ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ohun Tó Lè Tù Wá Nínú Kí Àjíǹde Tó Dé

Yorùbá
Ohun Tó Lè Tù Wá Nínú Kí Àjíǹde Tó Dé
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202022343/univ/art/202022343_univ_sqr_xl.jpg
mwb22 September ojú ìwé 15

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tó Lè Tù Wá Nínú Kí Àjíǹde Tó Dé

Ohun Tó Lè Tù Wá Nínú Kí Àjíǹde Tó Dé

Tí ẹni tá a fẹ́ràn bá kú, ìrètí tá a ní pé ẹni náà máa jí dìde máa ń tù wá nínú. Síbẹ̀ náà, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá gbogbo wa. (Ais 25:7, 8) Ìdí kan rèé tó fi jẹ́ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora.” (Ro 8:22) Kí àjíǹde tó wáyé, kí ló lè tù wá nínú ní báyìí téèyàn wa bá kú? A máa rí àwọn ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ TÍ ẸNI TÓ O FẸ́RÀN BÁ KÚ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá Danielle, Masahiro àti Yoshimi?

  • Àwọn àbá márùn-ún wo la mẹ́nu kan nínú fídíò yìí, báwo ló sì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Ta ni Orísun gbogbo ìtùnú?—2Kọ 1:3, 4