“Àwọn Ohun Àtijọ́ . . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà”
“Àwọn Ohun Àtijọ́ . . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà”
Ẹlẹ́dàá wa ti fi ohun tó máa ṣe láìpẹ́ hàn wá. Ó sọ pé:
“Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—AÍSÁYÀ 65:17.
Àwọn nǹkan wo ni “àwọn ohun àtijọ́” tí “kì yóò wá sí ọkàn-àyà”? Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà ìrẹ́jẹ, àìsàn, ìyà àtàwọn wàhálà míì tó ń dààmú aráyé ni àwọn ohun àtijọ́ yìí. Báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe máa dópin? Èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí “ọ̀run tuntun” àti “ayé tuntun” tí Ọlọ́run ṣèlérí bá dé.”
A máa gbọ́ àlàyé lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó fani lọ́kàn mọ́ra yìí àti ìtumọ̀ wọn nínú àsọyé fún gbogbo èèyàn náà, “Àwọn Ohun Àtijọ́. . . Kì Yóò Wá sí Ọkàn-àyà.” Àpéjọ Àgbègbè tá a pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní, “Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò la ti máa gbọ́ àsọyé yìí, èyí tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní September 2012, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Tìfẹ́tìfẹ́ la pè ọ́ pé kó o lọ síbi tó sún mọ́ ẹ jù lọ nínú àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí. Tó o bá fẹ́ mọ ibi tó sún mọ́ ẹ jù lọ, béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. A kọ àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí kárí ayé sórí ìkànnì www.jw.org lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.