Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbóríyìn fún Àwọn Èèyàn?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbóríyìn fún Àwọn Èèyàn?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn máa ń ronú pé àwọn èèyàn kò mọyì gbogbo ìgbìyànjú àwọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òṣìṣẹ́ kan máa ń ronú pé àwọn tó gba àwọn síṣẹ́ kò mọyì àwọn. Ọ̀pọ̀ lọ́kọláya ló gbà pé ẹnì-kejì àwọn kò mọyì àwọn. Àwọn ọmọ kan sì máa ń ronú pé kò sóhun táwọn lè ṣe tó máa tẹ́ àwọn òbí àwọn lọ́rùn. Kò sí àní-àní pé tó bá ti mọ́ wa lára láti máa gbóríyìn fúnni, ó ṣeé ṣe kí irú àwọn èrò yìí má ṣe máa wá sí àwọn èèyàn lọ́kàn.
Lóde òní, kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn lára láti máa gbóríyìn fáwọn ẹlòmíì. Kò yani lẹ́nu rárá pé ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀, torí pé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin.”—2 Tímótì 3:1, 2.
Ǹjẹ́ ẹnì kan ti gbóríyìn fún ẹ tọkàntọkàn rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ́ náà á gbà pé ó máa ń mú kí orí ẹni wú, ó sì máa ń mú kí ara ẹni yá gágá. Bíbélì sọ pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Òwe 15:23) Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe rere sí àwọn èèyàn.
Ibi Tí Àwọn Èèyàn Dára Sí Ni Kó O Máa Wò
Torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ìwà dáadáa tá à ń hù àti iṣẹ́ rere tá à ń ṣe ló máa ń wò, ó sì mọyì wọn. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ojú [Ọlọ́run] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Tá a bá ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó dájú pé Ọlọ́run máa kíyè sí i.
Kì í ṣe àṣìṣe wa ni Jèhófà Ọlọ́run ń ṣọ́. Tó bá jẹ́ àṣìṣe wa ló ń ṣọ́ ni, kò sí ẹni tó máa lè dúró. (Sáàmù 130:3) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà dà bí awakùsà tó máa ń fi sùúrù walẹ̀ tó sì máa ń ṣa àwọn òkúta lásán dà nù kó bàa lè rí òkúta iyebíye. Inú awakùsà máa ń dùn nígbà tó bá rí òkúta iyebíye kan. Òkúta iyebíye yìí lè má kọ́kọ́ fani mọ́ra, àmọ́ awakùsà náà mọ̀ pé ohun iyebíye ló máa dà tó bá yá. Lọ́nà kan náà, nígbà tí Ọlọ́run bá ṣàyẹ̀wò ọkàn wa, kì í ṣe ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí ló ń wá, àwọn ànímọ́ tó dára tá a ní ló ń wá. Inú rẹ̀ sì máa ń dùn tó bá rí ohun tó dára. Ó mọ̀ pé bá a bá ń sapá láti mú kí àwọn ànímọ́ tá a ní yìí sunwọ̀n sí i, a máa dẹni tó ń fi ìṣòtítọ́ àti gbogbo ọkàn sin Jèhófà.
A lè kẹ́kọ̀ọ́ látara Ọlọ́run. Nígbà tá a bá kíyè sí àwọn èèyàn, àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn la sábà máa ń gbájú mọ́. Àmọ́, tá a bá ń fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n, a máa rí ibi tí wọ́n dára sí. (Sáàmù 103:8-11, 17, 18) Tá a bá kíyè sí ìwà rere wọn, ẹ jẹ́ ká gbóríyìn fún wọn. Báwo nìyẹn ṣe máa rí lára wọn? Ọ̀rọ̀ wa máa tù wọ́n lára, ìyẹn sì máa mú kí wọ́n túbọ̀ sapá láti máa hùwà rere! Inú àwa fúnra wa náà á dùn pé a ṣe ohun tó dára fún àwọn míì.—Ìṣe 20:35.
Máa Yin Àwọn Èèyàn fún Ohun Rere Tí Wọ́n Ṣe
Jésù sábà máa ń kíyè sí ohun dáadáa tí àwọn èèyàn ṣe, ó sì máa ń yìn wọ́n. Nígbà kan tí obìnrin aláìsàn kan tí ẹ̀rù ń bà dọ́gbọ́n fọwọ́ kan ẹ̀wù Jésù pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé òun máa rí ìwòsàn, Jésù yìn ín, ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”—Máàkù 5:34.
Nígbà mìíràn, bí Jésù ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ń fowó sínú àpótí ìṣúra. Ó wá rí opó aláìní kan tí ó sọ “owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” sínú àpótí náà. Owó tí àwọn míì jù sínú àpótí náà ju ti obìnrin yìí lọ. Síbẹ̀, gbangba-gbàǹgbà báyìí ni Jésù gbóríyìn fún obìnrin náà torí ọrẹ àtinúwá tó ṣe yẹn, ó sọ pé: “Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Lúùkù 21:1-4.
opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.”—Báwo la ṣe lè fara wé Jésù? Bíbélì sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”—Òwe 3:27.
Yinniyinni Kẹ́ni Ó Ṣèmíì
Nínú ayé tó kún fún ìwà àìmoore yìí, gbogbo wa pátá la fẹ́ kí àwọn èèyàn mọyì wa kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ wa. Tá a bá ń yin àwọn èèyàn tọkàntọkàn, ó máa fún wọ́n lókun ó sì máa jẹ́ kí ara wọn yá gágá. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dà bí ọ̀rọ̀ Yorùbá tó sọ pé “yinniyinni kẹ́ni ó ṣèmíì.”—Òwe 31:28, 29.
Bíbélì rọ gbogbo Kristẹni pé: “Kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24) Ẹ wo bí ayé yìí ì bá ṣe dára tó ká sọ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, tí wọ́n ń kíyè sí ibi tí wọ́n dára sí, tí wọ́n sì máa ń yìn wọ́n fún ohun rere tí wọ́n ṣe. Kò sí àní-àní, yinniyinni kẹ́ni ó ṣèmíì ni!
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn èèyàn torí ohun rere tí wọ́n ṣe?—Òwe 15:23.
● Nígbà tí Jèhófà bá ń yẹ̀ wá wò, àwọn nǹkan wo ló máa ń kíyè sí?—2 Kíróníkà 16:9.
● Ìgbà wo ló yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn èèyàn?—Òwe 3:27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ǹjẹ́ o máa ń kíyè sí ohun rere tí àwọn èèyàn ń ṣe, ṣé o sì máa ń yìn wọ́n?