ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Jésù Jẹ́rìí sí Òtítọ́

Yorùbá
Jésù Jẹ́rìí sí Òtítọ́
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202018374/univ/art/202018374_univ_sqr_xl.jpg

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 18-19

Jésù Jẹ́rìí sí Òtítọ́

Jésù Jẹ́rìí sí Òtítọ́

18:​36-38a

Jésù jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé

  • NÍNÚ Ọ̀RỌ̀: Ó fi ìtara wàásù òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run[1]

  • NÍNÚ ÌṢE: Ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ mú kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ já sí òtítọ́

Àwa náà ń jẹ́rìí sí òtítọ́ torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù la jẹ́

  • NÍNÚ Ọ̀RỌ̀: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń pẹ̀gàn wa, síbẹ̀ à ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣàkóso báyìí, èyí tí Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀[2]

  • NÍNÚ ÌṢE: Bí a ò ṣe ń dá sọ̀rọ̀ òṣèlú àti ogun, tá a sì ń hùwà tínú Ọlọ́run dùn sí fi hàn pé ìjọba Jésù là ń tì lẹ́yìn