ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Kí Nìdí Tó O Fi Mọyì Ìjọsìn Mímọ́?

Yorùbá
Kí Nìdí Tó O Fi Mọyì Ìjọsìn Mímọ́?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202017323/univ/art/202017323_univ_sqr_xl.jpg

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kí Nìdí Tó O Fi Mọyì Ìjọsìn Mímọ́?

Kí Nìdí Tó O Fi Mọyì Ìjọsìn Mímọ́?

Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn níṣìírí gan-an, torí pé ó jẹ́ kí wọ́n nírètí pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò. Ní àkókò òpin tá a wà yìí, ìjọsìn mímọ́ ti ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá,’ àwa náà sì wà lára àwọn tó ń wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀. (Ais 2:2) Ǹjẹ́ o máa ń ronú nígbà gbogbo nípa àǹfààní tó o ní láti mọ Jèhófà, tó o sì ń sìn ín?

ÈRÈ TÓ WÀ NÍNÚ ÌJỌSÌN MÍMỌ́:

  • À ń jẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí, tó ń jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ, à ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa, a sì ní ìrètí tó dájú.​—Ais 48:17, 18; 65:13; Ro 15:4

  • A wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn.​—Sm 133:1; Jo 13:35

  • Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, a sì ń fi ayọ̀ ṣiṣẹ́ ìwàásù náà.​—Iṣe 20:35; 1Kọ 3:9

  • “Àlàáfíà Ọlọ́run” máa ń fún wa lókun nígbà ìṣòro.​—Flp 4:6, 7

  • A ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.​—2Ti 1:3

  • A ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.”​—Sm 25:14

Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà fi hàn pé mo mọyì ìjọsìn mímọ́?