Mo Ti Wá Mọ Bí Àìṣẹ̀tọ́ Ṣe Máa Dópin
Mo Ti Wá Mọ Bí Àìṣẹ̀tọ́ Ṣe Máa Dópin
Gẹ́gẹ́ bí Ursula Menne ṣe sọ ọ́
Ọjọ́ pẹ́ tó ti máa ń wù mí gan-an pé kí àwọn èèyàn wà láìsí pé wọ́n ń rẹ́ wọn jẹ tàbí kí wọ́n hùwà àìtọ́ sí wọn. Kódà, mo di èrò ẹ̀wọ̀n lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ní Ìlà Oòrùn Jámánì lórí pé mò ń jà fẹ́tọ̀ọ́. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, inú ẹ̀wọ̀n yẹn gan-an ni mo ti wá mọ̀ pé àìṣẹ̀tọ́ máa tó dópin. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀.
ỌDÚN 1922 ni wọ́n bí mi ní ìlú Halle ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ó ti lé ní ẹgbẹ̀fà [1,200] ọdún tí àwọn èèyàn ti ń gbé ìlú yìí. Ìlú Halle yìí wà ní igba [200] kìlómítà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Berlin, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì ti fìdí múlẹ̀ gan-an. Ọdún 1923 ni wọ́n bí Käthe, àbúrò mi obìnrin. Iṣẹ́ ológun ni bàbá mi ń ṣe. Màmá mi máa ń kọrin ní àwọn ilé sinimá.
Bàbá mi ni mo fìwà jọ tó bá dọ̀rọ̀ ká jà fún ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn. Nígbà tó fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, ó ra ṣọ́ọ̀bù kan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé tálákà ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń rajà lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa ń ṣàánú wọn, ó máa ń tajà fún wọn láwìn. Àmọ́, inúure tó ń ṣe fáwọn èèyàn yìí ló mú kí ó kógbá wọlé nígbà tó yá. Ó yẹ kí n ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí bàbá mi yìí pé kò sí béèyàn ṣe lè ja ìjà náà tí ìwà ìrẹ́jẹ àti àìṣẹ̀tọ́ fi máa kásẹ̀ nílẹ̀, torí pé ọ̀rọ̀ náà ju béèyàn ṣe rò lọ. Àmọ́, ẹ̀mí pé nǹkan ṣì máa dára tí mo ní nígbà ọ̀dọ́ kò jẹ́ kí n jáwọ́.
Ọ̀dọ́ ìyá mi ni mo tí kọ́ bí wọ́n ṣe ń dá àwọn èèyàn lárayá, ó kọ́ èmi àti àbúrò mi Käthe bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin, orin kíkọ àti ijó. Àtikékeré ni ara mi ti máa ń yọ̀ mọ́ni, ayé sì dẹrùn fún èmi àti Käthe gan-an ni, àfìgbà tó di ọdún 1939 tí nǹkan yí pa dà bìrí.
Àjálù Dé!
Lẹ́yìn tí mo ti parí ilé ìwé girama, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ijó alájòóyípo, ibẹ̀ sì ni Mary Wigman ti kọ́ mi ní ijó tí wọ́n ń pè ní Ausdruckstanz. Òléwájú ni obìnrin yìí jẹ́ tó bá di ká kọ́ èèyàn ní ijó Ausdruckstanz, ìyẹn ijó táwọn èèyàn fi máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Mo tún máa ń yàwòrán. Mo lè sọ nígbà náà pé mo gbádùn ìgbà kékeré mi dáadáa, mo ṣe àwọn ohun tó múnú mi dùn, mo sì kọ́ oríṣiríṣi nǹkan. Àmọ́, lọ́dún 1939 Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀. Àjálù míì tún ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1941 nígbà tí ikọ́ ẹ̀gbẹ pa bàbá mi.
