Kí Nìdí Tí Ọ̀rọ̀ Mi Kò Fi Yé Àwọn Òbí Mi?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Kí Nìdí Tí Ọ̀rọ̀ Mi Kò Fi Yé Àwọn Òbí Mi?
RONÚ LÓRÍ ÀPẸẸRẸ YÌÍ.
Lọ́jọ́ Friday kan, ní nǹkan bí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́, bí Jim, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ṣe fẹ́ jáde kúrò nínú ilé, ó tẹsẹ̀ mọ́rìn. Ó dágbére fáwọn òbí rẹ̀, ó ní, “Mò ń jáde o!” Ó gbà pé wọn kò ní bi òun ní ìbéèrè tí wọ́n sábà máa ń béèrè.
Ó yẹ kí òun náà ti mọ̀ pé wọn kò ní ṣàì béèrè ìgbà tí òun máa dé.
Mọ́mì ẹ̀ béèrè pé: “Jimmy, aago mélòó ni ká máa retí ẹ?”
Ńṣe ni Jim dúró pa sójú kan. Kò kọ́kọ́ mọ ohun tó máa sọ, ló bá sọ pé: “Un . . . ẹẹ . . . , ẹ má wulẹ̀ dúró dè mí, tẹ́ ẹ bá ti ṣe tán láti sùn, ẹ lọ sùn ní tiyín, ṣẹ́ ẹ gbọ́ mọ́mì?” Jim ṣílẹ̀kùn, ó ku díẹ̀ kó jáde. Àmọ́ kò tíì jáde tí Dádì ẹ̀ fi sọ pé, “Dúró ńbẹ̀, James!”
Jim tún dúró pa, ló wá gbọ́ tí Dádì rẹ̀ fi ohùn líle sọ pé: “O mọ òfin wa nínú ilé yìí. Aago mẹ́wàá kò gbọ́dọ̀ lù bá ẹ níta, kò sí àwáwí o!”
Inú Jim ò dùn sí ohun tí dádì ẹ̀ sọ yìí, ó wá ní: “Dádì, mi ò rò pé ẹ mọ bó ṣe máa ń tì mí lójú tó láti sọ fáwọn ọ̀rẹ́ mi pé mi ò ní pẹ́ pa dà sílé.”
Dádì rẹ̀ kò tiẹ̀ ṣe bí ẹni gbọ́ ohun tó sọ. Ńṣe ló tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, ó ní,“aago mẹ́wàá ò gbọ́dọ̀ lù bá ẹ níta, kò sí àwáwí o!”
Ó ṢEÉ ṢE kí irú nǹkan báyìí ti wáyé rí láàárín ìwọ àtàwọn òbí ẹ. Ó lè jẹ́ nítorí aago tó yẹ kó o máa wọlé, irú orin tó yẹ kó o máa gbọ́, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí irú aṣọ tó yẹ kó o máa wọ̀ ni àwọn òbí rẹ ṣe ṣe òfin, wọn ò sì ṣe tán láti yí òfin náà pa dà. Àpẹẹrẹ kan rèé:
“Lẹ́yìn tí mọ́mì mi fẹ́ ọkọ míì, ọkọ wọn kò gbà mí láyè láti máa gbọ́ àwọn orin tí mo máa ń gbọ́. Àfìgbà tí mo kó gbogbo àwo CD mi dà nù!”—Brandon. a
“Mọ́mì mi máa ń sọ̀rọ̀ sí mi nítorí pé mi ò lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́ nígbà tí mo bá rí ẹnì kan tí mo sì bi wọ́n bóyá mo lè máa bá onítọ̀hún ṣọ̀rẹ́, wọ́n á sọ pé rárá, torí pé àwọn ò mọ ẹni náà. Ó sú mi o!”—Carol.
“Aṣọ tó tóbi ni Dádì mi àti ìyàwó wọn máa ń fẹ́ kí n wọ̀. Dádì mi tún sọ pé síkẹ́ẹ̀tì tí kò bá dé orúnkún ti kéré jù!”—Serena.
