ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò Lóde Ẹ̀rí ní October 2017

Yorùbá
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò Lóde Ẹ̀rí ní October 2017
/assets/ct/579af9cf16/images/syn_placeholder_sqr.png

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa múra sílẹ̀ de àjálù?

Ka Bíbélì: Owe 27:12

Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe kí àjálù tó wáyé, nígbà àjálù àti lẹ́yìn tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀.

MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI

Béèrè ìbéèrè: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

Ka Bíbélì: 1Jo 5:3

Òtítọ́: Tá a bá ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

ǸJẸ́ ÀWỌN ÒKÚ LÈ JÍǸDE? (T-35)

Béèrè ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé máa ń ṣe àjọyọ̀ ọdọọdún láti ṣàyẹ́sí àwọn òkú. Ǹjẹ́ ẹ rò pé a tún lè rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?

Ka Bíbélì: Iṣe 24:15

Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ àǹfààní tí ìrètí àjíǹde máa ṣe fún wa. [Tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kó wo fídíò náà Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.