Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ kí N Máa Lọ Sáwọn Ìpàdé Kristẹni?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ kí N Máa Lọ Sáwọn Ìpàdé Kristẹni?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ kí N Máa Lọ Sáwọn Ìpàdé Kristẹni?

ṢÉ O MÁA Ń GBÁDÙN ÌPÀDÉ KRISTẸNI?

BẸ́Ẹ̀ NI

TÚBỌ̀ MÁA ṢE BẸ́Ẹ̀

RÁRÁ

KÍ LO LÈ ṢE NÍPA RẸ̀?

BÍBÉLÌ sọ pé kí àwọn Kristẹni máa pé jọ láti jọ́sìn Ọlọ́run. (Hébérù 10:25) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kì í wù ẹ́ láti lọ sípàdé ńkọ́? Kí lo lè ṣe tó bá jẹ́ pé nígbà tó o bá wà ní ìpàdé, ńṣe lo máa ń ronú nípa àwọn ibòmíì tó o lè lọ tàbí nípa nǹkan míì tó wù ẹ́ pé kó o máa ṣe lákòókò ìpàdé yẹn? O lè gbìyànjú mélòó kan lára àwọn àbá tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí láti ṣe àtúnṣe tó yẹ.

1. MÁA LỌ SÍPÀDÉ DÉÉDÉÉ

Ohun tí Bíbélì sọ: “Kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà.”—Hébérù 10:25.

Bí nǹkan kan bá wà tí kì í wù ẹ́ ṣe, kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣe nǹkan náà déédéé? Ìdí ni pé tó o bá ń ṣe é déédéé, o máa bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn rẹ̀! Wò ó báyìí ná: tó o bá fẹ́ já fáfá nídìí eré ìdárayá kan, tó sì wù ẹ́ láti máa gbádùn rẹ̀, báwo ló ṣe máa rí tó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ̀ọ̀kan lo máa ń lọ ṣe ìdánrawò? Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tó o bá fẹ́ máa gbádùn àwọn ìpàdé Kristẹni. Bó o bá ṣe tẹra mọ́ lílọ sípàdé tó bẹ́ẹ̀ náà ní wàá ṣe túbọ̀ máa gbádùn rẹ̀ táá sì mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, o kò ní fẹ́ láti máa pa ìpàdé jẹ!—Mátíù 5:3.

Ìmọ̀ràn: Lẹ́yìn ìpàdé kọ̀ọ̀kan, ó kéré tan, lọ bá ọ̀kan lára àwọn tó ṣíṣẹ nípàdé kó o sì sọ ohun tó o gbádùn nínú iṣẹ́ tí onítọ̀hún ṣe. Ṣe àkọsílẹ̀ ohun kan tó o gbádùn nípàdé náà sínú ìwé kan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni èyí tó pọ̀ nínú àwọn ìpàdé máa ń dá lé, pinnu pé wàá túbọ̀ máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí bí àwọn ohun tó ò ń gbọ́ nípàdé ṣe wúlò fún ẹ gan-an.

“Látìgbà tí mo ti wà ní kékeré ni wọ́n ti kọ́ mi pé ó pọn dandan pé kéèyàn máa lọ sípàdé. Nígbà tí mo ṣì kéré pàápàá, mi kì í fẹ́ pa ìpàdé jẹ. Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún méje ló ti mọ́ mi lára láti máa lọ sípàdé, kò sì tíì sú mi títí di báyìí.”—Kelsey.

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Àwọn tó máa ń lọ sípàdé déédéé máa ń gbádùn ìpàdé gan-an, wọ́n sì máa ń jàǹfààní gan-an!

2. FIYÈ SÍ OHUN TÍ Ò Ń GBỌ́

Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.”—Lúùkù 8:18.

Àwọn olùṣèwádìí sọ pé kódà àwọn tó máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí àwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀ kì í rántí gbogbo nǹkan tí wọ́n gbọ́, lópin gbogbo rẹ̀, wọn kì í lè rántí tó ìlàjì ohun tí wọ́n gbọ́. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ náà ni owó máa ń sọnù lọ́wọ́ rẹ, ǹjẹ́ o ò ní wá nǹkan ṣe sí i?

Ìmọ̀ràn: Máa jókòó ti àwọn òbí rẹ lọ́wọ́ iwájú, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa pọkàn pọ̀. Máa ṣe àkọsílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn èèyàn máa ń gbà kẹ́kọ̀ọ́, ó máa dára tó o bá lè máa ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì, èyí á jẹ́ kó o lè máa fọkàn bá ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lọ, wàá sì lè ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ rẹ lẹ́yìn náà.

“Nígbà kan, mi kì í lè pọkàn pọ̀ nípàdé, àmọ́ nǹkan ti yàtọ̀ báyìí. Mo máa ń rántí ìdí tí mo fi wà níbẹ̀. Kì í kàn ṣe ká máa pàtẹ́wọ́ ká sì máa jó, bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ní ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì. Torí kí n lè jọ́sìn Ọlọ́run kí n sì kọ́ ẹ̀kọ́ tó máa ṣe mí láǹfààní láyé mi ni mo ṣe máa ń lọ sípàdé.”—Kathleen.