Kí lo lè ṣe bí ìwọ àti àwọn òbí rẹ kì í bá gbọ́ ara yín yé? Ǹjẹ́ o lè sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún wọn? Joanne, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé, “Àwọn òbí mi kì í fẹ́ gbọ́ tèmi.” Amy tó jẹ́ ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], sọ́ pé, “Tí mo bá ti rí i pé ọ̀rọ̀ mi ò yé àwọn òbí mi, ńṣe ni mo máa ń dákẹ́.”
Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tètè sú ẹ! O lè rò pé ńṣe làwọn òbí rẹ kò fẹ́ gbọ́ tìẹ, àmọ́ tí kò sì rí bẹ́ẹ̀.
Rò ó wò náà: Àní Ọlọ́run pàápàá máa ń tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà tẹ́tí sí Mósè nígbà tó ń bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó hùwà tí kò tọ́.— Ẹ́kísódù 32:7-14; Diutarónómì 9:14, 19.
O lè máa ronú pé àwọn òbí rẹ kì í gba tiẹ̀ rò bíi ti Ọlọ́run. Òótọ́ ni pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín ọ̀rọ̀ tí Mósè bá Jèhófà sọ nípa ìyà tí Jèhófà fẹ́ fi jẹ odindi orílẹ̀-èdè kan àti ohun tó o fẹ́ bá Dádì tàbí Mọ́mì ẹ sọ nípa aago tó o fẹ́ máa wọlé. Àmọ́, a lè fi ìlànà kan náà yanjú ọ̀rọ̀ méjèèjì:
Tí ohun tó o fẹ́ sọ bá lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, àwọn tó wà nípò àṣẹ lè tẹ́tí sí ohun tó o fẹ́ sọ. Nínú ọ̀rọ̀ yìí, àwọn òbí ẹ ló wà nípò àṣẹ.
Ọ̀nà tó o bá gbà sọ̀rọ̀ ló máa pinnu bóyá wọ́n máa tẹ́tí sí ẹ tàbí wọn ò ní tẹ́tí. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí, wàá lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára:
1. Mọ ohun tó ń fa ìṣòro náà. Kọ ohun tó máa ń fa àríyànjiyàn láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.
․․․․․
2. Mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa ń rí lára rẹ. Lórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí, kọ bó ṣe máa ń rí lára rẹ nígbà tí àwọn òbí rẹ kò bá lóye rẹ, bóyá ó máa ń dùn ẹ́, ó ń bà ẹ́ nínú jẹ́, ó ń tì ẹ́ lójú, tàbí ó ń ṣe ẹ́ bíi pé wọn kò fọkàn tán ẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Bí àpẹẹrẹ, nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, Jim sọ pé òfin tí àwọn òbí òun fi lélẹ̀ lórí aago tó yẹ kí òun máa wọlé máa ń kó ìtìjú bá òun lójú àwọn ọ̀rẹ́ òun.)
․․․․․
3. Fi ara ẹ sípò àwọn òbí rẹ. Ká sọ pé o ní ọmọ tí kò tíì pé ogún ọdún tó ní irú ìṣòro tó o kọ sí kókó àkọ́kọ́ lókè. Ká gbà pé ìwọ ni òbí, kí ló máa jẹ ẹ́ lógún jù, kí sì nìdí? (Àpẹẹrẹ: Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láàárín Jim àtàwọn òbí rẹ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni ẹ̀rù ń ba àwọn òbí Jim pé nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀ sí i.)
․․․․․
4. Tún ronú dáadáa lórí ọ̀rọ̀ náà. Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ǹjẹ́ o rí àǹfààní kankan nínú ohun tí àwọn òbí rẹ sọ?
․․․․․
Kí lo lè ṣe láti fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?
․․․․․
5. Jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ kẹ́ ẹ sì jọ wá ojútùú sí i. Tó o bá lè ṣe àwọn ohun tá a sọ lókè yìí, tó o sì lo àwọn àbá tó wà nínú àpótí tá a pè ní “Bó O Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Rẹ Sọ̀rọ̀,” wàá rí i pé ìwọ àtàwọn òbí rẹ á lè máa gbọ́ ara yín yé, wàá sì fi hàn pé ìwọ́ náà ti ń gòkè àgbà. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kellie máa ń gbádùn irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú dádì àti mọ́mì rẹ̀ gan-an. Ó sọ pé, “Ọ̀rọ̀ kò lè lójú tó o bá ń bá àwọn òbí rẹ jiyàn, o ò sì lè borí wọn. Ohun tí èmi máa ń ṣe ni pé mo máa ń wá bí mo ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn òbí mi. Wọ́n sábà máa ń gba tèmi rò, èmi náà sì máa ń gbà pẹ̀lú wọn.”
