí ló wu ìwọ jù?

KÍ ÀLÀÁFÍÀ JỌBA LÁÀÁRÍN ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ

KÍ ÈTÒ ÌLERA DÁA, KÓ MÁ SÌ WỌ́N

KÍ Ẹ̀TANÚ DÓPIN

KÍ OÚNJẸ ÀTI OMI MÍMU PỌ̀ DÁADÁA

KÍ ÀÀBÒ TÓ PÉYE WÀ NÍBI GBOGBO

KÍ ÀYÍKÁ MỌ́ TÓNÍTÓNÍ

KÍ ÌWÀ ÌRẸ́JẸ DÓPIN

Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí ṣì máa dáa bó o ṣe fẹ́ kó rí? Àwọn kan lè sọ pé ọwọ́ àwọn ìjọba ló wà. Ǹjẹ́ àwọn ìjọba lè bá wa tún ayé yìí ṣe? Kí làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ti fi hàn?