ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìwà Mímọ́ àti Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀ Máa Ń Yíni Lọ́kàn Pa Dà

Yorùbá
Ìwà Mímọ́ àti Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀ Máa Ń Yíni Lọ́kàn Pa Dà
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202019369/univ/art/202019369_univ_sqr_xl.jpg

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìwà Mímọ́ àti Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀ Máa Ń Yíni Lọ́kàn Pa Dà

Ìwà Mímọ́ àti Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀ Máa Ń Yíni Lọ́kàn Pa Dà

Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwà rere àwọn ìyàwó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló máa ń mú kí ọkọ wọn náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, èyí lè gba pé kí wọ́n fara da àtakò fún ọ̀pọ̀ ọdún. (1Pe 2:21-23; 3:1, 2) Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ń kojú irú àtakò bẹ́ẹ̀, má ṣe jáwọ́ nínú fífi ire ṣẹ́gun ibi. (Ro 12:21) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè gbéṣẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ, ó sì lè mú kí ọkọ rẹ yí pa dà kó sì wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Má ṣe máa rin kinkin mọ́ èrò tìẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ máa gba ti ẹnì kejì ẹ rò. (Flp 2:3, 4) Máa fìfẹ́ hàn sí i, kó o sì máa ṣe ojúṣe ẹ̀ nínú ilé tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, máa fetí sílẹ̀ dáadáa. (Jem 1:19) Máa ṣe sùúrù, kó o sì jẹ́ kí ẹnì kejì ẹ mọ̀ pé ìfẹ́ rẹ̀ ò kúrò lọ́kàn ẹ. Kódà, tẹ́nì kejì rẹ ò bá fi bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn sí ẹ tàbí tí ò bọ̀wọ̀ fún ẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ò ń kojú, ó sì mọyì bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́.​—1Pe 2:19, 20.

WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ Ń FÚN WA LÓKUN KÁ LÈ GBÉ ẸRÙ WA, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Grace Li nígbà tó ṣègbéyàwó?

  • Kí ló mú kó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́?

  • Àwọn ìṣòro wo ni Arábìnrin Li kojú lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi?

  • Àdúrà wo ni Arábìnrin Li gbà nítorí ọkọ rẹ̀?

  • Àwọn ìbùkún wo ni Arábìnrin Li ti rí torí pé ó ń hùwà mímọ́, ó sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ ẹ̀?

Ìwà mímọ́ àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ máa ń yíni lọ́kàn pa dà!