Nǹkan burúkú gbáà ni ogun jẹ́. Bí mi ò tiẹ̀ jù ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] lọ nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, mo gbà pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Mo rí àìmọye èèyàn tí mo kà sí ọmọlúàbí tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá dẹni tó ń hùwà ẹhànnà lábẹ́ ìjọba Násì. Mo tún rí báwọn èèyàn ṣe ń jìyà, bí wọ́n ṣe ń kú àti bí wọ́n ṣe ń ba dúkìá àwọn èèyàn jẹ́. Bọ́ǹbù ba ilé wa jẹ́ gan-an, àwọn kan lára àwọn ìdílé wa sì bá ogun lọ.
Màmá mi, Käthe àtèmi ṣì wà nílùú Halle nígbà tí ogun náà fi máa parí ní ọdún 1945. Ní gbogbo àkókò tá à ń sọ yìí, mo ti ní ọkọ, a sì ti ní ọmọbìnrin kan, àmọ́ àárín èmi àti ọkọ mi kò
gún. Torí bẹ́ẹ̀, a pínyà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ijó àti àwòrán yíyà ṣe iṣẹ́ kí n lè bójú tó ara mi àti ọmọbìnrin mi.Lẹ́yìn tí ogun parí, wọ́n pín Jámánì sí apá mẹ́rin, apá tí orílẹ̀-èdè Soviet Union ń ṣàkóso sì ni ìlú tí àwa ń gbé bọ́ sí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di dandan kí gbogbo wa máa gbé lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì. Lọ́dún 1949, apá ibi tá a wà tí wọ́n sábà máa ń pè ní orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Jámánì dèyí tí wọ́n wá sọ di ilẹ̀ olómìnira ti Jámánì, ìyẹn German Democratic Republic (GDR).
Ohun Tójú Mi Rí Lábẹ́ Ìjọba Kọ́múníìsì
Láwọn ọdún yẹn, ara màmá mi kò yá, mo sì ní láti máa tọ́jú wọn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì ìjọba ìbílẹ̀. Ọ́fíìsì yìí ni mo wà tí mo pàdé àwọn ọmọléèwé tí kò fara mọ́ èrò ìjọba, tí wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa jẹ́ kí àwọn èèyàn rí àìṣẹ̀tọ́ tí ìjọba ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì kò jẹ́ kí ọ̀dọ́ kan kàwé torí pé bàbá rẹ̀ ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìjọba Násì. Mo mọ ọmọléèwé náà dáadáa torí pé a sábà máa ń kọrin pa pọ̀. Mo ronú pé, ‘Kí nìdí tí wọ́n fi máa fìyà jẹ ẹ́ torí ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe?’ Mo wá túbọ̀ tara bọ ohun tí àwọn tí kò fara mọ́ èrò ìjọba yìí ń ṣe, mo sì pinnu láti máa bá wọn wọ́de. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo lọ lẹ ìwé kan mọ́ ara àtẹ̀gùn tó wà níta ilé ẹjọ́ kan nílùú wa.
Gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé fún ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àlááfíà ìlú, wọ́n ní kí n tẹ àwọn lẹ́tà kan, ohun tó wà nínú lẹ́tà náà tún mú kí ara mi gbọgbẹ́ torí pé mi ò fẹ́ kí wọ́n máa rẹ́ èèyàn jẹ. Nígbà tó tún yá, ìgbìmọ̀ kan náà yìí lo ọgbọ́n òṣèlú fún bàbá àgbàlagbà kan tó ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì. Wọ́n ṣètò láti fi àwọn ìwé tó ń ba ìjọba Kọ́múníìsì lórúkọ jẹ́ ránṣẹ́ sí i kí wọ́n lè kó bá a. Inú bí mi gan-an sí ìwà ìkà tí wọ́n fẹ́ hù sí bàbá náà, torí bẹ́ẹ̀ ṣe ni mo fi lẹ́tà náà pa mọ́ sínú ọ́fíìsì. Bó ṣe di pé mi o fi lẹ́tà náà ránṣẹ́ nìyẹn.