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Tó o bá lọ sípàdé ṣùgbọ́n tí o kò fọkàn sí ohun tí wọ́n sọ, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o bá lọ síbi àpèjẹ kan àmọ́ tí o kò jẹun.

3. LỌ́WỌ́ NÍNÚ OHUN TÍ WỌ́N Ń ṢE

Ohun tí Bíbélì sọ: “Irin ni a fi ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.”—Òwe 27:17.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, ipa pàtàkì lò ń kó nínú àwọn ìpàdé Kristẹni. Má ṣe fojú kéré bó o ṣe máa ń lọ sípàdé àti bó o ṣe máa ń kópa, bóyá nípa dídáhùn nínú apá ìpàdé tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn tàbí nípa fífara rora pẹ̀lú àwọn ará.

Ìmọ̀ràn: Tó bá ti kan ìbéèrè àti ìdáhùn, rí i pé o dáhùn lẹ́ẹ̀kan, ó kéré tán. Máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ará nígbà tí wọ́n bá ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ míì, bóyá kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, ó sì lè jẹ́ lẹ́yìn ìpàdé. Wá ẹnì kan tí o kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè bá sọ̀rọ̀ kó o sì wá ohun kan tẹ́ ẹ lè sọ̀rọ̀ lé lórí.

“Nígbà tí mo wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́tàdínlógún, mo máa ń gbé makirofóònù nípàdé, mo sì máa ń to orí pèpéle. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí mú kí n mọ̀ pé mo wúlò gan-an, ó sì máa ń mú kí n máa lọ sípàdé déédéé kí n sì tètè máa dé ìpàdé. Ìyẹn mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì mú kí n fẹ́ láti sin Ọlọ́run.”—Miles.

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Má kàn jókòó síbẹ̀ lásán, rí i pé ìwọ náà lọ́wọ́ nínú ohun tí wọ́n ń ṣe! Àìsí níbẹ̀ ni àìbáwọn dá sí i.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

A FẸ́ KÓ O WÁ!

Ṣó o fẹ́

● Mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run?

● Kí ìwà rẹ dára sí i?

● Ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi?

Tó o bá wá sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọwọ́ rẹ máa tẹ gbogbo nǹkan yìí, àtàwọn nǹkan míì! Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa láti jọ́sìn Ọlọ́run. A kì í gbé igbá owó níbẹ̀, gbogbo èèyàn la sì pè.

Má ṣe jẹ́ kí àǹfààní yìí fò ẹ́ ru! Gbọ̀ngàn Ìjọba yàtọ̀ pátápátá sí ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tó o ti lọ. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dìídì máa ń kọ́ ní àwọn ìpàdé wa, wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú kó o gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ!—Diutarónómì 31:12; Aísáyà 48:17.

SaiNígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó yà mí lẹ́nu gan-an pé kò sí ère kankan níbẹ̀, kò sí ẹnì kan tó múra bí àlùfáà, kò sì sẹ́ni tó ní kí n mówó wá. Tọmọdé tàgbà ló yọ̀ mọ́ mi, ọkàn mi sì balẹ̀. Ohun tí wọ́n sọ nípàdé náà rọrùn láti lóye, ó sì bọ́gbọ́n mu. Òtítọ́ tí mo ti ń wá látọjọ́ pípẹ́ ni mo rí wẹ́rẹ́ yìí!

DeyaniraỌmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tọmọdé tàgbà ló kí mi káàbọ̀ bí mo ṣe débẹ̀. Mo rí i pé inú wọn dùn gan-an pé mo wá síbẹ̀, mo sì rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Torí bí wọ́n ṣe gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ yẹn, ojú kò tì mí láti pa dà lọ síbẹ̀!

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Lọ wo ohun tá a máa jíròrò nípàdé ìjọ ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Yan èyí tó wù ẹ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kó o wá . . .

GÉ IBÍ YÌÍ, KÓ O SÌ KỌ Ọ́ SÍNÚ ÀLÀFO YÌÍ

Kọ ọ̀rọ̀ kún àyè Kọ ọ̀rọ̀ kún àyè tó wà

tó wà nísàlẹ̀ yìí nísàlẹ̀ yìí lẹ́yìn tí wọ́n ti

kó o tó lọ sípàdé. bójú tó apá yìí tán.

Apá ìpàdé tó wù mí: Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́:

․․․․․ ․․․․․

Ohun tí mo fẹ́ Ohun tí màá sọ fún

mọ̀ nípa kókó yìí: olùbánisọ̀rọ̀ náà pé mo

gbádùn nínú iṣẹ́ rẹ̀:

․․․․․ ․․․․․