ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù

Yorùbá
Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202018332/univ/art/202018332_univ_sqr_xl.jpg

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù

Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀, Kó O Sì Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ Bí I Ti Jésù

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni ọkùnrin títóbi jù lọ tó gbé ayé rí, síbẹ̀ ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ torí pé Jèhófà ló máa ń fògo fún. (Jo 7:16-18) Lọ́wọ́ kejì, Sátánì ló di Èṣù, tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” (Jo 8:44) Ìwà burúkú Sátánì yìí náà làwọn Farisí máa ń hù, ìgbéraga wọn pọ̀ débi pé wọn máa ń fojú kéré àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà. (Jo 7:45-49) Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jésù tí wọ́n bá fún wa láǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan?

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”​—YẸRA FÚN OWÚ ÀTI ÌFỌ́NNU, APÁ KÌÍNÍ, LẸ́YÌN NÁÀ, BÉÈRÈ ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Adé sọ tó fi hàn pé ó jẹ́ agbéraga?

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”​—YẸRA FÚN OWÚ ÀTI ÌFỌ́NNU, APÁ KEJÌ, LẸ́YÌN NÁÀ, BÉÈRÈ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni Adé ṣe fi hàn pé òun lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

    Báwo ni Adé ṣe fún Báyọ̀ àti Kọ́lá níṣìírí?

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”​—KỌ ÌGBÉRAGA ÀTI ÌWÀKÍWÀ SÍLẸ̀, APÁ KÌÍNÍ, LẸ́YÌN NÁÀ, BÉÈRÈ ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Arákùnrin Adú ṣe tó fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀?

JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”​—KỌ ÌGBÉRAGA ÀTI ÌWÀKÍWÀ SÍLẸ̀, APÁ KEJÌ, LẸ́YÌN NÁÀ, BÉÈRÈ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ni Arákùnrin Adú ṣe tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀?

    Ẹ̀kọ́ wo ni Fèyí rí kọ́ nípa bí Arákùnrin Adú ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀?