Àwọn arákùnrin tí wọ́n dá sílẹ̀ lágọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Jámánì, lọ́dún 1945

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI September 2019

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ìjíròrò tó dá lórí bí ọ̀rọ̀ ẹni kọ̀ọ̀kan wa ṣe jẹ Ọlọ́run lọ́kàn tó.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Àlùfáà Títí Láé Ní Ọ̀nà Ti Melikisédékì”

Báwo ni Melikisédékì ṣe ṣàpẹẹrẹ Jésù?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Òjìji Àwọn Nǹkan Rere Tó Ń Bọ̀”

Báwo làwọn nǹkan tó wà nínú àgó ìjọsìn ṣe ṣàpẹẹrẹ ìràpadà?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́

Kí ni ìgbàgbọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni ní ìgbàgbọ́?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kí Lo Máa Ṣe Ní Ọdún Ọ̀gbẹlẹ̀?

Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ fara da “ooru” àti “ọdún ọ̀gbẹlẹ̀” bó ṣe wà nínú Jeremáyà 17:8?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ìbáwí Máa Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa

Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà máa ń gbà bá wa wí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí máa ń dunni, tá a bá jẹ́ kó dá wa lẹ́kọ̀ọ́, a máa di Kristẹni táyé ẹ̀ nítumọ̀.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ohun Tó Ń Fa Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú

Èròkerò lè mú kẹ́nì kan hu ìwàkíwà. Tó bá jẹ́ pé a ti fẹ́ dẹ́ṣẹ̀ tó lè yọrí sí ikú, kí lohun tá a lè ṣe tí èròkerò bá sọ sí wa lọ́kàn?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

“Ẹ Máa Ronú Lórí Àwọn Nǹkan Yìí”

Ohun tí Sátánì ń fẹ́ ni pé ká máa fi ọkàn wa ro èròkerò. Báwo la ṣe lè dojú ìjà kọ Sátánì?