“Ẹni Tó Burú Jù Nínú Ẹ̀wọ̀n” Ló Mú Kí N Nírètí
Ní June 1951, àwọn ọkùnrin méjì kan wá sínú ọ́fíìsì mi, wọ́n sọ pé: “ìjọba ní ká mú ẹ wá.” Wọ́n mú mi lọ sínú ẹ̀wọ̀n tí wọ́n pè ní Roter Ochse, èyí tó túmọ̀ sí Màlúù Pupa. Ọdún kan lẹ́yìn náà, wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń dìtẹ̀ sí ìjọba. Ọmọ iléèwé kan ló tú àṣírí mi fún àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, tí wọ́n ń pè ní Stasi, ó sọ fún wọn nípa ìwé tí mo lẹ̀ mọ́ ìta ilé ẹjọ́. Ńṣe ni wọ́n kàn dá ẹjọ́ náà bó ṣe wù wọ́n torí pé kò sẹ́ni tó ṣe tán àtigbọ́ ohun tí mo ní í sọ láti gbèjà ara mi. Bí wọ́n ṣe jù mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà nìyẹn. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, ara mi kò yá wọ́n sì fi mi sínú yàrá kan nínú ilé ìwòsàn tó wà fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, níbi tí nǹkan bí ogójì [40] àwọn obìnrin míì wà. Nígbà tí mo rí bí ojú àwọn tó wà nínú yàrá náà ṣe le koko, ẹ̀rù bà mí. Mo sá lọ sẹ́nu ìlẹ̀kùn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá ìlẹ̀kùn náà.
Wọ́dà tó wà níbẹ̀ bi mí pé “Kí lo fẹ́?”
Mo bá pariwo pé “Ẹ mú mi kúrò níbí. Ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe lẹ máa fi mi sínú àhámọ́ lémi nìkan, mi ò kọ̀, ẹ ṣáà mú mi kúrò níbí!” Ó kàn ń wò mí ni, kò tiẹ̀ sọ̀rọ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo kíyè sí obìnrin kan tó yàtọ̀ sí àwọn yòókù. Mo rí i lójú rẹ̀ pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Mo wá lọ jókòó tì í.
Ohun tó sọ yà mí lẹ́nu, ó ní: “Tó o bá máa jókòó tì mí, àfi kó o ṣọ́ra o.” Ó tún sọ pé: “Àwọn tó kù gbà pé èmi ni ẹni tó burú jù nínú ẹ̀wọ̀n yìí torí pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Mi ò mọ̀ rárá nígbà yẹn pé ọ̀tá Ìjọba Kọ́múníìsì ni àwọn èèyàn ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí. Àmọ́ ohun tí mo mọ̀ ni pé méjì nínú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí, (ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀) máa ń ṣèbẹ̀wò déédéé sí Bàbá mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Mo tiẹ̀ rántí pé Bàbá mi máa ń sọ pé “Òótọ́ ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ń sọ o!”
Ńṣe ni omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú mi, tí ọkàn mi sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ pé mo mọ obìnrin yìí, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Berta Brüggemeier. Mo bá sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́, ṣàlàyé nípa Jèhófà fún mi.” Látìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà la jọ máa ń wà pa pọ̀, a sì máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí jíròrò Bíbélì. Lára ohun tó kọ́ mi ni pé Ọlọ́run òtítọ́ náà, Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, onídàájọ́ òdodo, àti Ọlọ́run àlàáfíà. Ó tún kọ́ mi pé Ọlọ́run máa ṣàtúnṣe sí gbogbo ìpalára tí àwọn èèyàn burúkú àti àwọn ìkà ẹ̀dá ti fà. Sáàmù 37:10, 11 sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”
Wọ́n Dá Mi Sílẹ̀, Mo sì Lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì
Wọ́n dá mi sílẹ̀ lọ́dún 1956, lẹ́yìn tí mo ti lo ohun tó lé díẹ̀ lọ́dún márùn-ún lẹ́wọ̀n. Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀, mo fi Ìlà Oòrùn Jámánì, ìyẹn GDR sílẹ̀, mo sì lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì. Mo ti ní ọmọbìnrin méjì nígbà yẹn, orúkọ wọn ni Hannelore àti Sabine, mo sì mú àwọn náà dání. Nígbà tá a dé ọ̀hún, èmi àti ọkọ mi kọ ara wa sílẹ̀, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo wá rí i pé mo ní láti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà kí ìgbésí ayé mi lè bá ìlànà Jèhófà mu. Mo ṣe àwọn ìyípadà yìí, mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1958.
