ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Fi Ọgbọ́n Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́

Yorùbá
Fi Ọgbọ́n Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202022325/univ/art/202022325_univ_sqr_xl.jpg
mwb22 September ojú ìwé 4

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Fi Ọgbọ́n Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́

Fi Ọgbọ́n Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́

Sólómọ́nì ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu ní ti pé ó fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ abọ̀rìṣà (1Ọb 11:1, 2; w18.07 18 ¶7)

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó Sólómọ́nì yí i lọ́kàn pa dà, kò sì sin Jèhófà mọ́ (1Ọb 11:3-6; w19.01 15 ¶6)

Inú bí Jèhófà gan-an sí Sólómọ́nì (1Ọb 11:9, 10; w18.07 19 ¶9)

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn Kristẹni tí kò tíì ní ọkọ tàbí aya níyànjú pé kí wọ́n gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1Kọ 7:39) Síbẹ̀, ti pé ẹnì kan ti ṣèrìbọmi kò túmọ̀ sí pé ẹni náà máa jẹ́ ọkọ tàbí aya rere. Bi ara ẹ pé, Ṣé ẹni yìí máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa sin Jèhófà tọkàntọkàn? Ṣé ẹni náà ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú? Rí i dájú pé ó fara balẹ̀ mọ ẹnì kan dáadáa kó o tó pinnu pé ẹni náà lo máa fẹ́.