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
BÓ O ṢE LÈ BÁ ÀWỌN ÒBÍ RẸ SỌ̀RỌ̀
“Ọ̀rọ̀ máa lójú tó o bá tẹ́tí nígbà táwọn òbí rẹ bá ń sọ̀rọ̀ jù pé kó o wá máa pariwo sọ̀rọ̀. Tó o bá tẹ́tí sí àwọn òbí rẹ, tó o sì gbìyànjú láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ, ó ṣeé ṣe kí àwọn náà tẹ́tí sí ẹ kí wọ́n sì lóye rẹ.”—Rianne.
Ka Fílípì 2:3, 4.
“Má ṣe gbó àwọn òbí rẹ lẹ́nu! Mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀, tíyẹn sì máa ń kóyà jẹ mí. Àmọ́, ká sọ pé mi kì í gbó wọn lẹ́nu ni, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní wáyé!”—Danielle.
Ka Òwe 17:27; 21:23.
“Ní sùúrù dìgbà tí ara bá tu gbogbo yín, tó o sì mọ̀ pé àwọn òbí rẹ máa ṣe tán láti tẹ́tí sí ẹ.”—Collette.
Ka Òwe 25:11.
“Ó gbọ́dọ̀ ṣe kedere sí àwọn òbí rẹ pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn àti pé lóòótọ́ lo ṣe tán láti tẹ́tí sí ohun tí àwọn ń bá ẹ sọ. Torí náà, kó o tó sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹ, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o gbọ́ ohun tí wọ́n sọ àti pé ọ̀rọ̀ wọn yé ẹ.”—Emily.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀
Kì í ṣe gbogbo àríyànjiyàn lèèyàn gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo máa ‘sọ ohun tí o ní í sọ ní ọkàn-àyà rẹ kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’ (Sáàmù 4:4) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Beatrice sọ pé: “Nígbà míì, mo máa ń ronú pé kò sídìí láti máa fa ọ̀rọ̀, torí pé láàárín òní sí ọ̀la, ọ̀rọ̀ náà kò ní tó nǹkan mọ́. Ṣe ni mo máa ń jẹ́ kí ó tán síbẹ̀.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?
Báwo lẹ ṣe yanjú èdèkòyédè pẹ̀lú àwọn òbí yín? Ká sọ pé ẹ tún pa dà di ọ̀dọ́, ǹjẹ́ ọ̀nà míì wà tẹ́ ẹ máa gbà bójú tó ọ̀ràn náà? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lohun tẹ́ ẹ máa ṣe?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
Wyndia—Mo máa ń ronú dáadáa kí n tó sọ̀rọ̀. Mo máa ń ronú lórí ohun táwọn òbí mi sọ, mo sì máa ń gbàdúrà kí n tó sọ ohunkóhun. Tí mo bá mọ̀ pé ohun tí mo fẹ́ sọ máa bí àwọn òbí mi nínú, ńṣe ni mo máa ń dákẹ́ títí màá fi lè sọ ọ̀rọ̀ náà láìsí ariwo.
Ross—Tí mo bá rí i pé inú fẹ́ bí mi, mo máa ń sọ fún ara mi pé kò yẹ kí n jẹ́ kí ohun tí kò tó nǹkan bà mí nínú jẹ́ jálẹ̀ ọjọ́ yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, mo wá rí i pé mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ bínú mọ́ bí ìgbà tí mo ṣì kéré.
Ramona—Mo rí i pé ohun tó dára jù ni pé kí n máa tẹ́tí sí ohun tí àwọn òbí mi ń sọ. Ó lè wá jẹ́ pé èrò wọn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tèmi, torí náà kò ní sí ìdí pé à ń jiyàn tó bí mo ṣe rò.