Nígbà tó yá, mo fẹ́ ọkọ míì, ìyẹn Klaus Menne tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbéyàwó èmi àti Klaus dùn yùngbà yungba, a sì ní àwọn ọmọ méjì, ìyẹn Benjamin àti Tabia. Ó bà mí nínú jẹ́ pé, Klaus kú nínú ìjàǹbá kan ní ogún [20] ọdún sẹ́yìn, àtìgbà yẹn ni mo sì ti di opó. Àmọ́, ìrètí àjíǹde máa ń tù mí nínú gan-an, torí mo mọ̀ pé Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15) Ohun mìíràn tó tún máa ń tù mí nínú ni pé àwọn ọmọ mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń sin Jèhófà.
Ọpẹ́lọpẹ́ pé mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè ṣe ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ò dà bí àwa èèyàn, ó mọ ìṣòro wa àtàwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn, èyí tí kò hàn sí àwọn míì. Kódà ní báyìí, ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ti mú kí n máa fiyè dénú, pàápàá nígbà tí mo bá rí i pé wọ́n ń hùwà àìtọ́ sí ẹnì kan tàbí sí èmi fúnra mi. Oníwàásù 5:8 sọ pé: “Bí ìwọ bá rí ìnilára èyíkéyìí tí a ṣe sí ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ àti fífi ipá mú ìdájọ́ àti òdodo kúrò ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ, má ṣe jẹ́ kí kàyéfì ṣe ọ́ lórí àlámọ̀rí náà, nítorí ẹni tí ó ga ju ẹni gíga ń wò ó, àwọn tí ó ga sì ń bẹ lókè wọn.” Ẹlẹ́dàá wa ni “ẹni tí ó ga ju ẹni gíga” tí ibí yìí ń sọ. Hébérù 4:13 sọ pé, “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.”
Ohun Tójú Mi Ti Rí Ní Àádọ́rùn-ún Ọdún Ti Mo Lò Láyé
Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń béèrè lọ́wọ́ mi bí ìgbésí ayé ṣe rí lábẹ́ ìjọba Násì àti ti Kọ́múníìsì. Kò sí èyí tó tuni lára nínú àwọn méjèèjì. Ohun tí àwọn ìjọba méjèèjì yìí, àtàwọn ìjọba yòókù mú kí ó ṣe kedere ni pé àwa èèyàn kò lè ṣàkóso ara wa. Òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì, ó sì ṣe kedere pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
Nígbà tí mo ṣì kéré, tí mi ò tíì gbọ́n, mo gbà pé ìjọba èèyàn ló máa fòpin sí àìṣẹ̀tọ́. Àmọ́, ó ti wá yé mi báyìí. Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló lè mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò láyé, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá pa àwọn ẹni búburú run, tó sì gbé àkóso ayé sọ́wọ́ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, ẹni tó jẹ́ pé kì í ṣe tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, àmọ́ ó máa ń ro tàwọn èèyàn mọ́ tiẹ̀. Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin.” (Hébérù 1:9) Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run o, pé ó mú mi wá sọ́dọ̀ Ọba tó jẹ́ àgbàyanu àti onídàájọ́ òdodo, ẹni tí màá wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ títí láé!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àtàwọn ọmọbìnrin mi Hannelore àti Sabine lẹ́yìn tá a dé sí Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi rèé pẹ̀lú ọmọkùnrin mi, Benjamin, àti ìyàwó rẹ̀, Sandra