ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti October 6-12, 2025

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti October 6-12, 2025
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202025326/univ/art/202025326_univ_sqr_xl.jpg
mwb25 September ojú ìwé 10-11

October 6-12

ONÍWÀÁSÙ 5-6

October 6-12

Orin 42 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí àlùfáà kan ṣe ń ṣàlàyé Ìwé Òfin

1. Bá A Ṣe Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Wa Atóbilọ́lá

(10 min.)

Tá a bá ń kíyè sí bá a ṣe ń múra wá sípàdé, ìyẹn á fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà (Onw 5:1; w08 8/15 15-16 ¶17-18)

Tẹ́nì kan bá ń ṣojú fún ìjọ nínú àdúrà, kó gbà á tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kó nítumọ̀, kó má sì jẹ́ kí àdúrà náà gùn jù (Onw 5:2; w09 11/15 11 ¶21)

Ó yẹ ká mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ (Onw 5:4-6; w17.04 6 ¶12)

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Onw 5:8—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè tù wá nínú tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ? (w20.09 31 ¶3-5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà fẹ́ máa bá ẹ jiyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jíròrò kókó kan ní apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn” ní àfikún A látinú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)

6. Pa Dà Lọ

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi fídíò kan tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 3)

7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 160

8. Ṣé O Máa Ń Lo Apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn”?

(15 min.) Ìjíròrò.

Kò sí àní-àní pé àtìgbà tí ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn ti jáde ló ti ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. A dìídì ṣètò àwọn kókó tó wà nínú Àfikún A kó lè rọrùn fún wa láti fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ṣe tààrà kọ́ àwọn èèyàn. (Heb 4:12) Ṣé o mọ àwọn àkòrí mẹ́sàn-án tó wà ní apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn”?

  • Báwo la ṣe lè mú ọ̀rọ̀ Bíbélì wọnú ọ̀rọ̀ tá à ń bá ẹnì kan sọ?—lmd àfikún A

  • Àwọn àkòrí wo làwọn tó wà lágbègbè yín nífẹ̀ẹ́ sí?

  • Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o túbọ̀ mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà ní àfikún A?

Bó o ṣe ń lo àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí lóde ìwàásù látìgbàdégbà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti tètè rántí wọn. Àmọ́ ká tó lè lò wọ́n, ó yẹ ká kọ́kọ́ rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ “Irin Ń Pọ́n Irin”—Máa Wá Àwọn Tó O Máa Wàásù Fún. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí la lè ṣe ká lè máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀ lágbègbè wa?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 34 àti Àdúrà