ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti November 24-30, 2025

Yorùbá
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti November 24-30, 2025
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/202025404/univ/art/202025404_univ_sqr_xl.jpg
mwb25 November ojú ìwé 8

November 24-30

ÀÌSÁYÀ 1-2

November 24-30

Orin 44 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ọkàn Àwọn Tí “Ẹ̀ṣẹ̀ Wọ̀ Lọ́rùn” Lè Balẹ̀

(10 min.)

[Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà.]

‘Ẹ̀ṣẹ̀ wọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́rùn’ (Ais 1:4-6; ip-1 14 ¶8)

Tí wọ́n bá ronú pìwà dà, Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wọ́n (Ais 1:18; ip-1 28-29 ¶15-17)

RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Tá a bá ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá torí a ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀?

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Ais 2:2—Kí ni “òkè ilé Jèhófà” dúró fún? (ip-1 39 ¶9)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ohun tí ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí yàtọ̀ sí ohun tó o múra sílẹ̀ láti bá a sọ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) ijwbq àpilẹ̀kọ 96—Àkòrí: Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀? (th ẹ̀kọ́ 20)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 38

7. Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Jèhófà Máa Ń Dárí Jini

(15 min.) Ìjíròrò.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o bi wọ́n ní ìbéèrè nípa fídíò náà àtàwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́.

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 89 àti Àdúrà